You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Àwọn jàǹdùkú ya bo àgọ́ ọlọ́pàá l’Eko, iléṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn ọlọ́kadà ló wà nídí ẹ̀

  2. Alaafin Oyo, Alake Egba, Timi Ede, àtàwọn Oba Yorùbá kan rèé tí wọ́n rọ̀ lóyè, tí Oba míràn sì jẹ lójú ayé wọn

  3. Ṣé lóòtọ́ọ́ ni olubi ọmọ níí ṣe pẹ̀lú àyànmọ́ ọmọ láyé?

  4. Ọjọ́ wo gan ní àyájọ́ obìnrin lágbàyéé Mothers Day, kí ló dé tí wọn fí n ṣé ajọyọ rẹ̀ lọ̀pọ̀ ìgbà?

  5. Àwọn agbébọn tún jí akẹ́kọ̀ọ́ fásitì mẹ́sàn án gbé ní Kogi

  6. Ọmọọba Harry, Meghan gúnlẹ̀ sí Nàìjíríà

  7. Ìjà Awolowo, Akintola àti ogun 'Wẹtiẹ', ẹ̀kọ́ wo ló kọ́ wa?

  8. Aminat, akẹ́kọ̀ọ́ táwọn ọlọ́pàá yin tajútajú fọ́ lójú ṣàlàyé bí ọlọ́pàá ṣe jáa jù sílẹ̀ nílé ìwòsàn

  9. Wo ewu tó wà fún ìyálamọ tó ń jẹ olúbi ọmọ lẹ́yìn ọjọ́ ìkúnlẹ̀

  10. A ṣe àṣìṣe, kìí ṣe DJ Switch ni a mú - Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá

  11. Wo ìtàn ayé gbajúmọ̀ adigunjalè méje nílẹ̀ Yorùbá tí ìjọba dá sẹ̀ríà fún

  12. Ìtàn Àrọ̀gìdìgbà jẹ́ kí ń rò pé bàbá mi yan Yemọ̀ja ní àlè - Ọmọ Fagunwa

  13. Wo ìdí tí wọ́n fi n pé ayájọ́ ọjọ́ 'Good Friday' ní orúkọ náà

  14. Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

    Afara Francis Scott Key niluu Baltimore, Maryland, lorilẹede Amẹrika ti dawo lẹyin ti ọkọ oju omi nla kan to ko ọpọlọpọ kọntena, kọluu.

    Ileeṣẹ to n ri si ijamba ina sapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi ajalu nla, ti wọn ko si ti le sọ iye eeyan to ba isẹlẹ naa lọ tabi dukia to bajẹ.

    Isẹlẹ naa waye ni bi aago kan abọ ni oru ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta.

    Ohun to sokunfa isẹlẹ naa ni BBC ko ti le fidi rẹ mulẹ sugbọn iwadii ti bẹrẹ.

    Gomina ipinlẹ Maryland, Wes Moore ti kede ilu o fararọ, to si ni gbogbo ọna ni ijọba n tọ lati doola ẹmi awọn eeyan to ṣe e ṣe ko kagbako ninu iṣẹlẹ naa.

    O dupẹ lọwọ ti ọkunrin ati obinrin to sisẹ takuntakun lati doola ẹmi awọn eeyan

    Kevin Cartwright, agbẹnusọ ẹka to n risi isẹlẹ ina, salaye pe eeyan meje ati ọpọlọpọ ọkọ ayọkẹlẹ to n gba afara naa ni fọnran ka bi wọn n ṣe jabọ sinu odo Patapsco.

    O ni o to ogun osisẹ to wa ninu omi bayii to n gbiyanju lati doola awọn eeyan.

    Ẹka to n risi iṣẹlẹ ina ti bẹrẹ si ni gbe igbesẹ lati doola awọn eeyan to ha si omi naa.

    Olori kan ni Baltimore, Johnny Olszewski Jr ti rọ awọn eeyan lati ma fi adura sọwọ si awọn to lugbadi isẹlẹ naa.

    Ileeṣẹ to ni ọkọ oju omi nla, Synergy Marine Group ti fidi rẹ mulẹ pe ko si nnkan to mu awọn osisẹ to wa ninu ọkọ oju omi naa.

  15. Wo oríṣìí àrùn márùn ún tí ìgbéyàwó láàrin ìbátan si ìbátan máa ń fà

  16. Tinubu pàṣẹ ṣíṣí ẹnubodè Nàìjíríà sí Niger àtàwọn àyípadà míì

    Ààrẹ Bola Tinubu ti gbé àwọn òfin àti ìlànà tuntun kalẹ̀ lórí àwọn òfin tí wọ́n fi de orílẹ̀ èdè Niger.

    Nínú àtẹ̀jáde kan tí agbẹnusọ ààrẹ, Ajuri Ngelale fi léde sórí ẹ̀rọ X lọ́jọ́rú ní Tinubu ti pàṣẹ pé kí wọ́n gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tí wọ́n fi de ibodè Niger àtàwọn òfin míì tí wọ́n fi dè wọ́n.

    Ìdarí yìí ni wọ́n ní kí ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní kíákíá àti pé ó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹnukò àwọn olórí orílẹ̀ èdè àjọ ECOWAS níbi ìpàdé wọn tó wáyé lọ́jọ́ Kẹrìnlélógún oṣù Kejì ọdún 2024.

    Àwọn adarí ECOWAS fẹnukò láti gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí àwọn òfin tí wọ́n fi de Niger, Mali, Burkina Faso àti Guinea.

    Ṣaájú ni ìjọba ti fòfin de orílẹ̀ èdè Niger látàrí bí àwọn ológun ṣe fipá gba ìjọba ní orílẹ̀ èdè náà ní ọdún tó kọjá.

    Tinubu ti wá pàṣẹ pé gbogbo àwọn òfin tí wọ́n fi dé wọ̀n tó fi mọ̀ títi àwọn ẹnubodè Nàìjíríà sí Niger ni kó jẹ́ ṣíṣí padà.

    Bákan náà ni wọ́n ní kí káràkátà láàárín orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti Niger le bẹ̀rẹ̀ padà, àti pé iná mọ̀nàmọ́ná tí Nàìjíríà ń fún Niger tí wọ́n dá dúró tẹ́lẹ̀ ni wọ́n yóò dá padà fún wọn.

    Gbogbo akoto owó Niger tó wà ní àkàtà ECOWAS tí wọ́n ti gbẹ́sẹ̀ lé ni kó di ṣíṣí padà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

    Àwọn ẹbí àwọn adarí orílẹ̀ èdè Niger tí wọn kò ní àǹfàní láti rin ìrìnàjò látàrí òfin tí wọ́n fi dè wọ́n ni wọ́n ti lè rìnrìnàjò lọ sí ibi tí wọ́n bá fẹ́ báyìí.

    Ààrẹ Tinubu tún gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tí wọ́n fi de orílẹ̀ èdè Guinea lórí ìsùná àti ètò ọrọ̀ ajé wọn.

  17. Nǹkan márùn ún tó yẹ kí aláàwẹ̀ ṣe àti èyí tó yẹ kó yàgò fún

  18. Tinubu pàṣẹ fún iléeṣẹ́ 'Customs' láti dá oúnjẹ tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ọlọ́jà padà

    Ààrẹ orílẹ̀ Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu ti darí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ibodè ìyẹn Nigeria Customs Service láti dá gbogbo àwọn oúnjẹ tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ènìyàn padà fún wọn.

    Ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ Customs, Bashir Adewale Adeniyi ló ṣísọ lójú eégún ọ̀rọ̀ náà nínú àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi sórí ẹ̀rọ ayélujára X.

    Lásìkò tí Adeniyi ń sọ́rọ́ níbi ètò kan ní ẹnubodè Kwangwalam ní ìjọba ìbílẹ̀ Maiadua, ìpínlẹ̀ Katsina nígbà tó ń bá àwọn alẹ́nulọ́rọ̀ sọ̀rọ̀.

    Adeniyi ní Tinubu ti pa á láṣẹ fún àwọn láti ri dájú pé gbogbo àwọn ọlọ́jà tí wọ́n ní ọjà lọ́dọ̀ àwọn pàápàá oúnjẹ ni àwọn dá àwọn ọjà náà padà fún wọn.

    Ó ní àṣẹ yìí fi hàn pé ààrẹ ní ìfarajìn sí rírí dájú pé àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè yìí kò ráhùn oúnjẹ àti pé owó tí àwọn èèyàn fi ń ra oúnjẹ lọ́jà wálẹ̀ jọjọ.

    Ó fi kun pé gbogbo àwọn tí àwọn bá dá oúnjẹ padà náà fún ni wọn yóò ṣèlérí láti tà á sí ọjà Nàìjírià láì ní kó wọn lọ sí ilẹ̀ òkèrè tàbí orílẹ̀ èdè mìíràn.

    Ó tẹ̀síwájú pé àjọṣepọ̀ tó lóòrìn gbọdọ̀ wà láàárín àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò àtàwọn olókoòwò láti mú ìdàgbàsókè bá àwùjọ nítorí tí kò bá sì ààbò tó péye ní ìlú, ètò ọrọ̀ ajé kò lè rú gọ́gọ́.

  19. Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣèlérí ààbò tó péye fáwọn tó fẹ́ kópa nínú ìfẹ̀hónúhàn ṣùgbọ́n...

    Ṣaaju iwọde ifẹhonuhan to fẹwaye lorileede Naijiria bẹrẹ lọjọ Iṣẹgun, ileeṣẹ ọlọpaa ti jẹjẹ aabo to peye fawọn olufẹhonuhan.

    Amọ wọn sọ pe awọn ko ni jawọ lati ri wi pe wọn ko faaye gba ki wahala ati ikọlu kankan waye nibẹ.

    Alukoro agba ileeṣẹ ọlọpaa lo fidi ọrọ yi mulẹ ninu atẹjade kan tui wọn fi sita bo ṣe ku ọjọ kan ti iwọde ifẹhonuhan yi yoo waye.

    Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ lorileede Naijiria NLC lo pe fun iwọde yi jakejado orileede Naijiria lati le jẹ ki ijọba mọ pe inu araalu ko dun sibi ilu ko ṣe fararọ.

    Olumuyiwa Adejobi to buwọlu atẹjade ọlọpaa yi sọ pe ''ileeṣẹ ọlọpaa mọ riri ẹtọ awọn araalu lati ṣe iwọde alaafia ni ibamu pẹlu ofin orileede Naijiria.''

    Amọ atẹjade naa tẹsiwaju pe ''tohun ti baa ṣe faaye silẹ lati lo ẹtọ yi, ileeṣẹ ọlọpaa ko ni kawọ gbera ki awọn alaburu fi iwọde naa da wahala silẹ''

    Tori naa o ni awọn ko ni bikita lati kọdi awọn to ba fẹ tasẹ agẹrẹ si ofin pẹlu iwde ifẹhonuhan yii.

  20. N kò fẹ́ káwọn ọmọ mi jẹ́ àjèjì ní Nàíjíríà ní mó ṣe ń kọ́ wọn ní Yoruba - Bàbá ìbejì tó fẹ́ òyìnbó