You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Mi ò lè wo òkú ọmọ mi, wọ́n ti gún un lọ́rùn yána-yàna; ọmọ Nàìjíríà ẹ gbà mi o!

  2. ‘Èͅfoͅn tuntun tó ń fa àìsàn ibà míràn tún ti woͅ ilú’

  3. NAFDAC fí òǹtẹ̀ lu òògùn ibà R21 Matrix

    Ajọ NAFDAC ti fọwọsi lilọ oogun iba R21/Matrix ti awọn Ọjọgbọn onimo siẹnci ile ẹkọ Faṣiti Oxford ṣe awari.

    NAFDAC ni ileeṣe Serum to wa ni orilẹede Indian, ti o si ti ṣe lo fun awọn ọmọ orilẹede yii.

    Orilẹede Naijiria ni yóò jẹ orilẹede keji ti yo fọwọsi lilọ ogun ọhun lẹyin orilẹ-ede Ghana.

    Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye, alaga ajọ NAFDAC ṣalaye wi pe oogun ọhun ni yóò mú adinku baa iku awọn ọmọde to wa laarin oṣu marun -un si ọdun mẹta.

    Adeyeye tẹsiwaju wi pe orilẹ-ede Naijiria yoo kọkọ rí ida ọgọrun-un ọkẹ oogun iba ọhun lofe, ti yo si wa kari fun lilọ awọn ile iwosan alabode.

    Ajọ NAFDAC ṣeleri lati ri wí pe awọn oogun to dara fun lilo awọn ọmọ orilẹ-ede nikan ni ajọ ọhun yoo ma fọwọsi

    Naijiria leke awọn orilẹ-ede ti iba ti ṣọsẹ ju.

    Lọdun 2021 akọsilẹ ajọ to risi ìlera lagbaye,WHO ni orilẹ-ede Naijiria lo fara kasa iku latọwọ iba julọ lagbaye.

    Gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ WHO to filede fun ọdun 2022 ni, orilẹ-ede Naijiria ko ida ọkanlelọgbọn (31.3%) lagbaye ninu awọn orilẹ-ede to fara kasa iku latọwọ aisan Iba,nigbati orilẹ-ede olominira Congo ni ida mejila le diẹ (12.6) ninu awọn ti aisan Iba gbẹmi

    Ajọ WHO ni millionu ẹta din ni ọkan lenigba eeyan lagbaye lo lugbadi aisan Iba lagbaye lọdun 2022,ti eeyan ọkan din ni okoo-le-egbẹ́ta padanu ẹmi wọn lara isẹlẹ iba

    Ajọ WHO ni awọn ọmọde laarin ọdun márùn-ún sí isalẹ lọpọlọpọ ninu awọn to padanu ẹmi nitori aisan Iba.

  4. Ẹ kéde ẹni tí ìlú yàn nínú ètò ìdìbò Gómìnà tó kọjá - Makinde sí INEC Adamawa

    Gomina ipinlẹ Oyo Seyi Makinde ti ke si ajọ eleto idibo orilẹ-ede yii (INEC) lati ṣe ohun ti o yẹ nipa pi polongo ẹni to jawe olubori ninu eto idibo gomina ipinle Adamawa.

    Saaju lojọ isinmi ọsẹ yii, nibiti wọn ti kede esi idibo ipinlẹ Adamawa, ni kọmisona ajọ eleto idibo ipinlẹ Adamawa Hudu,Yunusa Ari, ti kede Aisha Binani Dahiru oludije labẹ ẹgbẹ oṣelu APC gẹgẹ bi olubori eto idibo sipo gomina Ipinlẹ Adamawa, lodi si ilana ofin ajọ eleto idibo orilẹ-ede yi.

    Igbesẹ eyi lo da awuyewuye silẹ laarin awọn ọmọ orilẹ-ede yi, ti ajọ eleto idibo INEC naa fọwọ osi juwe ile fun Yunusa Ari lori isẹlẹ ọhun.

    Gomina Makinde nigba ti o ṣe abẹwo si Gomina Umaru Fintiri ti Adamawa ni ile ijọba ni Yola, sọ wi pe ikede Ari lori ẹniti o jawe olubori ninu eto idibo Adamawa lo ta ẹrẹ ati itiju ba ajọ eleto idibo.

    O wa gboriyin fun ajọ INEC fun iṣẹ ribiribi to ṣe nipinle Oyo, o si fi ọwọ ṣọya wi pe ajọ eleto idibo INEC yoo ṣe afihan fun gbogbo aye laipẹ

    Makinde tun rọ awọn olugbe ipinle Adamawa lati jẹ ki alafia jọba o si fi da wọn loju pe ọrọ nipa esi abajade eto idibo Adamawa yo ni iyanju laipẹ.

  5. Ọ̀gá ikọ̀ ológun méjì dojú ìja kọra ní Sudan, ó kéré tán aráàlú 100 ti pàdànú èͅmí woͅn

    O ti di oͅjoͅ keͅta bayii ti ija ti beͅreͅ ni orileͅede Sudan leͅyin ti olori ikoͅ oͅmoͅ ogun ileͅ naa ati adari eͅsoͅ alabo Rapid Support Forces koju ija si ara woͅn.

    Oͅgagun Abdel Fattah al-Barhan to jeͅ olori ikoͅ oͅmoͅogun orileͅede naa to si jeͅ aareͅ lo n doju ija koͅ igbakeji reͅ, Oͅgagun Mohammed Handan Dagalo to jeͅ adari ikoͅ militia Raid Support Forces.

    Awoͅn mejeeji ko ni adehun lori bi o se yeͅ ki woͅn tukoͅ orileͅede naa ati bi woͅn yoo se da ijoba tiwantiwa pada si orileͅede naa, leͅyin ti ikoͅ Ologun gbajoͅba nibeͅ

    Awoͅn ara agbegbe olu ilu Sudan, Hartoum ti soͅ fun awoͅn oniroyin wi pe niisͅe ni iro iboͅn ati ado oloro n dun lakoͅ lakͅ nibeͅ.

    Bakan naa ni woͅn fikun un pe, ounjeͅ ati omi ti sͅoͅwoͅn lorileͅede naa, ti awoͅn eniyan ko si ri ounjeͅ jeͅ nitori ija to n waye naa.

    Olu ilu naa ni woͅn ti n fi oju ija oͅhun juloͅ, ti oͅpoͅloͅpoͅ dukia si ti bajeͅ ni papakoͅ ofurufu lorileͅede naa.

    Bakan naa ni ija n waye ni awoͅn ilu nla kaakiri orileͅede oͅhun lai yoͅ agbegbe Dafur sileͅ ati ilu Meroe.

    Geͅgeͅ bi eͅgbeͅ dokita lorileͅede Sudan soͅ, o kere tan oͅgorun un eniyan lo ti padanu eͅmi woͅn , to si seese ki iye awoͅn eniyan to tik u ju beͅeͅ loͅ , ti oͅpoͅloͅpoͅ si farapa ninu ija to n loͅ loͅwoͅ naa.

    Ninu oͅroͅ woͅn, orileͅede Ameͅrika ati Ileͅ Geͅeͅsi ti kesi igun mejeeji lati fopin si ija naa to ti gbeͅmi oͅpoͅloͅpoͅ eniyan ti woͅn si n ja loͅ.

    Ajoͅ Isͅoͅkan Lagbaye, UN bu eͅnu ateͅ lu bi awoͅn mejeeji to n ja ko se boͅwoͅ fun ofin ati fun eͅtoͅ oͅmoͅniyan

  6. Òkú ẹni ọdún 86 pòórá ní “mortuary” bí mọ̀lẹ́bí ṣe wá gbèé fún ìsìnkú, wàhálà bẹ́ sílẹ̀!

  7. Kìí ṣe pé mo yí orin padà sí ti Ọlọ́run, ìyàtọ́ orin mi ti tẹ́lẹ̀ sí ìpè "Evangelist" ti mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà rèé - Ebenezer Obey

  8. Àwọn afurasí agbébọn jí òṣìṣé ìjọba Ogun gbé lọ́nà márosẹ̀ Eko si Ibadan

    Awọn afurasi agbebọn ti ji oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Ogun kan Popoola Olasupo gbe loju ọna marosẹ ipinlẹ Eko si Ibadan.

    Olasupo to jẹ oṣiṣẹ ajọ to n ṣe abojuto igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Ogun iyẹn, 'Trace' ni awọn afurasi agbebon naa gbe lagbegbe Eledumare si Fidiwo loju ọna marosẹ Eko si Ibadan.

    Iroyin ni Olasupo n lọ si ẹnu iṣẹ rẹ ni nkan bi ago mẹfa abọ owurọ ni ki wọn to ji i gbe lọ.

    Lara awọn ti wọn jọ wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ to n gbe e lọ si ibi iṣẹ ṣalaye pe ṣaadede ni awọn agbebon jade lati inu igbo, "lẹsẹkẹsẹ ni wọn dabon bolẹ ti wọn si ji Olasupo nìkan gbe laarin awọn ti o wa ninu ọkọ ayọkẹlẹ akero ọhun.

    Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun DSP Abimbola Oyeyemi nigba ti o n fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ ni,"awọn ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n risi iṣẹlẹ ijinigbe ti wa ninu Igbo lati ṣe awari awọn ajinigbe ọhun "a si ni igbagbo wí pe a o ri wọn mu".

    "Ipinlẹ Ogun kii ṣe ibi ti awọn ọdaran ti le maa ṣọsẹ, gbogbo wọn lọwọ ọlọpa maa tẹ, ninu kí wọn kuro nilu fún wa abi ka fi imu wọn danrin".

  9. Dino Melaye ló jáwé olúborí nínú ètò ìdìbò abẹ́lé ẹgbẹ́ PDP nìpínlẹ̀ Kogi

    Ẹniti o ti figba kan ri jẹ Sẹnetọ fun ẹkun iwo oorun Kogi, Dino Malaye ni o ti jawe olubori ninu eto idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu PDP.

    Malaye lo jawe olubori lẹyin to fidi Yomi Awoniyi, ẹniti to ti figba kan ri jẹ igbakeji gomina Ipinlẹ naa ri, Sẹneto tẹlẹri Attai Aidoko.

    Awọn miran to bá Dino Malaye du ipo naa ni Zakaria Alfa, Musa Wada, Bolu Femi, ati Idoko Idah.

    Dino Melaye lo bori idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu PDP pẹlu ibo to to ẹji din ni okoo lelọọdunrun ti ẹni to ṣe ipo kejì Idoko Lona ni ibo ẹrinle ni ogofa.

    Pẹlu esi idibo abẹle ẹgbẹ oṣelu PDP, Sẹnetọ Dino Melaye ni ireti wa wí pé yo gbe asia ẹgbẹ oṣelu PDP ninu eto idibo sipo gomina Ipinlẹ Kogi ti yo waye laipe yii

  10. Ẹ wá wo ìdí tí Iléẹjọ ṣe rọ̀ Ọba aládé lóye nípínlẹ̀ Ondo

    Ileẹjọ giga ipinlẹ Ondo to fi ilu Akure ṣe ibujoko, ti rọ Olu Oke ti Oke Igbo lagbegbe ileoluji, Ọba Babajide Lawrence Oluwole loye.

    Ile ẹjọ ni, Ọba Babajide Lawrence to gba ọpa aṣẹ gẹgẹ bi Ọba Oke Igbo lọdun 2018, ki n ṣe ọmọ molebi toye Ọba kan.

    Awọn arẹmo lati ile aarẹ Kugbaigbe, Rufus Adekanye ati Temitope Adeoye ti wọn tun jẹ olori ati akọwe ile Kugbaigbe lo pe ijọba ipinlẹ Ondo lẹjọ lori bi ijọba se yan ẹniti oye ko tọ si gẹgẹ bi Ọba ilu Oke Igbo.

    Ninu iwe ti agbẹjọro idile Kugbaigbe, Sola Ebiseni fi pe ẹjọ, o ni Ọba Babajide Lawrence ki ṣe ọmọ ẹbi Kugbaigbe toye Ọba kan.

    Adajọ Ademola Enikuemehin, nigba to gbe ẹjọ kalẹ, ṣalaye pe idile Ọba Babajide Lawrence ko lo oye Ọba ilu Oke Igbo kan, nitori na ko yẹba lori oye fun awọn idile to yẹ ko yan ọmọoye.

    Adajọ naa ni "Ninu ofin to jẹmo oye jíjẹ ni Olu-Oke ti Oke-Igbo apakeji iwadii Adajọ Adeloye lori ohun to ni ṣe lori oye jijẹ,awọn to oye tọ si ni awọn ọmọ (1)Odò Eleyowo(2)Aarẹ Kugbaigbe (3) Kuole Oloje (4) Aderin Ologbenla (5) Ajibike Adedimeji ti gbogbo ọmọkùnrin idile mararun naa lẹtọ si jijẹ Ọba ilu Oke Igbo".

    Adajọ naa ni pẹlu ilana ifọbajẹ eyi ti ofin gba laye idile Aarẹ Kugbaigbe lo lẹtọ lati fa ọmọ oye silẹ. Ile-ẹjọ paṣẹ ki Ọba Babajide Lawrence jawo ati ma pe ararẹ ni Ọba ilu Oke Igbo,tabi dahun ti wọn ba pe ni Ọba.

  11. Afurasí oníjìbìtì ayélujára 47 wọ gbaga àjọ EFCC n'Ibadan,

    Awọn afurasi ọdọ to n lu jibiti lori ẹrọ ayelujara mẹrinlelogoji ni ajọ EFCC ti fi pampẹ ofin mu ni Ibadan oluilu ipinlẹ Oyo.

    Ninu atẹjade ti ajọ EFCC fi lede lori itakun ayelujara Twitter rẹ, ajo na ni agbegbe Apete àti Bodija nipinlẹ Oyo ni awọn ti mú awọn afurasi ọdọ naa.

    Lara ohun tí ajọ EFCC gba lọwọ awọn afurasi ọdọ to n lu jibiti ni ọkọ bọgini mẹwa, kẹkẹ alupupu meji, ẹrọ ibaraẹnisọrọ mẹtaleladọta, ẹrọ kọnputa mẹrin, gbohun gbohun Jbl kan, ẹrọ ere idaraya playstation kan àti awọn ohun elo miran.

    Lara awọn afurasi ti ajọ EFCC fi pampẹ ofin mu ni

    Alonge Timilehin Israel, Akinlade Tolulope Seyi, Taiwo Oluwatobiloba Daniel, Adesina Sodiq Ishola, Victor Paul Shedrack, Olawale Oladapo Olaleye, Muili Olamilekan Sodiq, Babalola Afeez Bolaji, Adeagbo Stephen Adegbenro, Ephraim Isaiah Joshua ati awọn miran ti apapọ gbogbo wọn jẹ mẹtalelọgọta .

    Ajọ EFCC ṣeleri lati gbe wọn lọle ẹjọ nikete ti iwadii ba ti pari .

  12. Lẹ́yìn ọjọ́ méjìlá làkàtà ajínigbé, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fáṣítì méjì gba òmìnira

    Awọn ọmọbirin Faṣiti ijọba apapọ to wa ni Gusau meji ti awọn ajinigbe gbe lọ ni abule Sabon Gida to wa ni ijọba ibilẹ Bungudu lo ti ri ominira gba lọwọ awọn ajinigbe.

    Olori ẹka to ri si ibaraẹnisọrọ awọn akẹkọọ to jẹ ọmọ ipinlẹ Zamfara ni ile ẹkọ naa lo fi iroyin naa lede.

    Umar Abubakar to jẹ alukoro ẹgbẹ akẹkọọ to jẹ ọmọ bibi Zamfara, ko ṣalaye boya wọn san owo itanra ṣaaju ki awọn akẹkọọ ọhun to ri ominira gba lọwọ awọn ajinigbe.

    Awọn akẹkọọ mejeeji to n ko nipa imọ ẹya ara lo ti wa pẹlu awọn molebi wọn lẹyin ti wọn lo ọjọ mejila ninu ahamo awọn ajinigbe.

    Ọkan lara awọn akẹkọọ tiwọn ji gbe lo dupẹ lọwọ awọn obi ati ile ẹkọ rẹ fun ipa ti wọn ko lati ri wi pe awọn ri ominira gba lọwọ awọn ajinigbe ọhun.

    Atẹjade naa rọ awọn agbofinro lati fi pampẹ ofin mu awọn to wa lẹyin iṣẹlẹ ọhun ko le mu opin ba iṣẹlẹ ijinigbe lagbegbe ati ni orilẹ-ede waa sopin.

  13. Ikọ̀ ológun àti ikọ̀ 'Paramilitary' gbéná wojú ara wọn ní Khartoum, òkú sùn

    Eeyan mẹta lo ti padanu ẹmi wọn ninu ikọlu to waye laarin awọn ọmọ ogun orilẹ-ede Sudan ati, awọn iko to farapẹ ologun ni oluilu orilẹ-ede Sudan,ìyẹn khartoum.

    Ikọ ologun ati awọn ikọ to farapẹ ologun ọhun ni wọn gbena woju ara wọn lati gba iṣakoso ile ijọba, ileeṣe mohun maworan ijọba Sudan ati olu ileeṣẹ ọmọ ogun.

    Ija naa lo bẹrẹ nitori aifọkanbalẹ to tẹlẹ ipinnu lati da ijọba pada si ijọba awarawa ni Sudan.

    Awọn ọmọ-ogun orilẹ-ede Sudan sọ wi pe awọn ọkọ ofurufu ologun Sudan ti ṣe ikọlu si ibuba awọn alatako rẹ, ìyẹn Rapid support force (RSF).

    Awọn ẹgbẹ mejeeji lo si n kede wi pe awọn wa ni iṣakoso papakọ ofurufu ati awọn ibudo pataki miiran to wa ni orilẹ-ede Sudan.

    Ikọlu naa si n tẹsiwaju ni awọn agbegbe kọkan ni ilu Dafur.

    Ija naa lo n waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ to ṣe atilẹyin fun Ọgagun Abdel Fattah al-Burhan ati adari ẹka ologun RSF ti igbakeji adari orilẹede Sudan,Mohamed Hamdan Dagalo ṣe akoso rẹ.

    Ọgagun Dagalo sọ wi pe awọn ọmọ ologun RSF yo tẹsiwaju ninu ija ọhun titi gbogbo awọn ibudo ọmọ ologun yoo fi wa ni iṣakoso ikọ ologun RSF.

    Nigba ti awọn ikọ ologun Sudan fesi ,wọn ṣeleri wi pe ko ni si ijiroro kankan laarin ikọ ologun Sudan ati iko RSF titi ti ikọ naa yo fi roko igbagbe.

    Awọn aworan lati Khartoum fi bi awọn eeyan ti n sa asala fun ẹmi wọn han,ti eefin dudu gba oluilu Sudan kan,bi rogbodiyan ọhun ṣe n tẹsiwaju.

    Awọn ọkọ ofuurufu orilẹede Saudi ati ti Egypt ni wọn ti dawọ iṣe duro ni khartoum ti Chad si ti aala rẹ pẹlu orilẹ-ede Sudan paa.

  14. Ọkùnrin tó wọ aṣọ ẹ̀há láti kópa nínú ìdíje àwọn obìnrin kó sí páńpẹ́ òfin

  15. Àwọn tó sun ọmọ mi níná ní ó wọ aṣọ olówó ńlá táwọn kò rí irú rẹ̀ wọ̀, ni wọn ṣe pa á - Ìyá Tope Olorunfemi

  16. Àjọ NDLEA ṣàwárí oko mẹ́ta tí wọ́n ti ń gbin igbó ní Katsina

    Àjọ tó ń gbógunti àwọn egbògi olóró ní Nàìjíríà, NDLEA ní àwọn ti ṣàwárí oko ńlá mẹ́ta tí wọ́n ti ń gbin igbó ní ìpínlẹ̀ Katsina.

    Igbákejì ọ̀gá àgbà àjọ náà ní ìpínlẹ̀ Katsina, Halilu Hamida ní àwọn kan ló ta ilé iṣẹ́ àwọn nípa àwọn oko náà.

    Hamidu ní ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí àwọn máa ṣàwárí oko igbó báyìí ní ìlú Sobashi, ìjọba ìbílẹ̀ Dutsi.

    Ó ní àwọn olóko náà fi gbíngbin ata, ẹ̀fọ́ àti àwọn nǹkan mìíràn bójú àmọ́ tó jẹ́ wí pé igbó gangan ni wọ́n gbìn sínú oko náà.

    NDLEA ní ọwọ́ ti tẹ ọ̀kan nínú àwọn afurasí tó ni oko igbó náà tí àwọn sì ń ṣiṣẹ́ láti ṣe àwárí àwọn yòókù náà.

    Ó ní ó dá àwọn lójú pé ọwọ́ máa tó ba àwọn yòókù náà nítorí ìwádìí àwọn ti lékún si.

    Hamidu tún fi kun pé oko igbó tí àwọn rí náà tó mílíọ̀nù mẹ́wàá níye tí èyí sì jẹ́ ìpèníjà ńlá fún ìlú.

  17. Tiwa Savage móríbọ̀ lọ́wọ́ àwọn ajínigbé ní ilé rẹ̀

    Gbajúgbajà olórin tàkasúfèé nnì, Tiwatope Savage tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Tiwa Savage ti ní àwọn kan gbèrò láti yawọ ilé òun láti jí òun gbé lọ́jọ́bọ̀.

    Tiwa Savage ló fi ìròyìn náà sójú òpó Instagram rẹ̀ nínú àtẹ̀jáde látọwọ́ àwọn alákòso rẹ̀.

    Àtẹ̀jáde náà ní àwọn kan fẹ́ wọ ilé Tiwa Savage àmọ́ tí orí ko yọ.

    Bákan náà ni wọ́n ní ọwọ́ àwọn tẹ díẹ̀ nínú àwọn afurasí náà, tí wọ́n sì ti wà ní àgọ́ ọlọ́pàá Alagbon tó wà ní Ikoyi.

    Àtẹ̀jáde náà fi kun pé Tiwa Savage àti àwọn ẹbí rẹ̀ wà ní àláfíà.

  18. Wọ́n ṣàwárí òkú ẹnìkan níbi ilé tó dàwó ní Eko

    Àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko, LASEMA ti yọ òkú ènìyàn kan níbi ilé tó dàwó ní 1st Avenue, Banana Island, Ikoyi.

    Kọmíṣọ́nà fétò ìbáraẹnisọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n inú ìpínlẹ̀ Eko, Gbenga Omotoso nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ibi tí iṣẹ́ dé níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

    Omotoso ní LASEMA ṣiṣẹ́ takuntakun láti ṣàwárí ẹnìkan tí wọ́n alámòjútó ilé náà ní àwọn kò ì tíì rí láti ìgbà tí ilé náà tí dàwó.

    Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́rú ni ilé alájà méje náà tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ ṣàdédé dàwó tí àwọn òṣìṣẹ́ ibẹ̀ sì farapa.

    Ó ní ènìyàn mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ níbi ilé náà ni wọ́n ti ṣáájú dóòlà nígbà tí ilé náà dàwó.

    Ó fi kun pé gbogbo àwọn ènìyàn ọ̀hún ni wọ́n wà ní àláfíà.

    Omotoso ní kò sí ẹni tó mọ̀ wí pé ẹni tí wọ́n rí òkú rẹ̀ yọ ní àárọ̀ yìí wà níbẹ̀ nígbà tí wọ́n ń ka orúkọ àwọn ènìyàn tó wà níbi iṣẹ́ lọ́jọ́ náà.

  19. "Àìrí ìyàwó fẹ́, ló mú mi ṣe iṣẹ́ abẹ lẹ́ẹ̀mejì láti ga si"

  20. Wo èníyàn 100 , tó fi mọ́ Bola Tinubu, tó gbajúgbajà jùlọ ní ágbàyé