Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika
Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye
Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́
Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan
“Èèyàn 11,240 ló ti bá ogun Gaza lọ báyìí”

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Apapọ iye eeyan to ti jade laye ni Gaza lati ọjọ keje, oṣu Kẹwaa ti jẹ 11,240 bayii.
Ijọba Gaza, eyii ti Hamas n dari lo kede bẹẹ ninu atẹjade kan.
Lara awọn to ku naa ni ọmọ wẹwẹ 4,630 wa, pẹlu obinrin ti iye wọn jẹ 3,130, gẹgẹ bii ohun ti agbẹnusọ ijọba naa sọ.
Ajọ eleto ilera agbaye, WHO sọ pe oun gbagbọ ninu iye awọn eeyan ti Hamas n kede pe wọn jade laye.
Wayi o, ọpọ eeyan kaakiri agbaye lo ti bẹrẹ si n bu ẹnu atẹ lu ogun naa, ti wọn si n ke si igun mejeji kin wọn dawo ogun ọhun duro.
GWR Cook-a-Thon : Tope Maggie bẹ̀rẹ̀ láti dáná oúnjẹ wákàtí igba láì dáwọ́rọ

Alase ọmọ bibi Ogbomoso, Tope Maggie, ti bẹrẹ ounjẹ sise oni igba wakati lati ni akọsilẹ tuntun fun ẹniti o le ṣe ounje fun wakati to gun julọ lagbaye.
Ounje ṣiṣe naa yoo waye fun ọjọ mejo titi ti wakati igba ọhun naa yoo fi pe.
Irọlẹ Ọjọbọ,ọsẹ to kọja ni eto igbiyanju rẹ lati kọ itan tuntun fun eto Guinness world Record rẹ bẹrẹ.
Eto ina dida naa si n waye ni gbagede Recreation Club Ogbomoso to koju si ile iwe ti wọn ti n kọ nipa iṣegun ara lagbegbe isalẹ General Ogbomoso nipinlẹ Oyo.
Ti ẹ o ba bagbe, laipẹ yii ni omo orileede Ireland kan, Alan Fisher, ti o ni ile ounjẹ ni Japan, ti fọ akọsilẹ ti Hilda Bassey ọmọbirin orilẹ-ede Nigeria ti ṣaaju ko nigba ti o ṣe ounjẹ fun wakati mọkandinlọgọfa.
Hilda Bassey ti saaju dana ounjẹ fun wakati mẹtalelaadọrun ki Fisher to ba akọsilẹ naa jẹ.
Tope Maggie, eni ti o loun ba iṣẹ ounjẹ sise lọwọ iya re, ni ile ounje ni ilu Ogbomọṣọ ti o si ti ṣe ounjẹ fun gomina mẹta otọọtọ nipinle Oyo.

Oríṣun àwòrán, Tope Maggie
Ta ni Duoye Diri tí àwọn olùdìbò yàn sípò gómìnà fún sáà kejì ní Bayelsa?
Àbájáde ìpàdé ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó pẹ̀lú àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ lórí ìfẹ̀hónúhàn àwọn awakọ̀ rèé
INEC: Ìdìbò tuntun yóò wáyé láwọn wọ́ọ̀dù tí màgòmágó tí ṣẹlẹ̀ ní Kogi
Ajọ eleto idibo Naijiria ti mu ileri rẹ ṣẹ nipa gbigbe abajade iwadii rẹ jade lori magomago to waye lawọn ibudo idibo kan nipinlẹ Kogi.
Ni bayii ajọ naa s pe idibo tuntun yoo waye lawọn ibudo idibo yi lọjọ Kejidinlogun oṣu Kọkanla.
Ninu atẹjade ti ajọ naa fi sita, wọn ni awọn gbọ abọ iwadii lawọn ijọba ibilẹ mii yatọ si ti Ogori Magongo ti wọn ti fidi rẹ mulẹ pe magomago waye lasiko idibo Gomina ipinlẹ Kogi.
Awọn ibudo idibo yoku ni ijọba ibilẹ ti ọrọ kan ni
- Adavi ibudo idibo marun un(wọọdu Okunchi/Ozuri/Onieka)
- Ajaokuta ibudo idibo marun (wọọ́du Adogo)
- Okehi(ibudo idibo kan ni wọọdu Eika/Ohizenyi)
- Okene ibudo idibo marun un ni wọọdu Obehira Uvete
Ni ti Ogori/Magongo ti ọrọ magomago ti pọju, esi wọọdu Oshobane II to ni ibudo idibo mẹjọ ti awọn oludibo 2,264 si forukọsilẹ nibẹ ni wọn ti ko jọ.
Idibo to waye lawọn ibudo idibo mkandinlọgbọon yoku ni wn ṣi so rọ naa.

Oríṣun àwòrán, INEC
Dino Melaye fìdí rẹmi ní ìjọba ìbílẹ̀ rẹ̀ nínú ìbò gómìnà Kogi, APC ló wọlé níbẹ̀

Oríṣun àwòrán, Dino Melaye/Facebook
Àkọlé àwòrán, Aworan Dino Melaye Oludije fun ipo gomina nipinlẹ Kogi labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Dino Melaye, ti padanu ijọba ibilẹ rẹ ti i ṣe Ijumu ninu ibo to waye lọjọ Satide.
Usman Ododo, oludije fun ipo yii kan naa ninu ẹgbẹ oṣelu APC ni Inec wọn kede pe o jawe olubori nijọba ibilẹ ti Melaye ti wa.
Abajade ibo naa bi ajọ INEC ṣe kede ẹ lọjọ Aiku ọsẹ yii, fidi ẹ mulẹ, pe ibo ẹgbẹrun mẹwaa ati ẹrin-le-ni-okoo-le-ni ẹẹdẹgbẹta(10, 524) ni Usman Ododo ni, nigba ti Dino Melaye lati PDP ni ibo ẹgbẹrun mẹfa, ọrundinlẹgbẹrun ati mẹsan-an (6,909).
Atupalẹ awọn ibo naa ree bi INEC ṣe kede ẹ
Iye oludibo:66, 482
Awọn to forukọ silẹ: 20,405
ADC: 1,898
APC: 10, 524
PDP: 6,909.
SDP: 356
Ibo to kunju oṣuwọn: 19,991
Ibo ti o ṣee ka: 348
Apapọ ibo ti wọn di: 20,375
APC lewaju nínú èsì ìbò kíkà tó n wáyé ní ìpínlẹ̀ Kogi
Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress lo n lewaju bayii ninu esi ibo kika ti ajọ eleto idibo Inec n ka lọwọ bayii ni ilu Lokoja.
Ninu ipinlẹ mejidinlogun ti wọn ti kede esi wọn bayii, Apc ti jaweolubori ninu ipinlẹ mọkanla,Sdp gbegba oroke ni ijọba ibilẹ mẹfa ti ẹgbẹ Adc si mu ijọba ipinlẹ kan sabẹ.
Ijọba ibilẹ mẹta lo ku ti wọn yoo kede ti aṣoju Inec si ni awọn yoo tẹsiwaju pẹlu kika esi naa ni ago mẹrin .
Ninu esi taa ri yi ẹgbẹ oṣelu Pdp ko mu ijọba ibilẹ kankan ti o si jọ pe ifigagbagba to n waye wa laarin ẹgbẹ SDP ati Apc botilẹwu ko jẹ pe Apc ya awọn ẹgbẹ toku silẹ nipa iye ibo ti wọn ri gba.
Oludije ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, Dino Melaye ti n ke gbajare pe wuruwuru waye ninu idibo ọhun ati peohun ti oun fẹ ni ki wọn wọgi le gbogbo eto idibo naa.
Lara ariwo to pa lo mu ki ajọ eleto idibo Inec sọ pe ki wọn so idibo rọ lawọn wọọdu mẹsan an kan ni ijọba ibilẹ Ogori Magongo.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Alhaji Ahmed Usman Ododo
Hope Uzodimma jáwé olúborí ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Imo fún sáà kejì
Kogi election: INEC ní kíkéde èsì ìbò yóò bẹ̀rẹ̀ ní aago mẹ́wàá

Ajọ to n ri si eto idibo ni Naijiria, INEC ti kede pe aago mẹwaa owurọ ọjọ Aiku ni kikede esi ibo ni ipinlẹ Kogi yoo bẹrẹ.
Ọga agba INEC ni Kogi, Ọmọwe GabrielLongpet lo kede ọrọ naa nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ ni ilu Lokoja.
Ni ijọba ibilẹ mọkanlelogun to wa ni Kogi ni eto idibo sipo gomina ti waye lọjọ Abamẹta, ọjọ Kọkanla, oṣù Kọkanla ọdun 2023.
INEC ni awọn oṣiṣẹ awọn kan fidi rẹ mulẹ fun awọn pe awọn kan gbero lati ṣeru nibi eto idibo naa.
Wọn ni awọn kan ti n kọ esi ibo silẹ lai ṣe wi pe awọn ti bẹrẹ si ni ka ibo ati pe eyi lo ṣokunfa ti awọn fi wọgile eto idibo ni awọn wọọdu kan.
Wọn fi kun un pe awọn agbegbe kan wa to jẹ iroyin nipa magomago ti wọn ṣe lasiko ibo naa han to si gbode kan.
Awọn agbegbe bii Adavi, Ajaokuta, Ogori/Magongo, Okehi ati Okene ko moribọ ninu magomago ibo bi INEC ṣe sọ ọ di mimọ, awọn eyi to si le ju nibẹ, Ogori/ Magongo lo ti waye ju. Ibudo iforukọsilẹ mẹsan-an ni wọn lo faragba a ninu mẹwaa to wa nibẹ.
‘’ A ko faramọ iru eyi rara, ibo yoowu ti wọn ko ba ti di lọna ẹtọ ko ni i jẹ kika.
‘’Ajọ INEC ko ṣetan lati fọwọ bo ibajẹ mọlẹ, nitori ẹ la ṣe da ibo awọn ibudo idobo mẹsan-an yẹn duro’’
Bẹẹ ni INEC wi ninu atẹjade kan ti Mohammed Kudu, Alakooso nipa dida awọn ara ilu lẹkọọ lẹkọo lori eto ibo fọwọ si.
Gẹgẹ bi wọn sẹ wi, iwadii n tẹsiwaju lori awọn ibo to waye lawọn ijọba ibilẹ yooku naa, abajade gbogbo eyi to ku naa yoo si bẹrẹ si i jade laipẹ.
INEC so ìdìbò rọ̀ ní wọ́ọ̀dù mẹ́sàn án Ogori/Magongo
Njẹ idibo Kogi ko ni jasi pe ko ni yanju bayii?
Ibeere to gbẹnu awọn araalu re lẹyin ti ajọ eleto idibo Inec kede pe ki wọn so idibo rọ ni wọọdu mẹsan an nijọba ibilẹ ogori Magongo.
Loju opo wọn ni Twitter X ni wọn fi ikede yi si lọjọ Abamẹta lẹyin ti awuyewuye pọ lori idibo naa .
Bakan naa ni oludije ẹgbẹ oṣelu PDP Sẹnẹtọ Dino Melaye to jẹ ọkan ninu awọn oludije ti kọkọ ke gbajare wi pe magomago n waye ni ijọba ibilẹ Ogori Magongo ti wọn si ti bẹrẹ si ni tẹ esi idibo ṣaaju ki idibo toi waye.
Inec sọ ninu atẹjade wọn ti Mohammed Kudu Haruna to jẹ kọmiṣana eto ipolongo ajọ naa fi sita pe awọn ko ni gba eyikeyi esi to ba wa lati ibudo idibo ti wọn ti n ṣe magomago ni paapa kikọ esi ṣaaju ki idibo to waye.
Awọn ijọba ibilẹ ti ajọ naa darukọ ni Adavi, Ajaokuta,Ogori Magongo Okehi ati Okene.
Wọn tẹsiwaju pe ibi ti iwa aburu yi ti pọ julọ ni ''Ogori Magongo''
Tori naa Inec lawọn ko ni faaye gba iwa buruku yi ti wọn yoo si so idibo r naa ni wọọdu mẹsan an ni Ogori Magongo iyẹn Eni, Okibo,Ileteju,Aiyeromi,Ugugu,Obinoyin,Obatgben, ati Oturu.
Wọn ni iwahii n tẹsiwaju lawọn ijọba ibilẹ to ku ati pe awọn yoo kede abajade iwadii naa laarin wakati mẹrinlelogun.
Lakotan Inec lawọn ni akojọpọ orukọ gbogbo awọn oṣiṣẹ awọn to wa lawọn aaye wọnyii.
Ijiya to tọ ni wọn lawọn yoo fi jẹ ẹnikẹni ti wọn ba ka iwa buruku mọ lọwọ.

Oríṣun àwòrán, Inec
Ojú wà rí ìṣẹlẹ dìbò kó o sebẹ̀ ní Bayelsa- Òǹwòye ètò ìdìbò labẹ́lè
Onwoye eto idibo labẹle kan to n foju wo bi idibo ipinlẹ Bayelsa ṣe n lọ ti sọ pe awọn eeyan ṣe karakata ibo lasiko idibo ọhun.
Iwa yi taa mọ si iwa dibo ko o sebẹ jẹ ọkan lara awọn kudiẹ kudiẹ to wa ninu eto idibo lorileede Naijiria.
Sylvester Okoduwa to jẹ ọkan lara awọn onwoye idibo Bayelsa to wa lati ẹgbẹ Transition Monitoring Group sọ fun BBC pe awọn woye pe awọn eeyan ko jade lati wa dibo lọpọ aaye.
O ni ''Ohun kan to han kedere ni pe iṣọwọ karakata ibo ga gaan .Koda wọn o gbe pamọ rara.''
O fi kun pe ''mi o fẹ ṣakoba fawọn agbofinro kọọkan nipa ki n sọ pe wọn o mọ nipa dibo ko o sebẹ.''
Lakotan o ni iru iṣẹlẹ bayii ko da fun idagbasoke eto idibo lorileede Naijiria.
Labẹ ofin idibo, ijiwa fun awọn ti ọwọ ba tẹ wi pe wọn n ta tabi ra ibo amọ lọpọ igba ti wọn ba mu awọn to hu iwa bayii, a kii gbọ nkan to ṣẹlẹ si wọn lẹyin idibo.

Ètò ìdìbò tí n kásẹ̀ nilẹ̀,ní Lokoja wọn tí n ká èsì ìbò láwọn ibùdó kọọkan
Lati ilu Lọkọja,eto idibo ti n kasẹ nilẹ ni awọn ibudo idibo kọọkan.
Awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo n duro ki aago meji aabọ ọsan lu ki wọn to bẹrẹ sini ka ibo.
Ibo ti pari lati agbegbe Rimi Centre ni Lọkọja. Wọn si ti bẹrẹ si ni ka ibo nibẹ.
Aworan ree to ṣafihan bawọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo ti n ka esi iboto waye ni ibudo idibo naa.



Ọlọ́pàá Bayelsa ṣalàye ọ̀rọ̀ nípa ìyìnbọn tó wáyé ní Yenegoa

Oríṣun àwòrán, bbc
Commissioner ọlọpaa nipinlẹ Bayelsa, CP Kolade Alausa ti fidi ọrọ ikọlu to waye ni agbegbe Famgbe ni ijọba ibilẹ Yenegoa mulẹ.
O ni nibi iṣẹlẹ yi, ọta ibọn ba eeyan meji.
Kọmiṣana ọlọpaa Alausa sọ fun BBC pe awọn meji yi si ti n gba itọju lọwọ ni ile iwosan ijọba apapọ to wa ni Yenegoa.
Ko darukọ awọn to yinbọn mọ wọn tabi boya awọn ti mu awọn to ṣe ikọlu yi.
O ni oun ti fi awọn agbofinro ranṣẹ si agbegbe naa lati ṣe iwadii ẹkunrẹrẹ.
Lafikun, o parọwa si awọn to ba faragbọta ibọn lati tara fẹjọ sun lagọ ọlọpaa ki wọn baa le ri itọju to peye kawọn si le bẹrẹ iwadii naa lasiko.
Ẹwẹ gbogbo nkan ti pada si bo ṣe yẹ ti idibo si n tẹsiwaju.
O rọ awọn ọmọ ipinlẹ naa lati ṣe ohun gbogbo ni ibamu pẹlu ofin.
Goodluck Jonathan: O yẹ kí a wá nkán ṣe sí ìdìbò tí àkókó rẹ̀ yàtọ sí tí àpapọ̀ táa n ṣe

Aarẹ orileede Naijiria tẹlẹri Goodluck Jonathan ti sọ ero rẹ nipa idibo ti akoko rẹ yatọ si idibo apapọ lorileede Naijiria.
O ni o ti to saiko bayii ti ile aṣofin Naijiria gbọdọ wa nkan ṣe lati yi iṣẹlẹ idibo yii nipa atunṣe ofin to de eto idibo Naijiria.
Lẹyin to di ibo rẹ tan ninu idibo Gomina ipinlẹ Bayelsa to n waye lo fidi ọrọ yi mulẹ ni Otuoke.
Jonathan sọ pe lootọ ni idibo to n waye lonii lọ ni irọwọrọsẹ amọ o ni leyi to bojumu ni pe ko yẹ ki awọn idibo kan maa waye lasiko to yatọ si ti gbogbogboo ni Naijiria.
''A ni lati kọdi iru idibo yi. Ko ba nkan to n ṣẹlẹ lawọn orileede to ti gun oke agba mu.''
O fiklun pe ''Ti a ba tẹsiwaju pẹlu iru idibo tasiko rẹ yatọ yi,a le baa debi pe idibo apapọ ti aarẹ naa yoo maa waye lasiko to yatọ si igba to yẹ ko waye''
O ni awọn eeyan le maa wo pe bawo ni iru nkan bayii ṣe le waye.
O ṣalaye pe iru rẹ fẹẹ waye tan diẹ loku lọdun 2007 ti mo dije dupo gẹgẹ bi igbakeji aarẹ pẹlu Umaru Musa Yar'Adua.
Ipinlẹ meje ni yoo ṣeto iru awọn idibo yi lorileede Naijiria.
Mẹta lo n kopa ninu idibo Gomina lopin ọsẹ yi-Bayelsa, Kogi ati Imo.
A ti bẹ̀ẹ̀rẹ̀ ìwadìí ẹ̀sùn kíkọ èsì ṣáájú ìdìbò ní Kogi- INEC
Ajọ INEC lo ti fesi si awọn ẹsun ti ajọ YIAGA ati Sẹnetọ Dino Melaye fi kan wọn pe wọn ti kọ esi ibo lawọn agbeegbe kan nipinlẹ Kogi ṣaaju ki eto idibo o too bẹrẹ.

Oríṣun àwòrán, @YIAGA
Sẹnetọ Melaye to jẹ oludije sipo gomina nipinlẹ naa lẹgbẹ oṣelu PDP lo ti kọkọ paruwo lori ẹrọ ayelajura ko too di pe ajọ YIAGA naa figbe bẹnu lori ọrọ ọhun.
Ẹwe, INEC ti wi pe awọn oṣiṣẹ ajó naa ti bẹrẹ iwadi lori iṣẹlẹ naa lati mọ ohun to ṣẹlẹ ni pato.
Ẹ gbà wá o! Wọ́n ti kọ èsì sílẹ̀ ní Ogorimagongo láì tíì dìbò – Dino Melaye fi igbe ta

Oríṣun àwòrán, Facebook/Dino Melaye
Oludije sipo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Kogi, Sẹnetọ Dino Melaye, lo ti kigbe lori ẹrọ ayelujara pe wọn ti kọ esi ibo ṣaaju idibo lawọn agbeegbe kan ni Ogorimagongo.
Sẹnetọ naa wi pe awọn oludibo ni Ogorimagongo lo ti fariga ti wọn ko si gba ki eto idibo o waye nitori eyi, ti wọn si n beere fun iwe esi ibo tuntun.
Dino, to ke gbajare lori ikanni X (twitter), wi pe ki awọn aṣoju ẹgbẹ PDP lawọn oriko idibo jakejado ipinlẹ naa o rii daju pe gbogbo iwe esi ibo tawọn oṣiṣẹ ajọ INEC ba ko wa ni wọn ko tii kọ ohunkohun si.
O fi kun pe to ba ni awọn oriko ti wọn ti kọ esi ṣaaju eto idibo, ki awọn ololufẹ ati ọmọ ẹgbe ohun to wa nibẹ kọ lati jẹ ki eto idibo o gbera sọ, ki wọn si fi ẹrọ ilewọ wọn ya gbogbo bo ba ṣe n lọ sori ẹrọ ayelujara.
, Duoye Diri ti ẹgbẹ́ oṣelu PDP to n dije dupo gomina ipinle Bayelsa ti dibo
Duoye Diri ti ẹgbẹ́ oṣelu PDP to n dije dupo gomina ipinle Bayelsa ti dibo

Oríṣun àwòrán, Bayelsa Govt House
Àkọlé àwòrán, Duoye Diri ti ẹgbẹ́ oṣelu PDP to n dije dupo gomina ipinle Bayelsa ti dibo Ètò ìdìbò kò tíì bẹ̀rẹ̀ ní agbèègbè Cantonement ní Lokoja
O yẹ ki eto idibo ti bẹrẹ ni Ward B, unit 006, ni agbegbe 'Cantonement' niluu Lọkọja, ṣugbọn awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo yari wi pe awọn ko ni ko ohun elo bọọlẹ ninu ọkọ, nitori pe awọn ẹṣọ abọ ko tii de.
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ ajọ naa ṣe alaye fun wa wi pe awọn kan ti ba ara wọn ja laarọ oni ni ibudo idibo naa, eyii lo mu wọn takete pe o di igba ti awọn agbofinro ba de ki eto idibo to bẹrẹ.



Àjọ elétò ìlera tó n mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì, ‘Red Cross’, wà ní ìkàlẹ̀ níbi ètò ìdìbò tó n lọ lọ́wọ́ n’ìpínlẹ̀ Kogi
Wọn ni pe ko ni si aaye pẹ ẹnikan wa farapa ko dẹ wa ri itọju lasiko ni ipinlẹ Kogi.
