You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika
Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye
Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́
Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan
Dúkìá ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ̀nù ṣòfò níbi ìṣẹ̀lẹ̀ iná tó jó lọ́jà Alaba Rago l'Eko
‘Ọmọ kan ṣoṣo tí Ọlọ́run yọ̀ǹda fún mi làwọn ọlọ́pàá lù pa’
Kò sí ohun tí mo fẹ́ ju kí wọ́n ju àwọn ọlọ́pàá tó pa ọmọ mi sí ẹ̀wọ̀n igbere lọ - Ìyá Sulyman Ayeyemi pariwo
Ọlọ́pàá lu òṣìṣẹ́ NSCDC lálùbami ní Osun, ìwádìí bẹ̀rẹ̀
'Ọlọ́pàá rere ni ọkọ mi àmọ́ wọ́n pa á lásìkò ìwọ́de #EndSARS'
Ǹjẹ́ o mọ̀ pé obìnrin lè bí Ìbejì tí wọn yóò sì ní bàbá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀?
Òkú obìnrin tí mò ń lọ wẹ̀ yọ sí mi, ohun tó sọ rèé - Agbókùújó
Ìwọ́de bẹ̀rẹ̀ l'Eko àti Osun, àwọn agbófinró fi gáàsì tajútajú tú olùwọ́de ká l'Abuja
Wo ohun tó yẹ ko mọ̀ nípa àrùn pọ̀jẹ̀-pọ̀jẹ̀ Marburg tó ṣekúpa èèyàn mẹ́fà ní Rwanda
Mọ̀ sí i nípa oríṣi ààrùn Corona tuntun, XEC, tó ń tàn kálẹ̀ báyìí
Olùwọ́de #EndSARS mẹ́fà gba ìtúsílẹ̀ lẹ́yìn ọdún mẹ́rin ní àtìmọ́lé
Buhari, Jonathan, Gowon, Abubakar péjú síbi ìpàdé ìgbìmọ̀ Májẹ̀óbàjẹ́, ṣe káre sí Tinubu pé kò gbà fáwọn olùwọ́de láti dojú ìjọba rẹ̀ bolẹ̀
Òní ni àṣekágba ìwọ́de ‘ebi ń pa wá’ #EndBadGovernance, àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ láàrin ọjọ́ mẹ́wàá rèé
Àwọn mọ̀lẹ́bí ọkùnri tí ọlọ́pàá ṣekúpa lásìkò ìwọ́de ìlú le bèrè ìdájọ́ òdodo
Èmi ni mo pe ọmọ mi kó jáde wá fẹ̀hónúhàn tí ó fi ṣàgbákò ikú òjijì - Ìyá ọmọkùnrin tó kú
''Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti máwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó ń ṣàtìlẹyìn fáwọn tó ń na àsìá Russia sókè níbí ìwọ́de''
Àwọn adarí olùwọ́de ní Bauchi, Katsina Kano, Kaduna àti Katsina wulẹ̀ fi ìwọ́de bojú láti hùwà ọ̀daràn ni
Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ni awọn to ṣe akojọpọ iwọde Ebi n panu #EndBadGovernance ni ipinlẹ Bauchi Kano, Kaduna ati Katsina lo anfani iwọde naa lati fi lo awọn ọmọde kan hu iwa ọdaran ni.
Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ ọlọpaa fi sita, eyi ti alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejọbi fi sita ṣalaye pe iwadii ti n waye lati fi oju gbogbo awọn to wa nidi iwa ọdaran naa sita.
Atẹjade naa ni o le lẹdẹẹgbẹrun awọn eeyan ti ọwọ ofin ti ba bayii gẹgẹ bi afurasi lori iwa ọdaran lilo aṣia ilẹ okeere lorilẹede Naijiria.
Àwọn olùwọ́de jí ìbọn àtàwọn ẹrù òfin míràn kó lásìkò tí wọ́n fọ́ ilé ẹjọ́ ní Kano
Alukoro fun ileeṣẹ eto idajọ ni ipinlẹ Kano, Baba Jibo Ibrahim ni wọn ti gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣe akọsilẹ awọn ẹru ofin ti awọn oluwọde ji ko lọ lasiko ti wọn fi fọ awọn ile ẹjọgiga ipinlẹ naa.
Alukoro ileeṣẹ eto idajọ ni ipinlẹ Kano ni ibọn atawọn ohun ija oloro loriṣiriṣi lo wa ninu ohun ti awọn oluwọde naa ji ko lọ.
Ninu ọrọ to ba ileeṣẹ iroyin Daily Trust sọ lọjọ Aje, ni titi di asiko ti ifọrọwerọ naa fi waye,wọn ṣi n ṣe akọsilẹ awọn ohun ti wọn ji ko lọ ni ile ẹjọ naa.
Àwọn olùwọ́de jí ìbọn àtàwọn ẹrù òfin míràn kó lásìkò tí wọ́n fọ́ ilé ẹjọ́ ní Kano.
Ọwọ́ DSS tẹ àwọn télọ̀ tó ń rán àṣíá Russia fún àwọn olùwọ́de ní Kano
Ọwọ awọn oṣiṣẹ agbofinro DSS lorilẹede Naijiria ti tẹ awọn aranṣọ to n ran aṣia orilẹede Russia fun awọn oluwọde niilu Kano.
Ileeṣẹ agbofinro DSS ni ọwọ tẹ awọn telọ naa ti wọn n ran awọn aṣia ti wọn n pin kaakiri ipinlẹ naa.
Bakan naa ni ileeṣẹ agbofinro DSS tun fi kun un pe ọwọ awọn ti tẹ awọn to gbe iṣẹ naa fun wọn., bẹẹ ni iwadi awọn ṣi n tẹsiwaju lori rẹ.
Ọmilẹgbẹ awọn oluwọde lapa ariwa orilẹede Naijiria ni wọn n mu aṣia orilẹede Russia kiri lasiko iwọde to n waye nibẹ.