Abdulsalam Abubakar náà dìbò ní Minna
Olori orilẹede yii nigba kan laye ijọba ologun, Ajagunfẹyinti Abdulsalam Abubakar naa ti lọ dibo tiẹ ni ilu abinibi rẹ, Minna

Lónìí, ọjọ́ kẹtà oṣù kejì ọdún 2019 ni ìdìbò tí àjọ elétòìdìbò, INEC sún síwájú fún ààrẹ àti ilé aṣofin àgbà.
Yetunde Olugbenga
Olori orilẹede yii nigba kan laye ijọba ologun, Ajagunfẹyinti Abdulsalam Abubakar naa ti lọ dibo tiẹ ni ilu abinibi rẹ, Minna

Ibudo ìdìbò ni VGC nipinlẹ Eko ni igbakeji aarẹ, Yemi Osinbajo ti sọrọ lẹyin to dibo tan.Osinbajo ni, o da oun loju pé APC lo maa wọle ti oun ati Buhari yoo tun sejọba lẹẹkan síi.
Osinbajo fikun pe oun yoo gba èsì ìdìbò òní wọlé to bá ti lọ bóṣe yẹ.
Ojọgbọn Yemi Osinbajo lo n dije dupo igbakeji aarẹ pẹlu Buhari ni ẹgbẹ oṣelu APC

Àwọn oludibo kan fi ìjà peeta ni agbègbè ìta Amodu, nilu Ilọrin.
Ifọti ti wọn fun oludibo naa, lo tí sọ oludibo naa di èrò ilé ìwòsàn nigba to dákú gborangandan.
Awọn eeyan to wa nibẹ si ti sáré gbé ẹni náà lọ ilé iwosan.

Minisita feto ohun amusagbara, ilegbe ati eto irinna, Babatunde Raji Fashola ati aya rẹ, Emmanuella Abimbola Fashola, lo dibo ni wọọdu G3, agọ idibo keji, nile ẹkọ girama kekere to wa ni opopona ltolo, ladugbo Surulere, nilu Eko.

Ọjọgbọn Yemi Ọsinbajo tii se igbakeji aarẹ ati iyawo rẹ, Dọlapọ naa ti dibo tiwọn ni ilu Eko

Oludije ẹgbẹ oṣelu YPP Kingsley Moghalu ti pe fun ki wọn ṣe afikun asiko idibo Aarẹ.
O pe ipe yi lẹyin ti ko ribi dibo laaye idibo rẹ.
Ninu fọnran fidio ti a fi si isalẹ yi,niṣe ni o n binu pe ẹrọ idibo ko ṣisẹ lẹyin tawọn ti pẹ lori iduro.
Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu to jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu APC ree to n tẹka ni ibudo idibo rẹ ni ipinlẹ Eko.

Adekunle Akinlade to jẹ oludije labẹ asia gbẹ oṣelu APM ni ipinlẹ Ogun ti dibo ni wọọdu rẹ.
Oun ni oludije ti Gomina Amosun ti ipinlẹ Ogun fa kalẹ gẹgẹ bi aayo rẹ.

Oludibo ti oruko re n je Tawa Oladepo gun oludibo miiran ti won npe ni Iya Ibeji ni igo ni oju ni Ife Central, Akarabata We, Ilagere Ile-Ife, ipinlẹ Osun. Won n jasi emi ni dibo kan, iwo ko lokan.
Ṣe ni jẹ bo gbogbo oju iya ibeji ti wọn si gbe e digba digba kuro nibi idibo. Ọlọpaa ti mu Tawa Oladepo bayii.

Akojọpọ aworan ree loriṣiriṣi ti ko ṣee mọkan kuro lasiko idibo tonii
Ni ilu ilorin, ipinlẹ Kwara, iya arugbo yii, ni ọdun marunlelaadọrin ni wọn ko jẹ ki oun dibo nitori pe wọn ni kaadi idibo to wa lọwọ rẹ kii ṣe alalopẹ. Iya ni lati ago meje owurọ ni oun ti wa lori ila ni ibudo idibo ti Dokita Ibrahim oloriẹgbẹ ti dibo.

Oju akroyin ta kan ri Gomina Ibikunle Amosun ati iyawo rẹ ti wọn to sori ila lati dibo ni wọọdu wọn ni ipinl Ogun.

Ni adugbo Mushin, ikọ iroyin wa se alabapade awọn ọdọ kan ti wọn n se faaji pẹlu ọti bia. Awọn ọdọ naa ni awọn ni kaadi idibo, tawọn si setan lati dibo. Wọn fikun pe awọn kan kọkọ n fi ọti bia pa ironu rẹ ni laarọ kutukutu.
Dokita Ibrahim Oloriẹgbẹ to jẹ alatako Sẹnetọ Bukola ti dibo ni wọọdu rẹ ni aarin gbungbun ipinlẹ Kwara ni ilu Ilorin. Oun ati Sẹnetọ Bukola Saraki ni wọn jọ n du aga kan naa nile igbimọ aṣofin agba Naijiria.

Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba Bukola Saraki ti dibo ni wọọdu idibo rẹ ni Òde Opobiyi 06, Agbaji ilu Ilorin.
Deede ago mwa kọja iṣẹju meji ni akọ́ọroyin wa sọ pe Bukola Saraki de ibudo idibo rẹ.
Oludije ipo Aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP Atiku Abubakar ti tẹka ni Yola
Ohun ati iyawo rẹ Titi Abubakar ni wọn jijọ kọwọrin lọ si aaye idibo wọn.
Nigba ti o n dahun ibeere awọn akoroyin lori boya yoo tẹwọgba esi idibo naa, Atiku ni 'ololufẹ ijọba awa ara wa lohun'


Akọroyin BBC ti fi aworan aṣoju ẹgbẹ oṣelu APC kan ti o n tọka ibi tawọn eeyan yoo dibo si ṣọwọ si wa.
Igbese yi lodi si ofin Inec nipa idibo


Aarẹ Muhammadu ati iyawo rẹ Aisha nigba ti wọn n dibo ni ibudo idibo wọn ni ilu Daura.
Nihin ni oju akọroyin wa ti ta kan to ri i bi o ṣe n wo ta ni yoo dibo fun.

Gomina ipinlẹ Ondo, rotimi Akeredolu ati iyawo rẹ naa ti lọ ṣe ayẹwo orukọ wọn si ti dibo ni wọọdu 5 ibudo idibo 6 ni Ijẹbu 2

