Bi idibo yoo ti ṣe lọ, Ilana ti INEC la kalẹ fun idibo nipinlẹ Kogi re e
Ajọ Eleto Idibo, INEC ti ni aago mejọ aarọ si meji ọsan ni ayẹwo orukọ yoo bere
Ẹni ti o ba de agọ idibo ki aago meji ọsan to lu ni wọn yoo fun laaye lati dibo.
Kaadi idibo ni wọn yoo lo lati fi se idibo naa.
Osisẹ Ajọ INEC yoo beere kaadi idibo rẹ lati se ayẹwo orukọ rẹ boya o fi orukọ silẹ.
Wọn ti kilọ fun awọn eniyan lati fi ago idibo silẹ ni kete ti wọn ba ti dibo wọn tan.
Ko gbọdọ si lilo ẹrọ ibanisọrọ ni ayika ibi ti idibo ba ti n lọ lọwọ.




