Inec ṣún àkókò àyẹ̀wò orúkọ olùdìbò síwájú
Ajọ eleto idibo lorileede Naijiria Inec ti kede afikun akoko idibo ninu ibo aarẹ to n lọ lọwọ.
Komisana fun ajọ naa kan Festus Okoye lo fidi ọrọ yi mulẹ fawọn oniroyin l'Abuja.
''Ohun ti a pinu ni pe ki awọn aaye idibo ti ibo bẹrẹ laago mẹsan fi wakati kan kun wakati idibo wọn''
O salaye pe nigba ti yoo fi di ago mejila kaakiri Naijiria awọn ti ri aṣeyọri pẹlu ibo to to ida 100% nipa bibẹrẹ ibo lawọn ibi kan ti awọn miran si ri to ida 90%.
Okoye ni lootọ lawọn ni ipenija pẹlu awọn ẹrọ kaadi idibo ti ko ṣiṣẹ daada,ipenija aabo, aisi awọn iwe esi ibo ati pipẹde awọ awakọ lawọn ipinlẹ kan.



















