Àwọn olùdìbò sọ òkò pa ọkùnrin kan tí wọn ló da ìbò rú

Lónìí, ọjọ́ kẹtà oṣù kejì ọdún 2019 ni ìdìbò tí àjọ elétòìdìbò, INEC sún síwájú fún ààrẹ àti ilé aṣofin àgbà.

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Yetunde Olugbenga

  1. Ẹni ba ṣe daada yoo pada wọle-Jonathan

    Aarẹ ana Goodluck Jonathan ti ni ẹnikẹni to ba ṣe daada,awọn ara ilu yoo dibo yan lẹẹkansi.

    O salaye ọrọ yi fun awọn akọroyin lẹyin igba ti o dibo tan nilu Yenegoa.

    Ẹ gbọ ohun ti o sọ lede Geesi

    Àkọlé fídíò, Aarẹ Jonathan sọrọ si awọn akọroyin lẹyin to dibo tan
  2. Adeleke rèé o ní ibùdó ìdìbò rẹ̀ l'Ọṣun

    Ni ibudo idibo Ademola Adeleke, Abegunde/Sagba Ede North ni ijọba ibilẹ Osun West, ipinlẹ Osun ree nibi to ti n ba awọn eniyan sọrọ.

    Ademola Adeleke
    Àkọlé àwòrán, Ademola Adeleke
    Ademola Adeleke
    Àkọlé àwòrán, Ademola Adeleke
  3. Ẹ wo àwọn ọ̀dọ́ tó ń dìbò fún ìgbà àkọ́kọ́

    Ikọ iroyin waṣe alabapade awọn ọdọ ni ipinlẹ Kwara, ti wọn fẹ kopa ninu eto idibo fun igba akọkọ.Ninu ifọrọwerọ wọn pẹlu ikọ iroyin wa, wọn salaye pe inu awọn dun pupọ lati kopa ninu eto idibo yii. Wọn ni eyi yoo fun awọn lanfaani lati mu ki iyipada rere ba ipinlẹ awọn ati orilẹede Naijiria lapapọ. Bakan naa ni wọn fi idi rẹ mulẹ pe, awọn ti gba ilanilọyẹ lati lori bi awọn yoo se tẹ ika, ti ibo awọn ko fi ni jona.

    Àkọlé fídíò, Nigeria 2019 Elections: Àwọn ọ̀dọ́ tó ń dìbò fún ìgbà àkọ́kọ́ ń fò fáyọ̀
  4. Igbákejì Atiku, Peter Obi ti dìbò

    Iroyin to n t wa lọwọ ni wi pe igbakeji oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP ti dibo ni ibudo idibo rẹ

    Peter Obi
    Àkọlé àwòrán, Peter Obi
  5. Láti ìpínlẹ Ọṣun

    Nkan bii agogo mẹsan kọja iṣẹju mẹẹdọgbọn ni idibo ti bẹrẹ ni wọọdu 08, ibudo idibo Megida Kuoye ni ijọba ibilẹ Ifẹlodun Ikirun, ipinlẹ Ọṣun.

    ibudo idibo Megida Kuoye
    Àkọlé àwòrán, ibudo idibo Megida Kuoye
    Ipinlẹ Oṣun
    Àkọlé àwòrán, Ipinlẹ Oṣun
  6. Wọn kò tíì bẹ̀rẹ̀ ìdìbò ní ìbùdó tí Ọṣinbajo yóò ti dìbò

    Ni ibudo ti igbakeji aarẹ ,Ọjọgbọn Yemi Ọṣinbajo yoo ti dibo, wọn ko tii bẹrẹ idibo bẹẹ si ni igbakeji aarẹ naa ko tii de ibudo idibo rẹ ni nkan bii agogo mẹwaa ku iṣẹju mẹwaa ti akọroyin wa fi aworan yii ranṣẹ.

    Eyi ni agbegbe BGC ni ilu Eko.

    Agbegbe BGC ni ilu Eko
    Àkọlé àwòrán, Agbegbe BGC ni ilu Eko
    Agbegbe BGC ni ilu Eko
    Àkọlé àwòrán, Agbegbe BGC ni ilu Eko
  7. Awọn ọdọ kan tun ree ni agbegbe ibudokọ Agege niluu Eko. Bọọ́lù ni o, lonìí ọjọ idibo.

    Agege, Eko
    Àkọlé àwòrán, Agege, Eko
  8. Bọ́ọ̀lù gbígbá làwọn ọ̀dọ́ kan fi ń ṣara rindin lọ́jọ́ ìdìbò

    Nigba ti awọn eeyan n duro lati dibo,ṣe ni awọn ọdọ kan n gba bọọlu.Akọroyin wa to lọ sawọn adugbo kann ilu Ibadan, lo se alabapade awọn ọdọ yii ti wọn gba bọọlu loju popo to da paroparo.Ninu ifọrọwanilẹnuwo taa se fun wọ, awọn ọdọ naa ni awọn n gbaradi silẹ lati dibo ni, awọn si fẹ ki ara awọn dangajia na.

    Àkọlé fídíò, Nigeria 2019 Elections: Àwọn ọ̀dọ́ ń gbá bọ́ọ́lù lọ́jọ́ ìbò
  9. Bí ìdìbò ṣe ń lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan ni iná dídá ń sọ kutu wọ̀wọ̀ lọ́dọ̀ àwọn olóúnjẹ

    Ebi kii wọnu kọrọ mii wọ ọ lo difa fun awọn olounjẹ ni ilu Ilorin pẹlu aduru koko yii lori aro.

    Lati ilu ilorin
    Àkọlé àwòrán, Lati ilu ilorin
  10. Jonathan àti ìyàwó rẹ̀ gúnlẹ̀ sáàyè ìdìbò wọn

    Aarẹ ana, Goodluck Jonathan ati Iyawo rẹ Dame Patience ti gunlẹ si aaye idibo wọn tii ṣe aaye idibo 39 to wa ni wọọdu 13.

    Aworan Aarẹ ana Jonathan
    Àkọlé àwòrán, Aworan Aarẹ ana Jonathan
    Aworan Aarẹ ana Jonathan
    Àkọlé àwòrán, Aworan Aarẹ ana Jonathan
  11. Èlò ìdibò pẹ́ dé ààyè ìdìbò Saraki

    9:06 ni awọn ohun elo idibo ṣẹ̀ṣẹ̀ dé ibi idibo Aare ile igbimo asofin agba, Bukola Saraki iyẹn Agbaji ward PU 005,Ode opobiyi 1.

    Akọroyin wa jabọ pe Bukola Saraki ko tii de ibẹ lati dibo.

    Aworan awọn oludibo
    Àkọlé àwòrán, Aye idibo Bukola Saraki ko tete ri nnkan elo didbo gba
  12. Ọdún yìí kò yẹ̀! Lọ́jọ́ ìdìbò

    Aṣọ ẹbi lawọn ọrẹ mẹta yii wọ lọ si aaye idibo wọn nipinlẹ Edo.

    Aworan awọn oludibo
    Àkọlé àwòrán, Aworan awọn oludibo
  13. Ìwé èsì ìbò wa kò pé - òṣìṣẹ́ INEC Ilorin

    Ni aaye idibo Akilaaso 1 002, pópó Igbọna, Ilorin West, nipinlẹ Kwara oṣiṣẹ INEC to wa nibẹ sọ fun akọroyin wa pe iwe esi ibo, ti nọmba wọn jẹ 1-40 ko si nibẹ.

    O ni awọn ti salaye fun awọn ọga awọn ṣugbọn wọn ko tii fun awọn lesi.

    aworan awọn oludibo
    Àkọlé àwòrán, Ibo ko duro laaye idibo naa ni agegbe Popo Igbọna nilu Ilorin
  14. Peter Obi: Bí a kò bá jawé olúborí, bí àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe fẹ́ nìyẹn

    Igbakeji oludije fun ipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu PDP, Peter Obi ti dibo ni ilu Agulu, ipinlẹ Anambra. O ni bi ẹgbẹ oṣelu PDP ba fidi rẹmi, tọ̀, bi awọn mọ Naijiria ṣe fẹ ẹ niyẹn o.

    Peter Obi
    Àkọlé àwòrán, Peter Obi
  15. 'A rí i ti wọ́n ti òpópónà Eko sí Ibadan pa'

    Awọn araalu lo fi fọto yii ranṣẹ lọna irinajo wọn laarin opopona Eko si Ibadan ti awọn ẹṣọ oju popo ti pa.

    Opopona Eko si Ibadan
    Àkọlé àwòrán, Opopona Eko si Ibadan
  16. Wọ́n ti gbé èlò ìdìbò dé ààyè ìdìbo Tinubu

    O pẹ wọn diẹ ṣugbọn awọn nkan elo idibo ti gunlẹ laaye idibo Asiwaju Bola Tinubu.

    Ni nnkan bi ago mẹsan ku iṣẹju mẹtadinlogun ni wọn fi danfo gbe e de.

    Aworan awọn oṣise Inec
    Àkọlé àwòrán, Aworan awọn oṣise Inec
  17. Ìdìbò kò tìí bẹ̀rẹ̀ láàyè ìdìbò Ààrẹ àná, Goodluck Jonathan

    Titi di nkan bii ago mẹsan ku iṣẹju mẹẹdogun ti akọroyin wa jabọ, idibo ko tii bẹrẹ ni aaye idibo aarẹ ana, Goodluck Jonathan.

    Aaye idibo 39 to wa ni wọọdu 13 nibi ti o ti fẹ dibo.

    Awọn ohun elo idibo ko ti de ibẹ gẹgẹ bi ohun ti a gbọ.

    Aworan aaye idibo Aarẹ ana Goodluck Jonathan
    Àkọlé àwòrán, Aworan aaye idibo Aarẹ ana Goodluck Jonathan
    Aworan aaye idibo Aarẹ ana Goodluck Jonathan
    Àkọlé àwòrán, Aworan aaye idibo Aarẹ ana Goodluck Jonathan
  18. Idibo ti bẹrẹ laaye idibo Gomina Oyetola l'Osun

    Awọn oludibo ti peju sibi aaye idibo PU002, Ward 1, Popo, Iragbiji, Boripe LG, Osun Central, nibi ti Gomina Ipinlẹ Osun, Gboyega Oyetola yoo ti dibo.

    Gbogbo awọn nnkan elo idibo loniroyin jabọ pe o ti wa nibẹ.

    Aworan idibo nipinlẹ Osun
    Àkọlé àwòrán, Aworan idibo nipinlẹ Osun
    Aworan idibo nipinlẹ Osun
    Àkọlé àwòrán, Aworan idibo nipinlẹ Osun
  19. Láti ìpínlẹ̀ Adamawa

    Ibudo idibo ti oludije fun ipo aar labẹ asia ẹgb oṣelu PDP, Atiku Abubakar yoo ti dibo niyii.

    Eto ti bẹrẹ nibẹ.

    Ipinlẹ Adamawa
    Àkọlé àwòrán, Ipinlẹ Adamawa
  20. Ààrẹ Buhari ti ń dìbò

    Ni ilu Daura, aarẹ Buhari ti n dibo, wọn beere lọwọ rẹ boya yoo ki ẹlomiran ku oriire bi ko ba jawe olubori, Buhari ni ara ohun lohun yoo ki ku oriire nigbẹyin gbẹyin. Aarẹ Buhari ati aya rẹ Aisha ni wọn kọkọ dibo ni ibudo idibo wọn.

    Buhari ni Daura
    Àkọlé àwòrán, Buhari ni Daura