Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Ìjọba ìpínlẹ̀ Kaduna kéde kónílé-ó-gbélé

    Aworan gomina ipinlẹ Kaduna

    Ijọba ipinlẹ Kaduna ti kede konile-o-gbele oniwakati mẹrinlelogun ni olu ilu ipinlẹ naa ati ilu Zaria.

    Ijọba ipinlẹ naa gbe igbesẹ yii “lẹyin ayẹwo ipo ti eto abo wa ni ipinlẹ naa nipasẹ iwọde to n waye” lẹyin ti awọn iwọde waye lawọn agbegbe kan ni ipinlẹ naa.

    Atẹjade kan ti ijọba ipinlẹ Kaduna fi sita sọ pe “ẹri to daju wa pe awọn kọlọrọnsi kan ti ja iwọde naa gba, wọn si ti bẹrẹ si nii lo o lati fi jale ati lati ba awọn dukia ijọba jẹ.”

    Samuel Aruwan kọmiṣọna fun ọrọ abo ni ipinlẹ Kaduna, to fọwọ si atẹjade naa rọ awọn eeyan ipinlẹ naa lati maa tẹle ofin ki wọn si wa ninu ile koowa wọn, lasiko ti awọn agbofinro ba n ba iṣẹ wọn lọ lati rii pe abo to peye wa fun gbogbo mutumuwa nibẹ.

    Awọn ipinlẹ miran to ti kede ofin konile-o-gbele lati igba ti iwọde yii ti bẹrẹ ni Ọjọbọ ni Kano, Jigawa, Borno, Yobe, Kaduna ati Plateau.

    Amọṣa awọn kan lara awọn ipinlẹ naa ti wọgile ofin naa.

  2. Arábìnrin tó gbé ìkòkò tí kò sí nǹkan nínú rẹ̀ lọ síbi ìwọ́de l'Eko ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀

  3. Ìgboro ìlú Kano dá páropáro nítorí ìséde tí ìjọba kéde lẹ́yìn tí rògbòdìyàn wọ ìwọ́de níbẹ̀

    Aworan bi igboro ṣe da ní ilu Kano nitori konile o gbele.

    Paroparo ni awọn oju popo da nipinlẹ Kano latigba ti Gomina Abba Yusuf ti kede ofin konile-o-gbele, latari iwọde to di rogbodiyan nipinlẹ naa.

    Aworan bi igboro ṣe da ní ilu Kano nitori konile o gbele.

    Aṣoju ikọ iroyin BBC ni Kano, ṣalaye pe ko si mọto ni titi, bẹẹ ni awọn eeyan perete ni wọn n fẹsẹ rin lẹsẹkuku, ti ko jinna si ile wọn.

    Aworan bi igboro ṣe da ní ilu Kano nitori konile o gbele.

    Awọn eeyan ti wọn tun n jokoo ni meji-mẹta leeyan tun le ri ni Kano bayii gẹgẹ bi iwadii BBC.

    Iwaju ile kaluku wọn si ni wọn n jokoo si, ti wọn n takurọsọ.

    Aworan bi igboro ṣe da ní ilu Kano nitori konile o gbele.

    Ko si ọja tita yanturu ti gbogbo aye mọ ni iṣẹ wọn ni Kano, awọn agbofinro ti ijọba da sita ni wọn n lọ kaakiri.

    Aworan bi igboro ṣe da ní ilu Kano nitori konile o gbele.

    Tẹ o ba gbagbe, ọjọ akọkọ ti iwọde ebi n pa wa bẹrẹ ni wahala bẹ silẹ ni Kano. Oku sun, wọn ba dukia jẹ, wọn si sọ iwọde naa di ọna lati jale pẹlu.

    Rogbodiyan naa lo mu Gomina Abba Yusuf kede ofin konile-o-gbele, titi ti alaafia yoo fi jọba.

  4. Fídíò bí àwọn agbófinró ṣe fe fi tajútajú tú àwọn olúwọ́de ká nílùú Abuja

    Àkọlé fídíò, Fidio iwọde nilu Abuja lọjọ Ẹti
  5. Ìwọ́de ti bẹ̀rẹ̀ fún ọjọ́ kejì nílùú Abúja

    Àwọn oluwọde tun ti korajọpọ si Berger nílùú Abuja furniture ètò iwode lonii to jẹ ọjọ́ keji osu kẹjọ yii.

    Iroyin sọ pe agbegbe Berger nilu Abuja ni wọn korijọ si ki awọn agbofinro atawọn ṣọja to wa ni ikalẹ fun amojuto eto abo to bẹrẹ si ni yin tajutaju si wọn.

    Awọn oluwọde niluu Abuja
    Àkọlé àwòrán, Awọn oluwọde niluu Abuja
    Awọn oluwọde niluu Abuja
    Àkọlé àwòrán, Awọn oluwọde niluu Abuja
    Awọn oluwọde niluu Abuja
    Àkọlé àwòrán, Awọn oluwọde niluu Abuja
    Awọn oluwọde niluu Abuja
    Àkọlé àwòrán, Awọn oluwọde niluu Abuja
    Awọn oluwọde niluu Abuja
    Àkọlé àwòrán, Awọn oluwọde niluu Abuja

    Ikọ ọlọpaa ati ọmọ ogun orilẹede Naijiria tun kọlu awọn oluwọde ni Berger niluu Abuja, ti wọn si bẹrẹ si n yin afẹfẹ gaasi tajutaju ati ibon lati fi tun wọn ka.

    Awọn oluwọde niluu Abuja
    Àkọlé àwòrán, Awọn oluwọde niluu Abuja
    Awọn oluwọde niluu Abuja
    Àkọlé àwòrán, Awọn oluwọde niluu Abuja
  6. Àwọn agbófinró ti ṣàwárí Sẹ́nétọ̀ tó ń ṣe agbódegbà fáwọn olùwọ́de - Nyesom Wike

    Awọn agbofinro n wo awọn oluwọde lọọkan

    Minisita fun olu ilu Naijiria, Nyesom Wike ti ṣalaye pe oju awọn agbofinro ti mọlẹ si ara Sẹnetọ kan fun jijẹ agbodegba fun iwọde to waye ni ilu Abuja tii ṣe olu ilu Naijiria.

    Lasiko to fi n ba awọn akọroyin ọrọ lẹyin ipade eto abo to waye ni Minisita Wike sọ eyi.

    Wike ni minisita ti wọn n tka si naa, vbi o tilẹ jẹ pe ko darukọ rẹ, lo n pin ounjẹ fun awọn oluwọde.

    O ni nigba to ba ya, awọn agbofinro yoo ran’sẹ pe sẹnetọ naa.

    Bakan naa lo tun ki awọn oluwọde nilọ pe ile ẹjọ ti gbe idajọ kalẹ pe wọn ko gbọdọ kọja papa iṣire MKO Abiọla fun iwde wọn, nitori naa ki wọn tẹle ofin naa lo dara.

  7. Báyìí ni ìwọ́de #Endbadgovernance ṣe wáyé ní Eko, Ibadan, Osogbo, Ilorin

  8. Àwọn olùwọ́de ti bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de nílùú Ibadan

    Àkọlé fídíò, Ìwọ́de ní ìlú Ibadan

    Agbegbe Iwo road lawọn Oluwọde naa ti gbera ki wọn to kọju si idi apẹ gba agbegbe Gate lọ.

    Àkọlé fídíò, Ìwọ́de nílùú Ibadan
    Àkọlé fídíò, Ìwọ́de nílùú Ibadan
  9. Ẹ gbo ewúro sójú kọ̀lọ̀rànsí tó bá fẹ́ fa wàhálà tàbí dáná sunlé lásìkò ìwọ́de - ọ̀gá ọlọ́pàá Nàìjíríà pàṣẹ fáwọn agbófinró

  10. Wo bí o ṣe lè dáàbò bo ara rẹ lásìkò ìwọ́de tó ń bọ̀ kí o má baà fara káásá

    ibi iwọde kan

    Oríṣun àwòrán, X/@_EL_AMEEN/via REUTERS

    Yoruba bọ, wọn ni o n bọ, o n bọ, awọn la a dẹ ẹ de e; eyi gan an ni BBC Yoruba fi fẹ ki o mọ bi o ti le daabo bo ara rẹ lasiko ifẹhonuhan ‘ebi n pa wa’ ti yoo bẹrẹ kaakiri orilẹede Naijiria ni Ọjọbọ ti i ṣe ọjọ kinni oṣu Kẹjọ ọdun yii.

    Bi ọjọ ṣe n sun mọ ọjọ kinni oṣu kẹjọ ti ifẹhonuhan yoo waye ni Aarẹ Bola Tinubu ti n ṣe oniruuru ipade pẹlu awọn gomina, ọba alaye, awọn olori ẹsin at'awọn mii tọrọ kan.