You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika
Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye
Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́
Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan
Agbébọn pa ọmọ ìyá méjì ní West Bank torí ìjà láàrin Israel àti Palestine
Awọn ọmọ baba meji ti wọn jẹ ọmọ ilẹ Israel ati Amẹrika ti ku lagbegbe West Bank ninu ija laarin orilẹede Israel ati Palestine.
Orukọ awọn mejeeji ni Maia ati Rina Dee
Ọsan ọjọ Ẹti ni awọn ọmọ iya kanaa yii ku lẹba ikorita Hamra to wa ni ẹkun Jordan Valley lasiko ti wọn n wa ọkọ wọn lọ si Tiberias
Awọn obinrin mejeeji naa lo jẹ ọmọ Rabbi Leo Dee, to wa lati ilu London, to si sapejuwe iku awọn ọmọ rẹ naa bii ‘ala to ba ni lẹru’.
Amọ iya awọn ọmọbinrin naa wa ninu ipo ti ko dara nile iwosan nigba to gbọ isẹlẹ iku awọn ọmọ rẹ naa.
Ẹni ogun ọdun ni Maia, to si wa sinru ilu nile ẹkọ girama kan nilẹ Israel, ti aburo rẹ, Rina si jẹ ẹni ọdun mẹẹdogun.
Awọn agbebọn kan lo da ibọn bo wọn bi wọn se n wa mọto wọn bọ, ti baba wọn si ti wa mọto tiẹ kọja lọ saaju wọn.
Amọ ori afẹfẹ ni baba wọn ti gbọ nipa isẹlẹ iku awọn ọmọ rẹ ko to mọ pe mọlẹbi oun ni ijamba kan.
Nigba to n ba BBC sọrọ, Rabbi Leo Dee sapejuwe awọn ọmọbinrin rẹ mejeeji bii awọn to rẹwa, ti wọn si dara lọmọ.
O ni oun ko tii le sun lati igba tawọn mejeeji ti ku.
"Ni gbogbo igba, alakala lo maa n ji mi. Amọ ohun to sẹlẹ yii gan buru ju alakala lọ.
Nitori naa lo se maa n wu mi lati pada lọ sun, bo se ri gan ree.”
Ọjọ Aiku ni wọn yoo sin awọn ọmọbinrin mejeeji naa ni ile wọn to wa ni agbegbe West Bank.
Olootu Ijoba ilẹ Isreal, Benjamin Netanyawu, wa se apejuwe iku awọn ọmọ mejeeji naa bi ikọlu awọn agbesunmọmi.
O si fi isẹ ibanikẹdun ransẹ sawọn mọlẹbi to n se ọfọ ọmọ wọn naa.
Ọkùnrin kan dáná sun ilé ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí nítorí pé ó kọ̀ láti fẹ padà
Ọwọ́ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti tẹ arákùnrin kan, Hassan Yusuf fẹ́sùn wí pé ó dáná sun ilé ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí kan, Busayo Falola.
Afurasí náà ni ìròyìn ní o dáná sun ilé tí Busayo Falola ń yá gbé tó wà ní ojúlé 127, Old Scholar Palace, Igan Road, Ago Iwoye ní ìjọba ìbílẹ̀ Ijebu-North fẹ́sùn pé ó kọ̀ láti fẹ́ òun padà.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ogun, Abimbola Oyeyemi nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde ni ìyá onílé náà, Adejoke Salau ló lọ fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá Ago Iwoye ló jẹ́ kí àwọn nawọ́ gán Hassan Yusuf.
Oyeyemi ṣàlàyé pé ṣàdédé ni òun gbọ́ tí ariwo sọ ní ilé òun ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun tó kọjá tí àwọn sì ri pe ilé ló ń jó lásìkò tí àwọn ènìyàn sì wà nínú ilé.
Ó ní ìyá náà sọ wí pé ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ènìyàn ni kò jẹ́ kí àwọn ayálégbé mẹ́ta kan jóná mọ́lé àmọ́ gbogbo ilé òun ló jóná pátápátá.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà fi kun pé lẹ́yìn tí ìyá onílé náà lọ fẹjọ́ sùn ni ọ̀gá ọlọ́pàá Ago Iwoye, Noah Adekanye ní kí àwọn ọlọ́pàá kó àwọn ayálégbé ibẹ̀ láti ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún wọn láti mọ nǹkan tó ṣokùnfà iná ọ̀hún.
"Lásìkò ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò ni ọ̀kan nínú àwọn ayálégbé náà ní òun rí ọ̀rẹ́kùnrin òun tẹ́lẹ̀ rí ní ojú fèrèsé òun ní nǹkan bíi aago méjìlá àbọ̀ òru èyí tó dá ẹ̀rù bá òun púpọ̀."
"Ó ní èyí ló mú òun sá lọ sí yàrá àwọn ará ilé mìíràn tí wọ́n sì jáde láti mọ òun tí Yusuf ń wá lásìkò náà ní ilé àwọn àmọ́ kò pẹ́ ni àwọn ri tí iná sọ láti yàrá Busayo."
Oyeyemi ní èyí ló jẹ́ kí àwọn wá Yusuf kàn láti wá wí tẹnu rẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó sì jẹ́wọ́ pé òun dáná sun yàrá Busayo nítorí ó kọ̀ láti gbà láti máa fẹ́ òun padà.
Ó ní kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Ogun, Frank MBA ti pàṣẹ pé kí àwọn gbé ẹjọ́ náà lọ sí ẹ̀ka tó ń rí sí ìwà ọ̀daràn fún ìwádìí tó péye.
Ìjàm̀bá iná jó ṣọ́ọ̀bù márùn-ún, ilé méjì run ní Ilorin
Ìjàm̀bá iná ṣọṣẹ́ ní Balogun Afin ní agbègbè Ita-Kure, ìlú Ilorin, ìpínlẹ̀ Kwara bí ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń ta ọ̀dà ìkunlé ṣe gbiná ní òru ọjọ́ Ẹtì mọ́júmọ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta.
Àtẹ̀jáde tí Agbẹnusọ Iléeṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Kwara, Hassan Adekunle fi léde ní nǹkan bí i aago méjìlá àbọ̀ òru ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀.
Adekunle ní ilé alájà kan àti ilé nílẹ̀ kan ni ìjàm̀bá iná náà ṣe àkóbá fún àti pé ó tún ran ṣọ́ọ̀bù márùn-ún mìíràn.
Ó ní ṣọ́ọ̀bù ọ̀dà ni iná náà ti bẹ̀rẹ̀ kó tó di wí pé ó ràn mọ́ àwọn ilé méjì tó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.
Ó fi kun pé iye dúkìá tí iná náà ṣàkóbá fún tó mílíọ̀nù méjìdínlógójì náírà.
Bákan náà ló rọ àwọn ènìyàn láti máa ri dájú pé wọ́n ń ṣàmójútó ilé wọn dada kí wọ́n sì ri pe wọ́n ń pa iná tó bá yẹ kí wọ́n tó sùn.
Ènìyàn kán kú, méjé farapa nínú ìkọlù agbéṣùnmọ̀mí ní Israel
Eniyan kan ti ku, ti awọn meje miran si farapa ninu iṣẹlẹ ikọlu igbesunmọmi to waye ni agbegbe eti omi igbafẹ ni ilu Tel Aviv, ni ilẹ Israel.
Ileeṣẹ pajawiri ni Israel ni arinrinajo lati ilẹ Italy wa si Israel lo ku ninu iṣẹlẹ naa, ti wọn si pe orukọ rẹ ni Alessandro Parini, ẹni ọdun mẹrindinlogoji.
Dokita to ṣaajo pajawiri ninu iṣẹlẹ naa ni mẹta ninu awọn to farapa naa jẹ arinrinajo lati Ilẹ Gẹẹsi.
Awọn aworan iṣẹlẹ naa ṣafihan ọkọ to ti dojubọlẹ, ti ọlọpaa ilẹ isrẹli si ṣina bolẹ.
Bakan naa ni awọn ọlọpaa nibẹ ni wọn ti yinbọn pa ẹni to ṣekọlu naa ti wọn si pe orukọ rẹ ni Yousef Abu Jaber lati agbegbe Kafr Qasim to jẹ Arabu-Isreli.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni aago mẹsan kọja ni akoko ti ilẹ Isrẹli ni ọkunrin kan wa ọkọ Kia kọja ni bebe odo ti awọn eniyan ti n gbafẹ to si bẹrẹ si ni kọju wọn, ki ọkọ rẹ to doju bọlẹ.
Wọn ni bi o ṣe jade ninu ọkọ naa to dabi ẹni pe o fẹ mu ibọn ni ọlọpaa kan yinbọn pa.
Nibayii, Olootu Ijọba Ilẹ Italy, Giorgia Meloni ti fi aidunnu rẹ han si iṣẹlẹ naa to si ba wọn kẹdun.
Agbẹjọro ni arakunrin ilẹ Italy, Parini to ku ninu iṣẹlẹ naa.
Ṣaaju ni wọn ti ṣekọlu si awọn ọmọ ilẹ Ilẹ Gẹẹsi to tun jẹ ara ilẹ Isrẹli meji pẹlu iya wọn ni agbegbe West Bank.
Àwọn agbébọn kọlu abúlé Umogidi, pa èèyàn 51
Ikọlu naa jẹ eyi to ya gan. Ilu to jẹ wipe o maa n dakẹrọrọ ni Umogidi amọ ariwo sọ, o di ikọlukọgba bi iro ibọn ṣe dun lọjọ ti iṣẹlẹ naa waye.
Awọn agbebọn lo kọlu ilu naa ti awọn to ṣoju wọn koro si ṣalaye pe ikọlu naa bẹrẹ lati aarin ọja ilu gẹgẹ bi awọn agbebọn naa ṣe n yinbọn lu ẹnikẹni ti wọn ba ri.
Lara awọn to sa wọ inu igbo lọ naa fara gba ọta ibọn.
Titi di ọjọ meji lẹyin ikọlu yii eyi tii ṣe ọjọ Ẹti ọsẹ, wọn ṣi n ri oku awọn eeyan lati lọ sin wọn. Olori ọdọ kan ni ilu naa, Adakole Inalegu Daniel sọ fun BBC lọjọ Ẹti pe awọn araalu ṣi n wa abẹ ilẹ lati mọ boya awọn mii wa ti wọn ku.
Bo tilẹ jẹ pe ijọba ipinlẹ Benue ti dari awọn ikọ ẹṣọ aabo si ilu naa latigba ti ikọlu ti maa n waye, awọn oniṣẹ laabi o dawọ ikọlu duro.
Lọsẹ to kọja ni awọn agbebọn ji Alufa ṣọọṣi kan ati ọmọ ijọ mii gbe lẹyin ti wọn yinbọn pa olujọsin kan ni apa ibomii ni ipinlẹ Benue.
Agbẹnusọ ọlọpaa Benu DSP Sewuese Anene sọ pe Kọmisana Ọlọpaa, Wale Abasse yoo ṣe ibẹwo sibi iṣẹlẹ naa amọ awọn ti ko ikọ ọlọpaa lọ sibẹ.
Owo: Ilé ìjọsìn àgùdà St Francis yóò di ṣíṣí lọ́jọ́ Àìkú fun ayájọ̀ Oͅjóͅ Àjínde
Lẹyin oṣu mẹwaa tí awọn agbebọn ṣe kọlu, ti wọn ṣekupa eeyan mọkanlelogoji ni ile ijọsin St Francis Catholic Church niluu Owo nipinlẹ Ondo, ile ijọsin naa yoo di sisi pada lọjọ Aiku, ọjọ ayẹyẹ ajinde Jesu.
Bisọọbu agba fun ìjọ aguda naa, Jude Arogundade lo kede ọrọ naa síta.
Arogundade ni lati igba ti ikọlu naa ti waye ni ile ijọsin naa ti wa ni títí pa fun awọn olujọsin.
"Lati Igba ikọlu naa ti waye, tí a padanu awọn ọmọ ile ijọsin wa sọwọ awọn agbebọn, tí wọn si ṣekupa wọn ní ile ìjọsìn naa ti wa ni títí pa lati da bobo awọn eeyan ati lati bu ọla fún àwọn to padanu ẹmi wọn.
"Ile ìjọsìn naa yoo di ṣíṣí pada fun ayẹyẹ ajinde Jesu. Ijọba ipinlẹ Ondo naa ti gbe igbimọ kalẹ lori iranti awọn eeyan wa to ba ikọlu naa lọ."
Páṣítọ́ Gambia kan lù àwọn olùjọsìn ní jìbìtì, palẹ̀mọ́ fóònù n'Ibadan
Pasitọ kan lati orilẹede Gambia, Owen Abraham ni wọn ti fẹsun kan pe o lu awọn olujọsin agbegbe Aponrin ni Agbowo ni jibiti owo ati awọn nnkan miiran paapa foonu toto mejileladọta niluu Ibadan.
Awọn olujọsin naa ni Pasitọ ni Ọlọrun ni pe ko wa ṣe ìsọji alagbara niluu Ibadan to jẹ olu ilu ipinlẹ Oyo.
Gẹgẹ bi awọn olujọsin se sọ, Pasitọ Abraham sọ lọjọ kẹyin ìsọji alagbara ọlọjọ mẹta pe Ọlọrun ni ki awọn olujọsin mu ẹrọ ibanisọrọ kalẹ sugbọn ohun iyalẹnu lo jẹ fun awọn olujọsin nigba ti wọn gbọ pe Pasitọ ti japa.
Ọkan lara awọn to lugbadi iṣẹlẹ naa, Iyaafin Grace Akintola ni ọpọlọpọ awọn opo lo wa síbi iṣọji náà nitori pe Pasitọ ṣe ileri lati fun wọn ni apo irẹsi ati owo, to si tun ni oun yoo se agbekalẹ eto ẹkọ ọfẹ fun awọn ọdọ.
Akintola tẹsiwaju pe Pasitọ naa tan wọn sinu awẹ ati adura ọlọjọ mẹta to si di awati lọjọ to gbẹyiniṣọji naa, ti gbogbo igbinyanju lati wa si ja si ofo.
"Pasitọ yii ba ọmọbinrin Igbo kan sọrọ ni adugbo mi lati ran lọwọ ko awọn opo ati akẹkọọ jọ, pe o fẹ ran wa lọwọ.
"Eeyan kan ni adugbo mi lo ni kí wa si iṣọji naa.
"Pasitọ ni oun yoo ra ile fun wa, koda o ni ile naa ti wa nilẹ.
"O ṣeleri pe oun yoo fun awọn eeyan to wa sibi iṣọji naa lọwọ, owo ti oloselu gan ko le fun eeyan.
"Lọjọ to gbẹyin iṣọji, o ta omi fun eeyan ni ẹgbẹrun marun-un dín diẹ, o ni turari wa ninu omi naa, ti ọpọlọpọ si ra omi ọhun."
Àwọn agbébọn ṣíná ìbọn bolẹ̀ nínú ọjà Benue, èèyàn 51 dèrò ọ̀run
O kere tan, eeyan mọkanlelaadọta lawọn agbebọn ti pa ni ipakupa, nigba ti ọpọ awọn mii di awati nipinlẹ Benue.
Iroyin ni awọn ara ilu Umogidi, nibi ti iṣẹlẹe naa ti waye ti kan lu igbẹ bayii lati ṣawari oku awọn eeyan to ku.
Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn ṣalaye pe inu ọja lawọn agbebọn ọhun ti kọkọ ṣina ibọn bolẹ lọjọru, ti wọn si n dana ibọn ya ẹnbikẹni ti wọn ba foju ganni.
Awọn mii lara awọn to salọ sinu igbo ni ibọn ba nibi tiwọ ti n salọ.
Lẹyin ọjọ meji tiiṣẹlẹ naa waye, wọn ṣi n ṣawari oku awọn eeyan ninu igbo.
Ọkan lara awọn adari ilu naa, Adakole Inalegu Daniel sọ fun BBC pe awọn ti n sin oku awọn to ba iṣẹlẹ ọhun lọ.
Nǹkan ò fararọ láàrin Isreal àti Palestine, níṣe ni àdó olóró ń fò lọ́tùn ún lósì
Awọn ọmọ ologun orilẹede Isreal ti fi ado oloro ransẹ si Lebanon ati Gaza strip lati ṣekọlu si awọn alakatakiti ẹsin Hamas ni Palestine.
Ile iṣẹ ologun ni ikọlu naa lo waye lati gba ẹsan adọ oloro mẹrinlelọgbọn ti wọn yin lati Lebanon si ariwa Isreal lọjọbọ latọwọ ẹgbẹ alakakiti Hamas.
Ṣaaju ni nkan o ti fararọ nitori ikọlu ti ile iṣẹ ọlọpaa ṣe si mosalasi al-Aqsa to wa ni Jerusalem laarin ọsẹ yii.
Ikọlu ti ile iṣẹ ọlọpaa Isreal ṣe si moṣalaṣi al-Aqsa lo fa ija pẹlu awọn ara Palestine ninu Moṣalaṣi, eyi to se pataki si awọn Musulumi lagbaye.
Botilẹ jẹ wi pe ikọ Hamas ko kede bọya awọn lo wa lẹyin jiju ado oloro naa ṣugbọn, adari ẹgbẹ ohun Ismail Haniyeh to se abẹwo si Beiruit ni awọn ko ni kapa rọ si bi Isreal se n fiya jẹ awọn.
Oru moju idun gbamu ado oloro mẹta si meji lo waye lagbegbe Rashidieh, nibi ti awọn to sa fogun lati Palestine wa,o jẹ kilometer marun si Tyre, lorilẹede Lebanon.
Ile isẹ ologun Isreal (IDF) ninu atẹjade to ṣe lori ikanni ayelujara Twitter rẹ ni,awọn ọkọ ofurufu ologun Isreal lo kọlu awọn nkan to ni se pẹlu ẹgbẹ Hamas ni Lebanon.
Ile iṣẹ akọroyin Isreal ni ikọlu to le ni mẹrinlẹlogoji ni wọn ṣe lati Gaza si gusuu Isreal.
Pupọ ninu ado oloro ti wọn yin si Isreal ni ẹrọ idabobo Isreal bajẹ lori ofurufu,ti awọn miran si jabọ si itagbangba,ile kan pere ni Sderot ni ado oloro ohun kọlu.
Wo ọ̀rọ̀ Iya Rainbow, Saheed Osupa, àwọn Alfa, àwọn òṣèré sí Pasuma bó ṣe ń sọkún ikú ìyà rẹ̀
Àwọn ajínigbé ṣèkọlù sí ilé igbákejì gómìnà, wọ́n jí i gbé lọ
Awọn agbebon kan ti gbe eniti o ti figba kan ri jẹ igba keji gomina ipinlẹ Nasarawa,Ọjọgbọn Onje Gye-Wado ni ile rẹ to wa ni agbegbe Gwagi, to wa ni ijọba ibilẹ Wamba lafẹmoju oni.
Molebi Onje to ba awọn akọroyin sọrọ wi pe, awọn ajinigbe ohun lo fo igana ile naa wọle ti wọn si gba oju feresẹ yara iyawo rẹ wole, ki wọn to gbe e lọ.
Ọjọgbọn Onje Gye-Wado lo jẹ igbakeji gomina ipinlẹ Nasarawa laarin ọdun 1999 si ọdun 2003, ti wọn si ti gbiyanju lati ji i gbe lọpọ igba tẹlẹ ri.
Nigba ti oun fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu atẹjade ti alukoro ọlọpaa ipinlẹ Nasarawa DSP Rahman Nansel filede, Rahman ni awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ ọlọpaa ti n ṣiṣẹ lati rii wi pe wọn doola ọjọgbọn Onje lai farapa.
Rahman ni "iroyin ti ile iṣẹ ọlọpaa gba lo fihan wi pe lọjọ keje oṣu kẹrin ni bi ago mejila abọ oru, awọn agbebon yawọ abule Gwagi to wa ni ijọba ibilẹ Wamba, ti wọn si wọ ile ọjọgbọn Onje Gye-Wado, wọn ji i gbe lọ si ibiti a o le sọ bayii’.
O fi kun un pe bi awọn ti gbọ iroyin yii, awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ ọlọpaa agbegbe Wamba lọ sibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ, ṣugbọn awọn agbebon ọhun ti lọ pẹlu ẹniti wọn jigbe.
Atẹjade naa tẹsiwaju wi pe "kọmisona ọlọpaa fun ipinlẹ Nasarawa, Maiyaki Baba ti fi awọn ọlọpaa to mọ nipa iwa ijinigbe, awọn ologun, fijilante ati awọn ọlọdẹ agbegbe naa lati kun awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ ọlọpaa lọwọ ki wọn le doola ẹmi ẹni ti wọn gbe lalafia.”
Agbẹnusọ ile iṣẹ ọlọpaa rọ awọn ara ilu to ba ni ẹri to daju lati ran ile iṣẹ ọlọpaa lọwọ ki wọn lẹ tete doola ẹni ti awọn ajinigbe ji gbe.
Wọ́n fi sísọ́ọ̀sì gún akẹ́kọ̀ọ́ fásitì Ondo lọ́rùn pa torí N1000
APC sọ̀rọ̀ lórí ìdí tí Tinubu fi jọ̀wọ́ $460,000 fún ìjọba Amẹ́ríkà lórí ẹ̀sùn egbògi olóró
Mo ti pé ọdún tí àwọn Dókítà ní màá kú àmọ́ mo ṣì gbàgbọ́ nínú iṣẹ́ ìyanu – Fikayomi Aaron
Olósèlú tí wóͅn fi èͅsùn kàn pé o jí páànù òrulé tó lé ní 14,000 yóò wà ní àtìmóͅlé títí di Oͅjóͅ Àjínde
Asͅofin lorileͅede Uganda, Arabinrin Mary Goretti Kitutu yoo wani atimoͅle oͅloͅpaa titi di eͅyin Ajinde, leͅyin ti woͅn fi eͅsun ole kan an.
Ileesͅeͅ oͅloͅpaa lorileͅede naa ni arabinrin naa ji paanu orule to le ni aͅgbeͅgbeͅrun to toͅ si awoͅn ilu kereje, to si lu ni ponpo.
Bakan naa ni woͅn ni awoͅn oloselu meͅwa miran loͅwoͅ ninu isͅeͅleͅ iwa jibiti naa.
Lara awoͅn ti woͅn fi eͅsun kan oͅhun ni igbakeji aareͅ orileͅede Uganda, Olootu Ijoͅba to fi moͅ abeͅnugan ile igbimoͅ asͅofin.
Oͅga agba oͅloͅpaa lorileͅede naa lo kede reͅ lasiko ti woͅn ni awoͅn n sewadii bii paanu to le ni 14,500 se di awati.
Ninu oͅroͅ tireͅ, Olotu Ijoͅba ti woͅn fi eͅsun kan lara woͅn pe, o gba ninu paanu naa, ti toͅroͅ aforiji to si ti da tireͅ pada. Bakan naa ni abeͅnugan ile igbimo asofin naa ti da tireͅ pada.
Iroyin tileͅ ni minisita kan to ti fi paanu naa koͅ ile ti awoͅn eͅran reͅ n gbe ti loͅ da pada.
Amoͅ arabinrin ti woͅn fi eͅsun kan, Mary Kitutu ni iroͅ ni woͅn pa moͅ oun, ati pe oun ko jeͅbi eͅsun ti woͅn fi kan oun.
Agbegbe Karamoja to nilo orule tuntun naa ni ojo aroͅroͅda ti n sͅoͅsͅeͅ nibeͅ, ti awoͅn ara ilu naa si nilo iranwoͅ loͅpoͅ igba.
‘’INEC ti kéde ààreͅ tuntun tí wóͅn dìbò yàn, kò sí ohun tó ń jeͅ ìjoͅba fìdíeͅ ‘’- Iléeséͅ oͅmoͅogun Naijiria kìlòͅ
Ileesͅeͅ oͅmoͅogun Naijiria, DHQ ti kede pe oͅroͅ lori asan ni awoͅn to n pe fun ijoͅba fidieͅ.
Adari eͅka eto iroyin fun ileesͅeͅ oͅmoͅogun, Oͅgagun Musa Dammadami lo soͅ beͅeͅ ni ilu Abuja nibi ijiroro oͅloͅsoͅoͅseͅ peͅlu awoͅn oniroyin.
Dammadani bu eͅnu ateͅ lu awoͅn to n pe fun ijoͅba fidieͅ lorileͅede Naijiria.
O ni leͅyin ti INEC ti kede eͅni to jawe olubori ninu idibo sipo, ipe fun ijoͅba fidieͅ ru ofin ni Naijiria.
Laipeͅ yii ni awoͅn to n fi apa janu ninu esi idibo to gbe Bola Ahmed Tinubu woͅle geͅgeͅ bi aareͅ ti woͅn dibo yan, n loͅgun fun ijoͅba fidieͅ.
Amoͅ ajoͅ oͅteͅleͅmuyeͅ DSS lo koͅkoͅ ke gbajare sita lori ipe naa, ti woͅn si ni awoͅn oͅbayejeͅ oloselu kan lo wa ni idi isͅeͅleͅ naa.
Bakan naa ni woͅn ni awoͅn n soͅ awoͅn to n soͅroͅ kubakugbe naa loͅwoͅ-leͅseͅ, ti woͅn yoo si kosi panpeͅ woͅn laipeͅ.
Amoͅ eͅgbeͅ oselu Labour party ni awoͅn ko hu iwa aitoͅ nipa gbigba ileeͅjoͅ loͅ, lati beere fun eͅtoͅ woͅn ninu idibo sipo aareͅ to waye ni Naijiria naa.
Agbeͅnusoͅ fun eͅgbeͅ oselu naa, Yunusa Tanko ni ikoͅ oͅmoͅogun Naijiria ko lo ni iwe ofin Naijiria, nitori naa oun ti awoͅn beere loͅwoͅ ileeͅjoͅ ni lati fi idi otitoͅ muleͅ lori esi idibo sipo aareͅ to waye ni Naijiria.
Kíló fa òͅwóͅngógó tòmátò káàkiri oͅjà ní Naijiria?
Lati bi osͅu melo dieͅ seͅyin ni oͅwoͅngogo tomato ti gbode kan ni Naijiria, to fi moͅ awoͅn orileͅede koͅoͅkan ni okeere.
Awoͅn eniyan tileͅ rope osu Ramadan lo fa oͅwoͅngogo tomato ni Niajiria nitori awoͅn Musulumi ti woͅn ko sͅisͅeͅ loͅpoͅ lasiko Ramadan yii.
Amoͅ, iwadii ti fihan wi pe oͅwoͅngogo tomato naa ko niise peͅlu asiko Ramadan, kokoro to n je tomato lo n ba ere oko awoͅn agbe jeͅ.
Agbeͅ tomato kan ni ilu Kano,Muhsin Musa nibi ti oͅgbin tomato poͅ si juloͅ, soͅ fun BBC Pidgin pe oun ti soͅ gbogbo ere oko ohun nu, ni ko si si eͅyoͅ tomato kan to sͅeͅku sinu oko naa
Musa ni kii se oun nikan lo padanu ohun oͅgbin naa, to fi moͅ awoͅ agbeͅ akeͅgbeͅ oun ti woͅn joͅ n sͅisͅeͅ
O ni kokoro ajeͅnirun ‘’Tuta absoluta’’ ni ohun ba gbogbo ere oro woͅn jeͅ, to si fa oͅwoͅngogo tomato kaakiri orileͅede Naijiria.
Alaga eͅgbeͅ awoͅn oni tomato ni Kano, Alhaji Sani ni oͅwoͅngogo naa ko seͅyin pe ere oko to bajeͅ naa, to si jeͅ pe oͅpoͅ ilu ni Naijiria lo n duro de awoͅn agbeͅ lati ilu Kano lati gbe tomato wa fun woͅn.
Ninu oͅroͅ tireͅ onimoͅ nipa eto agbeͅ ni fasiti Bayero, Dr Nfiu Bala Sanda to ba BBC Pidgin soͅroͅ ni oͅna abayoͅ ni imoͅ to peye fun awoͅn agbeͅ oni tomato nipa oͅgbin naa.
O ni kii se oogun apa kokoro lo le bori kokoro ajeͅnirun Tuta Absoluta naa nitori pe o ti giran moͅ oogun apa kokoro naa.
Onimoͅ naa ni ohun ti woͅn le se ni lati tete ria mi to safihan pe kokoro naa ti sekolu si oko naa, ki woͅn si tu paleͅ ni kiakia.
Brain Drain: Àbádòfin láti dènà àwoͅn dókítà tó ń ‘jápa’ loͅ sí òkè òkun koͅjá ipele kejì ní ilé asͅòfin
Abadofin lati dena awoͅn dokita lati orileͅede Naijiria to n loͅ si oke okun ti koͅja ipele keji, ni ile igbimoͅ asofin ni Naijiira.
Ninu ateͅjade ti ile igbimoͅ asͅofin Naijiria fi si oju opo Twitter woͅn, ni woͅn ti kede reͅ.
Abadofin naa lo wa lara igbeseͅ awoͅn asͅofin lati dena bi awoͅn dokita lati Naijiria sͅe n loͅ si oke okun loͅgoͅoͅroͅ.
Woͅn ni eyi n mu ifaseͅyin ba eto ilera ni Naijiria, nitori pe awoͅn dokita ko to moͅ, ni awoͅn ileewosan kaakiri orileͅede Naijiria.
Ara alakaleͅ abadofin naa ni pe, dokita ti woͅn ba koͅ ni awoͅn ileeͅkoͅ ni Naijiria gboͅdoͅ lo oͅdun marun un lati siseͅ ni Naijiria, ki woͅn to le loͅ si okeere.
Abadofin naa ti ko yoͅ awoͅn dokita to n se itoͅju eͅyin sileͅ, lo ni woͅn ko gboͅdoͅ fun awoͅn dokita naa ni ''license'', afi ti woͅn ba ti lo oͅdun marun un ni Naijiria.
Amoͅ ateͅjade ti woͅn fi lede naa ni awoͅn asofin kan tako igbeseͅ ati abadofin naa, amoͅ pupoͅ ninu woͅn lo buwoͅlu, to si fi koͅja ipele keji.
Iwadii ti eͅgbeͅ awoͅn dokita ni Naijiria, NARD gbe jade ni, ida marunleloͅgoͅrin awoͅn dokita ni woͅn n kuro ni Naijiria loͅ gba isͅeͅ ni oke okun.
Amoͅ saaju ni ijoͅba Naijiria ti ni ko ba nkankan jeͅ, bi awoͅn dokita sͅe n kuro ni Naijiria loͅgoͅoͅroͅ.
Ìyá Wasiu Alabi Pasuma ti jáde láyé
Gbajugbaja olorin Fuji, Wasiu Alabi Odetola, ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Pasuma ti padanu iya rẹ, Alhaja Adijat Kuburat.
Olorin Fuji naa funra rẹ lo kede iku oloogbe naa ninu atẹjade kan to fi soju opo Instagram rẹ.
Pasuma sọ ninu atẹjade ọhun pe “Wura mi ọwọn! Mo maa saaro rẹ titi ayeraye.”
“Mi o mọ ohun ti mo le sọ, sun re o... ma gbagbe lati maa ṣọ mi latode ọrun.”
Ọpọ awọn ololufẹ Pasuma lo ti bẹrẹ si n ba daro iku iya rẹ naa bayii lẹyin ikede ọhun.
Ti ẹko ba gbagbe, inu oṣu Kẹsan an, ọdun to kọja ni iya olorin naa ṣe ọjọ ibi, ti Pasumo si ki ku orrirẹ.
Ọjọ naa lo tun ṣadura fun pe yoo dagba, ti yoo si jẹun ọmọ pẹ.