Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Ghana àti South Africa tọwọ́bọ àdéhùn láti máa wọ orílẹ̀ èdè arawọn láì lo físà

    Aarẹ Ghana ati aarẹ South Africa

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    Orilẹ-ede Ghana ati South Africa ti tọwọbọ adehun pe awọnọmọ orilẹ-ede mejeji le maa wọ orilẹ ede arawọn lai gba iwe iwọlu ti a mọ si “visa”.

    Ohun ti eyi tumọ si ni pe iwe irinna nikan ni awọn ọmọ orilẹ ede mejeeji yii nilo lati wọ orilẹ arawọn lati lo aadọrun-un ọjọ.

    Atẹjade kan ti Minisita to n risi ọrọ ilẹ okere ni orilẹ-ede Ghana fi lede ni lati ọjọ Kiini, osu Kọkanla, ọdun 2023 ni ilana tuntun yoo bẹrẹ.

    Lẹyin ti aadọrun-un ọjọ ba pe ti ẹni to rinrinajo yii ṣi fẹ maa wa ninu awọn orilẹ ede yii, onitọhun yoo ṣẹṣẹ gba iwe aṣẹ lati tunbọ wa ninu orilẹ ede naa.

    Atẹjade kan lati ile iṣẹ South Africa to wa ni Ghana ni ti kii ba ṣe inu ọdun kan ni gbogbo awọn aadọrun-un ọjọ yii bọ si, onitọhun ko ni gba iwe igbelu.

    Ṣaaju asiko yii, awọn ọmọ orilẹ-ede Ghana ati South Africa maa n nilo fisa lati wọ orílé ede arawọn.

    Awọn ọmọ Ghana ko ni anfani pe ti wọn ba de South Africa ki wọn to gba fisa gẹgẹ bo ṣe wa fun awọn orilẹ ede kan tẹlẹ amọ ti anfani naa ti wa fun wọn bayii.

    Gbigba fisa lọ si South Africa lati Ghana maa n gba ọpọlọpọ ọsẹ tabi oṣu nitori awọn eniyan maa n pọ nibẹ.

    Nigba to n ba BBC sọrọ, Ernest Apraku ṣalaye pe o gba oun to oṣu meji lẹyin ti oun kọwe lati gba fisa lọ si orilẹ-ede South Africa fun isinmi.

    O fi kun pe pẹlu igbesẹ tuntun yii, o maa din gbogbo iṣoro ati ọpọlọpọ wahala lati gba fisa ku fun awọn ọmọ orilẹ-ede naa.

    Ninu oṣu Kẹsan-an ọdun yii, adẹrininpoṣonu kan ni Ghana, OB Amponsah kò ribi kopa nibi ayẹyẹ awada kan ni South Africa ti awọn akẹgbẹ rẹ n ṣe.

    O kọ sori ayelujara nigba naa pe oun ko ribi kopa nibi ayẹyẹ naa pẹlu gbogbo wahala ti oun ṣe lati ri iṣẹ naa gba latari bi oun ko ṣe ri fisa gba.

    Lẹyin ti wọn kede igbesẹ tuntun yii, o ni aarẹ orilẹ ede awọn ṣe dada pẹlu ohun ti wọn ṣe yii.

  2. Ọkọ̀ mọ́kànlá jóná bí táńkà agbépo ṣe gbaná ní Eko

    Awon oko to jona

    Oríṣun àwòrán, @LagosRescue/TWITTER

    Àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko ìyẹn Lagos State Emergency Management Agency, LASEMA ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn ló há sínú ìjàm̀bá iná bí táńkà agbépo méjì kan ṣe gbaná ní ìpínlẹ̀ náà.

    Ní agbègbè Costain ní ìjàm̀bá náà ti wáyé lálẹ́ ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kejìlá oṣù Kẹwàá ọdún 2023.

    Ọ̀gá àgbà àjọ LASEMA, Dókítà Olufemi Damilola Oke-Osanyintolu nínú àtẹ̀jáde tó fi léde ní ọ̀kan nínú àwọn táńkà náà ló fẹ́ gun afárá Costain ọ̀hún kó tó yẹ̀ padà sẹ́yìn.

    Oke-Osanyintolu ṣàlàyé pé bí ọkọ̀ táńkà náà ṣe yẹ̀ padà sẹ́yìn náà ló lọ kọlu ọkọ̀ táńkà mìíràn àtàwọn ọkọ̀ míì tó wà lẹ́yìn rẹ̀, tí àwọn táńkà náà sì gbaná lójú ẹsẹ̀.

    Ó ní àwọn kò ì tíì lè fìdí iye ènìyàn tó há sínú ìjàm̀bá náà múlẹ̀ àmọ́ àwọn ọkọ̀ tó wà nínú ìjà a náà lé ní mẹ́fà.

    Ó ní ọ̀pọ̀ àwọn ọkọ̀ ńlá tó wà nínú ìjàm̀bá náà ló kó àwọn ẹrù tí àwọn kò lè sọ pàtó ohun tó wà nínú wọn.

    Àjọ panápaná Eko nínú àtẹ̀jáde tó fi léde lórí X ní àwọn ti pa iná náà àti pé iṣẹ́ ń lọ láti kó àwọn ọkọ̀ tó jóná náà kúrò lọ́nà.

    Ọ̀gá àgbà àjọ náà, Margaret Adeseye ní ọkọ̀ mọ́kànlá ní àpapọ̀ ló bá ìjàm̀bá iná náà lọ.

    Skip X post
    Allow X content?

    This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

    Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

    End of X post

  3. Ẹ máà pín owó rìbá yín kàn mí, ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá kìlọ̀ f’áwọn ọlọ́pàá

  4. Ta ni Ola Olukoyede, pásítọ̀ ìjọ RCCG tó di alága EFCC?

  5. Ìjọba Nàìjíríà ti dá ìrìnàjò lọ sí ilẹ̀ mímọ́ Israel dúró báyìí

  6. Iná sọ ní pápákọ̀ òfurufú, ọkọ̀ 1500 jóná ráúráú, Isẹlẹ yii lo waye ni lojọ Isẹgun ni nnkan bi ago mẹta ni papakọ ofurufu Luton, ni ilẹ Gẹẹsi.

    Aworan isẹlẹ ina

    Awọn alasẹ Ileeṣẹ Ofurufu ti wọgile gbogbo irina ọkọ ofurufu ni papakọ ofurufu lẹyin ti isẹlẹ ina nla kan waye ni papakọ ofurufu, ti ọkọ ayọkẹlẹ o le ni ẹgbẹrun kan si jona.

    Isẹlẹ yii lo waye ni lojọ Isẹgun ni nnkan bi ago mẹta ni papakọ ofurufu Luton, ni ilẹ Gẹẹsi.

    Osisẹ Ileeṣẹ panapana mẹrin ati osisẹ ileeṣẹ papakọ ofurufu kan lo ti di ero Ile wosan, ti isẹlẹ ina naa si ṣe wọn ni ijamba.

    Eeyan mii ti wọn ṣe itọju rẹ ni bi ti isẹlẹ naa ti waye ni o da pe ko fi ara ṣeeṣe pupọ.

    Ariwo ọkọ ati ibugbamu isẹlẹ ina ọhun ni ọpọ gbọ, ti oṣojumikoro si salaye bi ina naa ṣe si orule ibi gbagede igbọkọ si jẹ ohun to yanilẹnu.

    Awọn alasẹ ileeṣẹ ofurufu naa ni awọn yoo sisẹ pọ pẹlu osisẹ panapana lati ri pe awọn doola ẹmi awọn arin irinajo ati awọn osisẹ ileeṣẹ ofurufu to tumọ sipe awọn ti wọgile gbogbo irinajo.

    Onimọ nipa irinajo, Simon Calder ni oun ni igbagbọ pe yoo to ẹgbẹrun lọna ogoji si aadọta eeyan to ni lati wọgile irinajo wọn lẹyin isẹlẹ naa waye, ti ileeṣẹ ofurufu si n reti iranlọwọ laipẹ.

  7. Kí ni ìdájọ́ ikú? Ìgbà wo ni wọ́n máa ń pa ẹni tí wọ́n bá dájọ́ ikú fún?

  8. Ìjọba Nàìjíríà rán èèyàn sí Igboho lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Benin láti jáwọ́ lórí Yoruba Nation kí wọ́n lè fi sílẹ̀ – Banji Akintoye

  9. ‘Ẹgbẹ̀ òkùnkùn wù mí láti darapọ̀ mọ́ ni mo ṣe darapọ̀, wọn kò fi ipá mú mi’

  10. O ní ohun tí mo ń bá Peter Obi jà sí -Lamidi Apapa, alaga ẹgbẹ́ òṣèlú LP

  11. Ó ní ìdí tí mo fi ní kí wọ́n sin òkú ọmọ mi ní kíákíá, Bàbá Mohbad ṣàlàyé

  12. Ìṣẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ rírì mú ẹ̀mí èèyàn 15 lọ ni Afganistan, 78 míì farapa yánayàna

    earthquake

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    O kere tan, eeyan marundinlogun lo ti jade laye ni Afganistan ti awọn awọn mejidinlọgọrin mii si farapa yanayana lẹyin iṣẹlẹ ilẹ riri to waye nibẹ.

    Aṣoju ijọba orilẹ-ede naa kan ṣalaye pe ọpọ ile lo dawo, ti awọn eeyan si ha sabẹ awọn ile naa.

    Ọkan lara awọn olugbe agbegbe ibi ti isẹlẹn aa ti waye, Bashir Ahmad sọ fun ileeṣe iroyion AFP pe “Inu ọọfisi ni a wa nigba ti a ṣakiyesi pe ile naa n mi titi, ti awọn nnkan ti wọn fi rẹ ile ọhun si bẹrẹ si n jabọ ki apakan rẹ to dawo.”

    “Mi o tii ri aye ba awọn mọlẹbi mi sọrọ bayii nitori itakun ibaraẹnisọrọ ti ja, ẹru n ba mi nitori mi o mọ irufẹ ipo ti wọn wa.”

    Wayi o, awọn eeyan ti wọn ṣeṣẹ ti wa nile iwosan bayii nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ.

    Ninu oṣu Kẹfa ọdun to kọja ni irufẹ iṣẹlẹ bayii kọlu agbegbe Paktika ni orilẹ-ede yii kan naa, eyii to mu ẹmi ẹgbẹrun kan eeyan lọ.

  13. DPO àtàwọn ọlọ́pàá míì fara gbọta níbí aáwọ̀ tó tún bẹ́ sílẹ̀ láàrin Ifon àti Ilobu l'Osun

  14. Ìgbẹ́jọ́ Nnamdi Kanu ti bẹ̀rẹ̀ nílé ẹjọ́ tó ga jùlọ l'Abuja

  15. Àràmàǹdà tíṣà kan rèé tó ń fi èdè Yorùbá kọ́ ìmọ̀ ìṣirò "Mathematics" lórí ayélujára

  16. Ilé ìjọsìn Dunamis dàwó, pásítọ̀ kan dágbére fáyé

    Ilé ìjọsìn tó dàwó

    Oríṣun àwòrán, Others

    Ile ijọsin Dunamis to wa ni agbegbe Mission Ward North Bank niluu Makurdi, olu ilu ipinlẹ Benue lẹkun aarin gbungbun ariwa orilẹ ede Naijiria ti da wo lowurọ ọjọ Iṣẹgun.

    Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe ile ijọsin naa wo pa ọkan lara awọn pasitọ ijọ naa.

    Gẹgẹ bi ohun ti awọn eeyan kan nibẹ sọ, awọn eeyan mẹrin lo wa ninu ile ijọsin naa ti wọn n gba adura lasiko ti ile ijọsin naa da wo.

    Pasitọ yii nikan lo ku nibẹ, ti ori si ko awọn mẹta yooku yọ.

    Awọn ile to wa ni ayika ile ijọsin naa, atawọn opo ina ẹlẹntiriki to wa nibẹ ni wọn fara gba iṣubu ile ijọsin ọhun.

    Ko tii si ẹni le sọ ni pato ohun to ṣokunfa iṣẹlẹ ijamba naa.

    Ilé ìjọsìn Dunamis tó dàwó

    Oríṣun àwòrán, Others

  17. Àwọn kókó ohun tó mú kí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC, TUC wọ́gilé ìyanṣẹ́lódì wọn ní Nàìjíríà

  18. A kò fẹ́ ọlọ́pàá mọ́! Aráàlú faraya lẹ́yìn tí àwọn ajínigbé pa èèyàn nílùú Alalubosa

  19. Wo àwọn kókó ìpàdé láàrín ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC pẹ̀lú TUC, tó ń mú àwọn ọmọ Nàìjíríà wòye pé ìjà ti tán

  20. Àwọn ajínigbé tó jí àwọn akọrin gbé ní ìpínlẹ̀ Ondo ti ń kàn sí wa lórí ohun tí wọ́n fẹ́ - Àlùfáà Ìjọ