Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Àwọn Eléso dúró pé kí ebi Kó má pa àwọn olùdìbò ní agbègbè Zango Daji primary school PU - Lokoja - Kogi

    Àwọn Eléso dúró pé kí ebi Kó má pa àwọn olùdìbò ní agbègbè Zango Daji primary school PU - Lokoja - Kogi

    Eleso
  2. Wọ́n jí òṣìṣẹ́ àjọ INEC gbé ní Bayelsa, bí àwọn 12 míràn ṣe móríbọ́ nínú ọkọ̀ ojú omi tó dànù, Adarí ẹ̀ka ìlanilọ́yẹ àjọ INEC wí pé èyí kò níí dá àwọn dúró

    Boat

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    Nkan ko ṣe ẹnu re fun ajọ eleto idibo ilẹ yii (INEC), ni ipinlẹ Bayelsa ni bi oṣiṣẹ ajọ naa kan to jẹ alamojuto ibo (SPO) ni wọọdu Ossioma nijọba ibilẹ Sagbama ṣe bọ sọwọ awọn ajinigbe nibi ti o tin duro lati wọ ọkọ oju omi ni etido Amassoma.

    Adari ẹka ilanilọyẹ lajọ naa, Wilfred Ifogah, to fi ọrọ yii lede ninu atẹjade kan wi pe awọn ti fi ọrọ naa to awọn agbofinro leti.

    Bii pe ẹni ti wọn ji gbe o tii to, awọn mejila miran to tun jẹ oṣiṣẹ ajọ naa ni ori koyọ ninu ijamba ọkọ oju omi nigba ti ọkọ ti awọn oṣiṣẹ naa wa ninu rẹ dojude lakoko ti wọn n ko nkan idibo lọ wọọdu Koluama, nijọba ibilẹ Guusu Ijaw.

    Atẹjade naa wi pe “O jẹ ohun idunnu pe a ko padanu ẹnikẹni bi wọn ṣe doola ẹmi awọn oṣiṣẹ mejila naa ati awakọ wọn”.

    Bo tilẹ jẹ pe ko si ẹnikẹni to farapa, lara awọn ohun elo idibo ti wọn ko dani bii iwe esi ibo, ẹrọ ilewọ amunaọwa (power bank) ati ẹru awọn oṣiṣẹ naa lo b’odo lọ.

    Ifogah wi pe “iye awọn to forukọ silẹ ni agbeegbe naa jẹ ẹgbẹẹdọgbọn ati ejidinlaadọriinlelọọdurun (5368), ti awọn to gba kaadi idibo alalopẹ si jẹ ẹgbẹẹdọgbọn ati ọkanlelẹwaalelọọdurun (5311)”.

    O fi kun un pe ajọ INEC n sagbogbo ipa rẹ lati ri pe eto idibo waye lagbeegbe naa.

  3. Àjọ INEC ti pín àwọn ohun èlò fún ètò ìdìbò n'ípínlẹ̀ Kogi, Àjọ INEC ti bẹ̀rẹ̀ síní pín àwọn ohun èlò fún ètò ìdìbò n'ípínlẹ̀ Kogi

    Aworan nnkan elo fun eto idibo ipinlẹ Kogi

    Ajọ eleto idibo, INEC ti bẹrẹ sini pin awọn nnkan elo fun eto idibo ati iwe akọsilẹ abajade ibo ni ẹka banki apapọ orilẹede Naijiria, CBN, to n bẹ ni Lọkọja, olu ilu ipinlẹ Kogi.

    Ninu ọrọ ti o ba awọn oniroyin sọ l'Ọjọbọ nibi ti wọn ti n ṣe eto naa, adari itaniji ati ilanilọyẹ fun awọn oludibo fun ajọ INEC n'ipinlẹ Lọkọja, Aliru Haruna Sule ṣe alaye wi pe ajọ naa ti pese awọn ohun elo ti o to lati dibo ninu eto idibo ti yoo waye ni Satide ọjọ kọkanla oṣu kọkanla ọdun yii n'ipinlẹ Kogi.

    O ni awọn ọkọ ti yoo pin awọn ohun elo naa ti wa n'ikalẹ, bẹẹ sini awọn ẹṣo aabo ti yoo maa mojuto igbokegbodo awọn ohun elo naa jakejado awọn ijọba ibilẹ mọkanlelogun to n bẹ n'ipinlẹ naa ti n duro wamuwamu.

    Sule ni gbogbo ibudo ti idibo yoo tiwaye ni awọn oṣiṣẹ ajọ naa yoo ti ni anfani lati ṣe onka ati akọsilẹ abajade ibo, dipo bi alakoso ajọ naa ni ijọba ibilẹ ṣe maa n ṣee tẹlẹri. O parọwa si awọn oludibo lati jade lọ ṣe ojuṣe wọn lọjọ idibo lai si ifoya kankan. O fi kun ọrọ rẹ wi pe ẹni ti o ba ni ero tabi eto buburu nikan ni ko ni jade lati lọ dibo lọjọ Abamẹta.

    Aworan nnkan elo fun eto idibo ipinlẹ Kogi
    Aworan nnkan elo fun eto idibo ipinlẹ Kogi
    Aworan nnkan elo fun eto idibo ipinlẹ Kogi
    Aworan nnkan elo fun eto idibo ipinlẹ Kogi
  4. Àwọn ọ̀nà láti fi dá ìròyìn òfégè mọ̀ lásìkò ìbò 2023

  5. Àwọn nǹkan tí o gbọ́dọ̀ mọ̀ kí o tó lọ sí ibùdó ìdìbò nìyí

  6. Ọ̀gá àgbà Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá ṣe ìpàdé àlàáfíà pẹ̀lú àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ saaju ètò ìdìbò Ìpínlẹ̀ Kogi, Afojusun ipade naa ni lati sọ asọyepọ, pin iroyin ati lati ṣe eto ti yoo mu ku eto idibo lọ ni irọwọrọsẹ pẹlu alaafia ni ipinlẹ naa.

    Aworan ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa ati awọn lọbalọba

    Oríṣun àwòrán, X/Muyiwa Adejobi

    Ninu igbiyanju lati riidaju wi pe alaafia j’ọba ni ipinlẹ Bayelsa, Imo, ati Kogi ti eto idibo yoo ti waye lọjọ kọkanla oṣu kọkanla ọdun yii, Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Naijiria, Kayode Adeolu Egbetokun gbe ipade alaafia to ṣe kaakiri awọn ipinlẹ wọnyii de ipinlẹ Kogi l'Ọjọru.

    Awọn ọkanojọkan alẹnulọrọ ni ẹka eto ilera, ẹgbẹ awujọ, oṣiṣẹ eto idibo, awọn adari ilu ati awọn aṣiwaju ẹsin, ẹgbẹ ọdọ ati awọn ẹṣọ aabo lo pejupesẹ nibi ipade naa to waye ni ilu Lọkọja tii ṣe olu ilu ipinlẹ Kogi.

    Afojusun ipade naa ni lati sọ asọyepọ, pin iroyin ati lati ṣe eto ti yoo mu ku eto idibo lọ ni irọwọrọsẹ pẹlu alaafia ni ipinlẹ naa.

    Aworan ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa ati awọn lọbalọba

    Oríṣun àwòrán, X/Muyiwa Adejobi

    Bakan naa ni Egbetokun parọwa si awọn adari ẹgbẹ oṣelu lati ko ipa ti yoo mu ki alaafia j'ọba lai si iwa ipanle laarin awọn ọmọ ẹgbẹ ati alatilẹyin wọn, ki wọn si riidaju wi pe awọn oludibo ni anfani lati ṣe ojuṣe wọn lai si ifoya.

    Nibi ipade naa, oga agba ileeṣẹ ọlọpaa fesi lori fọnran to n lọ kaakiri niluu Anyingba, nibi ti wọn ti fi ẹsun kan wi pe awọn ọlọpaa jawọ ile ọkan lara awọn adari ẹgbẹ oṣelu ni agbegbe naa, gẹgẹ bi o ṣe ke si igbakeji oga agba ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣe akoso ẹka iwadiii lori iwa ọdaran, lati ṣe iwadii ọrọ naa, ki wọn le ṣe awari ohun to ṣẹlẹ gan an ni pato.

    Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa mẹnuba pataki ojuṣe ileeṣẹ naa lati ko akoyawọ lai gbe si ẹyin ẹnikẹni ninu eto idibo naa.

    O kilọ fun awọn to n dije du ipo ati awọn alatilẹyin wọn, to fi mọ awọn ẹṣọ aabo pe ẹnikẹni ti o ba tapa si ofin ko ni lọ lai jiya.

    Aworan ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa ati awọn lọbalọba

    Oríṣun àwòrán, X/Muyiwa Adejobi

    Aworan ọga agba fun ileeṣẹ ọlọpaa ati awọn lọbalọba

    Oríṣun àwòrán, X/Muyiwa Adejobi

  7. Alásè ọmọ orílẹ̀-èdè Ireland gba adé Guinness World Records mọ́ Hilda Baci lọ́wọ́

  8. Wo àwọn gbajúmọ̀ tí wọ́n pàdánú ẹ̀mí wọn lẹ́ni ọdún 27

  9. Gómìnà Otti faraya bí wọ́n ṣe ṣàwárí òkú ènìyàn tó lé ní àádọ́rin ní ẹ̀gbẹ́ ọjà ẹran

    Gomina Alex Otti atawon Maluu

    Oríṣun àwòrán, Alex/Getty Images

    Gómìnà ìpínlẹ̀ Abia, Alex Otti ní àwọn ṣe àwárí òkú tó ti gbẹ tó lé ní àádọ́ta tó fi mọ́ àwọn tí kò ní orí mọ́ nínú igbó tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọjà ẹran Lokpanta tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Umunneochi ní òpópónà Enugu sí Port Harcourt.

    Gómìnà Otti ní àwọn tún ṣàwárí rẹ̀ pé àwọn ajínigbé kan máa ń lo ọjà náà láti gba owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn àwọn tí wọ́n bá jí gbé.

    Lásìkò tí gómìnà Otti ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ ló tú pẹrẹpẹ́rẹ̀ sílẹ̀ pé àwọn afurasí gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn kan ti sọ ọjà náà di orikò wọn níbi tí wọ́n ti máa ń hu àwọn ìwà kò tọ́.

    Ó ní àwọn kan máa ń ta oogun olóró, ìbon àtàwọn nǹkan míì tó lòdì sí òfin nínú ọjà náà.

    Ó ní egungun òkú ọkùnrin, obìnrin àtàwọn ọmọdé ni àwọn rí ní ẹ̀bá ọjà náà.

    Ó ṣàlàyé pé èyí ló mú àwọn gbé àwọn ìgbésẹ̀ tuntun lórí ọjà ọ̀hún àti pé àwọn kò ní gba àwọn ọ̀daràn kankan láyé láti fi ìpínlẹ̀ Abia ṣe ibùjókòó.

    Ó fi kun pé ìpinnu ìjọba láti sọ ọjà náà di ọjà ojoojúmọ̀ nìyí àti pé kìí ṣe pé àwọn fi tako ẹ̀yà kan bíkòṣe láti mú kí ètò ààbò ìpínlẹ̀ náà gbópọn si.

    Gómìnà Otti fi kun pé àwọn ti pèsè ẹ̀rọ ayàwòrán sí gbogbo inú ọjà náà láti lè mú kí ètò ààbò tó dájú wà ní tìbú tòró ọjà ọ̀hún.

    Bákan náà ló ní gbogbo àwọn tó ń sùn nínú ọjà náà tẹ́lẹ̀ ti ń sùn ní ìgboro àti pé àwọn máa mọ odi yí ọjà náà ká láti lè túnbọ̀ pọn kún ètò ààbò ọjà náà.

  10. Aiyedatiwa tọrọ àforíjì lọ́wọ́ Akeredolu, gómìnà fárígá

  11. Ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin da àbá láti sọ ìdánwò WAEC, NECO, JAMB di ọ̀fẹ́ nù

  12. Wo kókó mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa àìsàn jẹjẹrẹ ojú ara

  13. Alága tuntun EFCC pàṣẹ fún gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ láti kéde iye dúkìá tí wọ́n ní

    Ola Olukoyede

    Oríṣun àwòrán, Ola Olukoyede/FACEBOOK

    Alága àjọ tó ń gbógun ti ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà, EFCC, Ola Olukoyede ti darí gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ àjọ náà láti kéde iye dúkìá tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ní.

    Olukoyede tó kéde ìdarí náà ní olú Iléeṣẹ́ EFCC tó wà ní Abuja ní ìgbésẹ̀ náà wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin tó de àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba Nàìjíríà.

    Ó ní ó pọn dandan fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ń gbógun ti ìwà àjẹbánu gbọ́dọ̀ wẹ ọwọ́ náà mọ́ dáradára.

    Ó ṣàlàyé pé gbogbo àwọn tí àwọn n ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ náà ni àwọn máa kéde dúkìá àwọn àti pé àwọn ènìyàn kò nílò láti bẹ̀rù ohunkóhun tí wọn kò bá ti lẹ́bọ lẹ́rù.

    Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ Agbẹnusọ EFCC, Dele Oyewale ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òṣìṣẹ́ kan ti kéde dúkìá wọn tẹ́lẹ̀ rí, ó ní wọ́n máa tun kéde báyìí.

    Bákan náà ló ní àwọn máa ṣèwádìí àwọn dúkìá tí ẹnì kọ̀ọ̀kan bá kéde láti fìdí òótọ́ múlẹ̀ lórí àwọn dúkìá náà.

    Olukoyede tún pàrọwà sí àwọn òṣìṣẹ́ àjọ náà láti ní ìfarajìn sí iṣẹ́ wọn àti ìdí rẹ̀ tí wọ́n ṣe ń gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ láwùjọ.

  14. PDP ń pè fún yíyọ Akeredolu nípò gómìnà l’Ondo, APC ní àìríkanṣèkan ló ń da PDP láàmú

  15. Ọmọdé mẹ́rin kú lásìkò tí ògiri ṣọ́ọ̀ṣì dà wó

    Awọn ọmọde mẹrin ti padanu ẹmi wọn lorileede Burundi lẹyin ti ile ijọsin kan wo lasiko ojo.

    Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin ijọba nilẹ naa ṣe sọ awọn eeyan mẹẹdogun mii farapa ninu iṣẹlẹ naa to waye lowurọ ọjọ Aiku.

    Apa guusu ilẹ naa nibi ti ile ijọsin yi wa jẹ ibi to ti n koju afẹfẹ lile ati arọrọda ojo lẹnu lọọlọ yi.

    Ogiri ile ijọsin yi kan lo wo lo awọn ọmọde wọnyi ti wọn n kopa ninu isin idanilẹkọ ni ṣọọṣi naa.

    Lasiko isin idanilẹkọ ni ogiri wo pa awọn ọmọde wọnyi ni ile ijọsin wọn

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

  16. Ìjọba Ogun fèsì lórí fídíò ìrẹsì "palliative" tó gba orí ayélujára

  17. Ọwọ́ ọlọ́pàá tún padà tẹ afurasí ayédèrú dókítà tó sá làhámọ́

    Awọn ọlọpaa lorileede South Africa ti kede pe awọn ti tun arakunrin kan to sa ni ahamọ wọn mu pada.

    Kingsley Leeto Chele, jẹ ẹni ti wọn fẹsun kan pe ayederu dokita nii ṣe.

    Loju opo ayelujara a maa pe ara rẹ ni Dr Kingsley Chele tabi Dr KJ Ncube.

    Ninu iroyin to taa jabọ tẹlẹ lọsẹ to kọja, ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe awọn ti bẹrẹ si ni wa afurasi yi to sa mọ awọn lọwọ.

    Wọn ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi oni gbajuẹ oju opo Facebook to n parọ tan awọn obinrin.

    Bayii, wọn ni ọwọ awọn ti tẹ ẹ pada lowurọ kutu ọjọ Aje ni Vosloorus lẹba Johannesburg lẹyin ti ileeṣẹ iroyin kan tawọn lolobo ibi to sa pamọ si.

    Ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Gauteng lawọn mọ riri ipa ti ileeṣẹ iroyin yi ko ati ni paapa tawọn araadugbo nipa kikoju iwa ọdaran.

    Bẹẹ ni atẹjade kan lati ọdọ ileeṣẹ ọlọpaa ṣe wi.

    Afurasi yi ti wọn ko mọ ọmọ orileede ibi to ti wa yoo foju ba ileẹjọ ni Pretoris lọjọ Iṣẹgun gẹgẹ bo ṣe wa ninu eto ko to sa mọ awọn ọlọpaa lọwọ.

    Pẹlu binkan ṣe ri yi, wọn ti fi ẹsun pe o sa mọ ọlọpaa lọwọ kun eleyiii to n koju tẹlẹ.

    Ẹsun onigun meji ni wọn fi kan tẹlẹ to da lori gbajuẹ-o sọ fawọn akọṣẹmọṣẹ ilera loju opo Facebook pe oun n wa awọn ti yoo dowo pọ pẹlu rẹ ko to lu wọn ni gbajuẹ.

    Titi di asiko yi, Ọgbẹni Chele ko tii sọrọ nipa awọn ẹsun wọnyi.

    Aworan Kingsley Leeto Chele ti wọn fẹsun kan pe ayederu dokita nii ṣe.

    Oríṣun àwòrán, SA Police Service

  18. 'Ifá ló yẹ kí a máa lò láti fi yan àwọn olóṣèlú tí a bá fẹ́ yan adarí rere'

  19. NIMC kéde ìdádúró ní àwọn ibùdó ìforúkọsílẹ̀ kọọkan tó n ṣètò NIN

    Ajọ to n ṣeto iforukọsilẹ fun kaadi idanimọ lorileede Naijiria NIMC ti da eto iforukọsilẹ duro lawọn ibudo kọọkan ti awọn alajọṣepọ wọn n ṣe idari rẹ faraalu to ba fẹ forukọsilẹ lati gba nọmba idanimọ NIN.

    Atẹjade kan lati ọwọ adari ajọ naa Onimọ ẹrọ Abisoye Coker-Odusote sọ pe igbesẹ yi wa ni ibamu pẹlu ifarajin ajọ naa lati ri wi pe ilana iforukọsilẹ NIN gunrege fun awọn araalu.

    Ohun ti eyi tunmọ si gẹgẹ bo ṣe sọ ni pe awn yoo daabo bo iroyin nipa araalu ni ibamu pẹlu ilana to bojumu.

    O ni ''eto taa fẹ gunle yi yoo jẹ ki iforukọsilẹ lọ ni irọwọ ti ko si ni si kọnun kọhọ kankan bi awọn eeyan ba fẹ ṣe iyipada nọmba NIN wọn''

    Ni bayii fifi orukọ silẹ lawọn aaye ti NIMC ya sọtọ ko ni waye lasiko yi titi ti wn yoo fi pari eto agbeyẹwo fawọn to n ba wọn dari eto nibẹ.

    Ni idahun si igba ti awọn araalu yoo lanfaani lati bẹrẹ si ni forukọsilẹ pada, adari ajọ NIMC ko sọ igba kan pato amọ o ni awọn ko ni jẹ ko pẹ kawọn to bẹrẹ pada.

    Amọ ṣa o ni gbogbo eto iforukọsilẹ,iyipada lori nọmba NIN ati awọn iṣẹ miran lawọn ibudo iforukọsilẹ to wa ni ijọba ibilẹ ati ọfisi ipinlẹ ṣ i n tẹsiwaju.

    Ni ti tawọn ọmọ Naijiria to wa lẹyin odi, wọn ni eto n lọ lọwọ lati jẹ ki wọn ṣe iforukọsilẹ loju opo ayelujara.

    Aworan afihan kaadi idanimọ ọmọ orileede Naijiria ti NIMC n ṣeto

    Oríṣun àwòrán, NIMC

  20. Ṣé ẹ ti gbọ́ nípa ọdún Ifa ìlú Shao rí?