Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti ilé ìwòsàn aládàni mẹ́fà pa lórí ẹ̀sùn lílo ayédèrú òṣìṣẹ́

    Ọkan lara awọn ile iwosan ti wọn ti pa

    Oríṣun àwòrán, Oyo State government

    Ijọba ipinlẹ Oyo ti gbe ile iwosan mẹfa tipa lori ẹsun pe wọn ko koju oṣuwọn.

    Lara awọn ẹsun ti ijọba fi kan awọn ile iwosan naa ni pe wọn n gba awọn oṣiṣẹ ti ko koju oṣuwọn siṣẹ lati maa tọju awọn alaisan.

    Kọmiṣọna fun eto iroyin ipinlẹ oyo, Ọmọba Dotun Oyelade, lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan.

    Lasiko to n yẹ awọn ile iwosan kan wo niluu Ibadan, alaga ajọ to n gbogun ti awọn ayederu oṣiṣẹ eto ilera, Dọkita Adekunle Aremu sọ pe awọn n ṣeto naa lati daabo ilera awọn eeyan ipinlẹ Oyo.

    Aremu ni ijọba Oyo ko ni faaye gba ki awọn oṣiṣe ti ko koju oṣuwọn maa tọju awọn alaisan nipinlẹ naa.

    O fi kun pe ẹnikẹni to tapa si ofin eto ilera ipinlẹ Oyo yoo foju wina ofin.

    O tun rọ awọn araalu lati maa ṣi ijọba ni gbẹrẹ ipakọ ti wọn ba kofiri ayederu oṣiṣẹ eto ilera kankan layika wọn.

    O sọ ninu atẹjade naa pe “Afojusun wa ko ṣoro lati damọ, ijọba ipinlẹ Oyo mu eto ilera araalu ni ọkunkundun.

    “Ijọba n ri daju pe eto ilera awọn eeyan wa wà lara eyi to dara julọ lasiko yii, ki awọn araalu le wa ni ilera pipe."

    Lara awọn ile iwosan ti ijọba naa gbe tipa ni New Jobi Memorial Hospital; Omolara Clinic & Maternity Home; Amazing Grace Medical Clinic; Emiloju Clinic ati Maternity Centre, Ogbere.

    Awọn to ku ni Safeway Clinic, Gbaremu ati Emilagba Clinic ati Maternity Centre, Ibadan.

  2. Ẹ̀ṣọ́ Amotekun nawọ́ gán afurasí ajínigbé 43 ní ìpínlẹ̀ Ondo

  3. EFCC kéde ìyàwó Emefiele, àwọn mẹ́ta mìíràn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n ń wá

    Godwin ati Margaret Emefiele

    Oríṣun àwòrán, OTHERS

    Àjọ tó ń gbógunti ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà, EFCC ti kéde ìyàwó gómìnà àná fún ilé ìfowópamọ́ àgbà Nàìjíríà, CBN Godwin Emefiele, Margaret Dumbiri Emefiele gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n ń wá.

    Margaret Emefiele àti àwọn mẹ́ta mìíràn - òṣìṣẹ́ CBN kan, Eric Odoh, obìnrin oníṣòwò kan, Anita Omoile àti òṣìṣẹ́ Bureau de Change kan, Jonathan Omoile - ni EFCC fi sórí ayélujára X wọn pé wọ́n ń wá.

    Nínú àtẹ̀jáde tí wọ́n fi kéde àwọn ènìyàn náà bi ẹni tí wọ́n ń wá ni wọ́n ti sọ pé àwọn ènìyàn ọ̀hún lẹ̀dí àpòpọ̀ pẹ̀lú gómìnà CBN àná, Godwin Emefiele láti fi kó ọ̀bítíbitì owó tó wà fún ará ìlú sápò ara rẹ̀.

    EFCC ní láti ìgbà tí àwọn ti nawọ́ gán Godwin Emefiele tí àwọn sì ti gbe lọ sílé ẹjọ́ ni ìyàwó rẹ̀ Magraret ti sá lọ, tò sí lọ farasin láti ìgbà náà.

    Àwòrán àwọn ẹni mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí ni EFCC fi sójú òpó X wọn.

    Wọ́n ní ẹnikẹ́ni tó bá mọ bí ọwọ́ ṣe lè tẹ àwọn ènìyàn náà kò kán sí àjọ EFCC tàbí àgọ́ ọlọ́pàá tó bá sún mọ́ wọn.

    Ìkéde yìí lọ tún jẹ́ ọ̀tun sí ẹ̀sùn tí gómìnà àná CBN, Emefiele ń kojú láti ìgbà tí ààrẹ Bola Tinubu ti ní kó lọ rọ́kún nílé ní ọjọ́ Kẹsàn-án, oṣù Kẹfà ọdún 2023.

    Skip X post
    Allow X content?

    This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

    Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

    End of X post

  4. Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ afurasí méjì tó ń kó ayédèrú òògùn lọ si ọjà Alaba

    Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti ṣafihan awọn afurasi meji kan to fẹ lọ ta oogun ti gbendeke iye ọjọ ti wọn fi ṣee lo ti kọja.

    SP Benjamin Hundeyin to jẹ alukoro ọlọpaa lo fidi ọrọ yi mulẹ ni oju opo rẹ ni Twitter X.

    O sọ pe paali aadọrin oogun Feed Fine Cyproheptadine Caplets 4g lawọn ba ninu ọkọ wọn ladugbo Okokomaiko ni Eko.

    O ni awọn afurasi meji naa Augustine Egemoye,ẹni ọgọta ọdun ati Innocent Eromosele ẹni ọdun marundinlogoji jẹwọ pe awọn fẹ gbe oogun naa lọ ba eeyan kan ni ọja Alaba.

    O ni ẹni naa yoo yi ọjọ ti wọn kọ sara oogun naa pada lati le fi ri wọn ta bii oogun to ṣi da.

    Ati ayederu oogun ti wọn gba,ọkọ ati awọn afurasi naa lo jijọ wa ni ahamọ ọlọpaa.

    Aworan awọn afurasi ti ọwọ ọlọpaa tẹ

    Oríṣun àwòrán, Twitter/benhundeyin

  5. Wo ọmọ ọdun mẹ́tàlá tó ń ta ''Hawaiian guitar'' sí orin Obey, Sunny àti tàkasúfèé

  6. Ọlọ́run sọ fún mi nínú ẹ̀mí pé ẹnu Yorùbá kò ṣọ̀kan fún ìdásílẹ̀ Yorùbá Nation - Funmi Aragbaiye

  7. Alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP gba ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé

  8. Gomina Adeleke yọ ọba mẹta nipo nipinlẹ Ọṣun

  9. Àwọn adigunjalè ṣèkọlù sí oní POS ní Kwara, wọ́n tún pa obìnrin kan

  10. EFCC bẹ̀rẹ̀ ìwádìí àwọn gómìnà, mínísítà lórí ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu, Àwọn gómìnà tẹ́lẹ̀rí mẹ́tàlá, àwọn mínísítà ni wọ́n ṣàgbédìde ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu tọ wà lọ́rùn wọn

    EFCC

    Oríṣun àwòrán, EFCC

    Àjọ tó ń gbógunti ìwà àjẹbánu ní Nàìjíríà, EFCC ti ṣàgbédìde àwọn ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu èyí tí iye rẹ̀ tó ₦853.bn tàko àwọn gómìnà àti mínísítà tẹ́lẹ̀ rí kan.

    Gẹ́gẹ́ bí ohun tí iléeṣẹ́ ìròyìn The Punch fi síta lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ Kérìnlá oṣù Kìíní ọdún 2024, àwọn gómìnà àti mínísítà tẹ́lẹ̀ rí mẹ́tàlá ni àjọ náà ń ṣèwádìí lé lórí.

    Wọ́n ní ₦772.2bn ni iye owó tí wọ́n ń ṣèwádìí àwọn gómìnà àtàwọn mínísítà ọ̀hún lé lórí àti pé EFCC tún ń ṣèwádìí ₦81.6bn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàwárí rẹ̀ pé àwọn kan kó jẹ ní iléeṣẹ́ tó ń rí pípa ìṣẹ́ àti òṣì rẹ́.

    Bákan náà ni wọ́n ní $2.2bn tó yẹ kí wọ́n fi ra nǹkan ìjà ogun lábẹ́ àkóso ààrẹ Goodluck Jonathan, tí wọ́n fẹ̀sùn kan olùbádámọ̀ràn Jonathan lórí ètò àbò, Sambo Dasuki pé òun ló lọ́wọ́ nínú bí owó náà ṣe parẹ́ wà lára àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n gbé dìde padà.

    Lára àwọn gómìnà tẹ́lẹ̀ rí tí wọ́n fẹ́ tún ẹ̀sùn tó wà lọ́rùn wọn gbé dìde padà ni Kayode Fayemi, Ayo Fayose, Bello Matawalle Chimaroke Nnamani, Abdullahi Adamu, Rabiu Kwankwaso, Peter Odili, Theodore Orji, Danjuma Goje, Aliyu Wamako, Timipre Slyva àti Sule Lamido.

    Àwọn mínísítà tẹ́lẹ̀ rí tí wọ́n tún ẹ̀sùn tó wà lọ́rùn wọn gbé dìde ni Olu Agunloye, Sadiya Umar-Farouq àti Betta Edu tí ààrẹ Tinubu ní kí ó lọ rọ́kún nílé lknu ọjọ́ mẹ́ta yìí.

    Ìgbésẹ̀ EFCC yìí kò ṣẹ̀yìn bí àwọn kan tí wọ́n pe ara wọn ní Zamfara Alternative Forum ṣe ṣèwọ́de lọ sí iléeṣẹ́ EFCC tó wà ní Jabi, Abuja pé kí wọ́n ṣàtúngbéyẹ̀wò ẹ̀sùn ₦70bn tó wà lọ́rùn gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Zamfara, Bello Matawalle.

    Alága EFCC, Ola Olukoyede nígbà tó ń fún àwọn ènìyàn náà lésì ní gbogbo àwọn ẹ̀sùn tó wà lọ́rùn àwọn èèkàn ìlú ni àwọn máa gbé dìde láì ní fi ipò tí wọ́n bá wà ṣe.

    Olukeyede, ẹni ti adarí ẹ̀ka tó ń rí sí ọ̀rs ará ìlú gba ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ̀ ní gbogbo àwọn ẹ̀sùn tó wà níwájú EFCC ni àwọn yóò tọná wádìí rẹ̀ àti pé àwọn máa jẹ́ kí ó yé àwọn ará ìlú pé k]o sí ẹni tó ga ju òfin lọ.

  11. Ẹ ò gbọdọ̀ gbowó àìtọ́ lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ - Ìjọba Oyo kìlọ̀ fáwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́ ìjọba

  12. Ààrẹ Felix Tshisekedi wọlé ìbò ààrẹ DR Congo fún sáà kejì

    Aworan Aarẹ Felix Tshisekedi

    Oríṣun àwòrán, Reuters

    Àkọlé àwòrán, Aarẹ Felix Tshisekedi

    Aarẹ Felix Tshisekedi ti wọle ibo aarẹ orilẹede DR Congo fun saa keji.

    Ajọ eleto idibo orilẹede naa kede rẹ gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu ibo ọhun lẹyin to ni ibo ida mẹtalelaadọrin ninu ọgọrunun nigba ti alatako rẹ, Moise Katumbi ni ida mejidinlogun pere.

    Eto idibo naa to waye ni ogunjọ oṣu Kejila ni o kun fun ọpọlọpọ ipenija eleyii to mu ki ibo didi tẹsiwaju di ọjọ keji lawọn apa kan orilẹede naa.

    Ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu ọmọ orilẹede naa ni wọn to sori ila fun ọpọ wakati lati dibo.

    Koda, awọn miiran ti wọn ko le duro pẹ ni lati pada sile wọn nigba ti wọn ko ri ibo di.

    Adari ajọ eleto idibo, Denis Kadima, gba pe awọn kudiẹkudiẹ kan wa ninu eto idibo naa, amọ o sọ pe esi idibo fihan pe aarẹ Tshisekedi naa ni araalu n fẹ.

    Ogunjọ oṣu kinni ọdun 2024 ni wọ yoo ṣe ibura fun Tshisekedi gẹgẹ bi aarẹ DR Congo fun saa keji.

  13. Àwọn agbébọn tún ṣe ìkọlù sí Plateau, wọ́n pa èèyàn méjì

    Aworan awọn agbebọn

    Oríṣun àwòrán, Others

    Eeyan meji ti jẹ ipe Ọlọrun ninu ikọlu miiran ti awọn agbebọn se si ilu Durbi ni Shere nijọba ibilẹ Ila oorun Jos,nipinlẹ Plateau, lọjọ Satide, ọgbọnjọ, oṣu Kejila, ọdun 2023.

    Ikọlu naa waye lẹyin ọsẹ kan ti awọn agbebọn kọlu awọn abule kan ni agbegbe Bokkos, agbegbe Bokkos nijọba ibilẹ Barkin Ladi nipinlẹ naa.

    Ọjọ aisun ọdun Keresi ku ọla ni ikọlu naa waye, eyi to gba ẹmi eeyan to le ni ọgọrun, ti ọpọ si tun farapa.

    Markus Nyam, alaga ijọba ibilẹ ti ikọlu tuntun naa ti waye, sọ fun ileeṣẹ iroyin Channels pe ọganjọ oru ni awọn agbebọn yabo abule naa, ti wọn si sekupa baba kan ati ọmọ rẹ ọkunrin.

    Nyam ni awọn fijilante agbegbe naa le awọn ọdaran naa, ti wọn si ṣekupa ọkan lara wọn.

    Iroyin sọ pe awọn ẹsọ alabo ti de si agbegbe naa lati dena irufẹ ikọlu bẹẹ.

  14. Àwọn ọmọẹ̀yìn àwọn olóṣèlú alátakò ń kojú àwọn ọlọ́pàá lẹ́yìn ìbò ààrẹ lórílẹ̀èdè DRC

  15. Ẹ sinmi irọ́,kò sí òótọ́ nínú ìròyìn pé á bèèrè N2000 lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ gbà iṣẹ́ ọlọ́pàá

    Ajọ to n mojuto iṣakoso ileeṣẹ ọlọpaa lorileede Naijiria,PSC, sọ pe awọn ko ni kawọn to n gbero lati darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa mu ẹgbẹrun meji Naira wa sibi ayẹwo.

    Ajọ naa sọ pe irọ pata ni iroyin yi ati pe awọn to gbe e kalẹ fẹ fi ṣi awọn araalu lọna ni.

    Ninu atẹjade kan ti olori ẹka iroyin ati ibaraẹnisọrọ ajọ naa, Ikechukwu Ani, fi sita, o ni ayẹwo tawọn n ṣe yi ko la owo lọ bẹrẹ lati igba tawọn eeyan ba forukọsilẹ titi di igba ti wọn yoo fi ṣe ayẹwo ilera wọn.

    ''Ko si nkankan to yatọ ti yoo mu ki awọn to fẹ darapọ mọ ọlọpaa mu ẹgbẹrun meji dani lati wa fi ṣe ayẹwo''

    O fikun pe awọn ko ni fara mọ iwa awọn onijibiti to mura kankan lati ba orukọ awọn jẹ lori eto igbaniṣiṣẹ yi.

    Ani wa rọ gbogbo awọn to fẹ darapọ mọ iṣẹ ọlọpaa lati yago fun iroyin ofege yi to si ni awọn ti n fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si awọn to ba jaweolubori pẹlu ilana to kan ninu eto igbanisiṣẹ.

    Iroyin ofege to mu ki wọn fi ikilọ yi sita leleyi tawọn kan kọ sori ayederu iwe pẹlu orukọ ajọ naa to sọ pe ''Ajọ ileeṣẹ ọlọpaa ki ọ ku orire to si ni ko wa fun ayẹwo pẹlu ẹgbẹrun meji Naira lọjọ Kẹjọ oṣu Kini''

    Aworan awọn ọlọpaa ni Naijiria

    Oríṣun àwòrán, Nigeria Police Force

  16. Níbi ìgbìyànjú láti dóòlà ẹ̀mí ọmọ dókítà tí wọ́n jí gbé ní Kwara, fijilanté kàgbákò ikú lọ́wọ́ àwọn agbébọn

  17. Ìjọba àpapọ̀ kéde ìsinmi fún ayẹyẹ ọdún Keresimesi àti ọdún tuntun

  18. Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn nípìnlẹ̀ Ogun

    Afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun ti ọwọ tẹ

    Oríṣun àwòrán, Ogun State Police

    Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun kan, Ademuyiwa Sodiq Akanni.

    Ọwọ tẹ afurasi naa lẹyin ti ikọ ọlọpaa to n gbogun ti ẹgbẹ okunkun yabo ibuba awọn ọm ẹgbẹ okunkun naa.

    Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, SP Omolola Odutola, sọ ninu atẹjade to fi sita pe asiko ti awọn ọlọpaa de ibuba naa lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2023, ni ọwọ tẹ Ọgbẹni Akanni, to jẹ ẹni ọgbọn ọdun.

    O ni ibọn agbelẹrọ kan ni wọn ba lọwọ rẹ.

    SP Odutola sọ pe botilẹ jẹ pe awọn akẹẹgbẹ afurasi naa salọ mọ awọn ọlọpaa lọwọ, o ni ẹka ọlọpaa ti ọrọ kan ti n ṣiṣẹ karakara lati ṣawari wọn.

    Ninu ọrọ to sọ fun awọn ọlọpaa, Akanni sọ pe ẹgbẹ okunkun Buccaneers, ti awọn kan tun mọ si Alora, ni oun n ṣe.

    Agbẹnusọ ọlọpaa ṣalaye pe afurasi ti ọwọ tẹ ọhun ti sọ awọn nnkan pataki ti awọn ọlọpaa nilo lati fi mọ gbogbo ibuba awọn ẹlẹgbẹ okunkun naa.

  19. Tongeji Island: Mọ̀ síi nípa ìlú tí omi Ọ̀sà àti omi Yewa yí kà tó wa ní ẹnu bodè Naijiria

  20. Irọ́ ni ìròyìn tó sọ pé àrùn Covid-19 tún padà ṣẹ́yọ ní Naijiria – Ìjọba àpapọ̀