Wo bí àjọyọ̀ ṣe ń lọ lọ́wọ́ ní Kogi 'toríi Yahaya

Ẹ kaabọ si oju opo BBC Yoruba. Wọnyii ni ohun ti awọn akọ̀ròyìn wa to ti wa ni ikalẹ ni ipinlẹ Kogi ati Bayelsa.

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Yetunde Olugbenga

  1. Yagba East LGA

    APC: 6735

    PDP: 7546

    SDP: 220

  2. Kogi

    APC: 14097

    PDP: 9404

    SDP: 657

  3. Kabba Bunu

    APC: 15364

    PDP: 8084

    SDP: 364

  4. Okene LGA

    APC: 112764

    PDP: 139

    SDP: 50

  5. Igalamela Odolu

    APC: 8075

    PDP: 11195

    SDP: 208

    Ni ijọba ibilẹ yii, wọn wọgile ibo ni ibudo idibo marun nitori iwa ipa lasiko idibo ati pe ibo pọ ju iye to yẹ lọ.

  6. Adavi LGA

    APC: 64657

    PDP: 366

    SDP: 279

    Ni Adavi, esi ibudo idibo mẹwa ni wọn wọgile toripe iye ibo ju iye oludibo to forukọ silẹ lọ.

    Aṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP kọ esi ti ajọ INEC kede fun ijọba ibilẹ Adavi pe wọn ko jẹ kawọn ṣamojuto ibo naa.

  7. Omala LGA

    APC: 8473

    PDP: 14403

    SDP: 567

    Ni ijọba ibilẹ Omala, wọn wọgile esi idibo ibudo iforukọsilẹ mẹrin nitori iwa ipa lasiko idibo - Akpata, Ogbodu, okpatala, Odiaje eyi si ṣakoba fun ibudo idibo marun.

  8. Ijumu LGA

    APC: 11425

    PDP: 7587

    SDP: 223

    Ni ijọba ibilẹ Ijumu, kọnunkọhọ fẹ wa ni ibudo iforukọsilẹ to si ko ba ibudo idibo marun. Laarin idibo, ojo ibọn bẹrẹ si ni rọ, awọn eeyan si sa asala fun ẹmi wọn. Wọn ko pada lati kopa ninu idibo naa. Bakan naa ni wọn wọgile idibo lawọn ibudo kọọkan ti ko ni kaadi to n ṣe ayẹwo oludibo.

  9. Ogori/Magongo

    APC: 3679

    PDP: 2145

    SDP: 244

  10. Ẹ wo ẹni tó ń lékè nínú ìdìbò gómìnà Kogi

    Ikede idibo ti gberasọ ni ipinlẹ Kogi bayii. Nkan bii ijọba ipinlẹ mẹrinla lo ti pari akojọpọ ti wọn si ti ṣe tan lati kede esi idibo wọn ni olu ileeṣẹ ajọ eleto idibo to wa ni ilu Lokoja, ipinlẹ Kogi.

    Bakan naa, wọn n reti akojọpọ esi lati ijọba ibilẹ mọkanlelogun.

    Bi esi gomina Kogi ṣe n jade
  11. Fídíò bó ṣe ń lọ ní àjọ INEC ìpínlẹ̀ Kogi

  12. Àwòrán àwọn aráàlù tó kára mọ́ àbájáde ìdìbò.

    Ọkan lara ibudo idibo kika
    Ọkan lara ibudo idibo kika
    Aṣoju ẹgbẹ oṣelu kan to mu kika esi lọkunkundun
  13. Ìbátan Dino Melaye bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn lọ lásìkò ìdìbò

    Ikede ibanujẹ ni sẹnetọ Dino Melaye fi ṣe lowurọ yii loju opo twitter rẹ pe ibatan oun kan wa lara awọn ti wọn yinbọn lu lanaa lasiko rogbodiyan to waye nibi idibo to waye ni ipinlẹ Kogi lọjọ abamẹta to kọja.

    Dino kede pe ibatan oun ọhun jẹ Ọlọrun nipe lowurọ yii.

    Skip X post
    Allow X content?

    This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

    Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

    End of X post

  14. Àwọn àwòrán láti ibùdó tí wọ́n ti ń ka èsì ìdìbò

    Lati ajọ INEC ipinlẹ Kogi

    Ibi ti ibo kikojọ ti n waye ni Kogi
    Awọn esi idibo sẹnetọ to ti jade
    Awọn oniroyin n reti lati gberoyin safẹfẹ
    Ajọ eleto idibo
  15. Lọwọlọwọ, ajọ INEC ti n ka esi idibo ẹni ti yoo ṣoju ipinlẹ Kogi gẹgẹ bii sẹnetọ nile igbimọ aṣofin agba Naijiria.

    Kabba/Bunu LGA

    APC 15,037 PDP, 8974

    Ijumu LGA APC 11627 PDP 7647

    Kogi Koton-Karfe APC 14,168 PDP 9786

    Mopa Muro APC. 4874 PDP. 3704

    Yagba East APC. 6683 PDP. 7745

    Dino Melaye ati oludije alatako rẹ, Smart Adeyemi

    Oríṣun àwòrán, @DinoMelaye, @Smart Adeyemi

  16. Nínú Dino àti Smart, ta ni yóò gbégbá orókè?

    Ẹ ku ojumọ, ẹ ṣaa mọ pé a kii wi bẹ́ẹ̀ ka ma ṣe bẹẹ lede BBC Yoruba. Gẹgẹ bí ẹ ṣe gbadun gbogbo bo ṣe n lọ ti a mu wa fun un yin lanaa lati ipinlẹ Kogi ati Bayelsa, a tun ti ji si i lowurọ yii.

  17. A sa ipá gbogbo tó yẹ, ṣùgbọ́n òde kò dùn níbi ìdìbò Kogi àti bayelsa-INEC, INEC ní ọgbẹ́ ọkàn ni ètò ìdìbò Kogi àti Bayelsa jẹ́, pẹ̀lú owó tó wọlẹ̀ sí ètò wọn

    Ajọ INEC ni ibanujẹ ati ọgbẹ nla ni abajade eto idibo to waye ni ipinlẹ Kogi ati Bayelsa jẹ fun awọn paapaa julọ pẹlu eto ati igbaradi gbogbo ti wọn gbe kalẹ fun.

    Amugbalẹgbẹ fun alaga ajọ INEC, ọjọgbọn Mahmud Yakubu, iyẹn Ọgbẹni Rotimi oyekanmi lo sọ bẹẹ lasiko to fi n sọrọ lori ileeṣẹ tẹlifiṣan abẹle kan lorilẹede Naijiria.

    O ni pẹlu gbogbo ipade ati adehun alaafia ti ajọ naa atawọn olukopa ninu idibo naa tọwọ bọ, ọkan balẹ pe ko yẹ ki omi ti ẹyin wọ igbin eto idibo naa lẹnu.

    O ni ohun to yẹ kawọn oloṣelu o mọ ni pe, owo ilu ni wọn fi n ṣe awọn idibo wọnyii, owo oju eegun si ni.

    Ajọ INEC ni oun ti n gba abọ latọwọ awọn aṣoju rẹ gbogbo to wa nigboro lasiko idibo, ti wọn si ti n gbe e yẹwo.

    O ni ajọ naa gbiyanju ipa tirẹ, ṣugbọn igboro ko dun nibi oṣelu naa

    Awọn oludibo atawọn oṣiṣẹ INEC letido kan ni ipinlẹ Bayelsa

    Oríṣun àwòrán, INEC

  18. Kò dín léèyàn méjìlélógún tọ́wọ́ ọlọ́pàá ti tẹ̀ lórí wàhálà ìdìbò ní Kogi-Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá, Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá ní ọpẹ́lọpẹ́ iṣẹ́ ìfimúfínlẹ̀ tó wáyé ṣáájú ìdìbò ni kò jẹ́ kí rògbòdìyàn ìdìbò ní Kogi ó pọ̀ ju èyí tó wáyé lọ.

    Ileeṣẹ ọlọpaa ni ko din ni eeyan mejilelogun ni ọwọ ti tẹ lori rogbodiyan to waye lasiko idibo nipinlẹ Kogi.

    Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Frank Mba lo ṣalaye ọrọ yii lasiko to fi n sọrọ lori ileeṣẹ mohunmaworan abẹle kan lorilẹede Naijiria lalẹ ọjọ Satide lẹyin ti ibo didi pari lawọn ipinlẹ mejeeji.

    Bakan naa lo ni ọkọ kan tawọn janduku fẹ fi lọ hu iwa laabi wọn lagbegbe kan ni Kogi lọwọ awọn ọlọpaa tun tẹ.

    O fi kun pe oniruuru ibọn pẹlu ọkẹaimoye ọta ibsn ni wọn tun gba lọwọ awọn ọdaluru kan nipinlẹ naa.

    Ọga ọlọpaa Frank Mba ni awọn oloṣelu pẹlu iwa booba o pa, boo ba o bu u lẹsẹ ati iwa afemi-afemi wọn lo fa gbogbo rukerudo to waye lasiko idibo ni ipinlẹ mejeeji, paapaajulọ nipinlẹ Kogi.

    Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria

    Oríṣun àwòrán, Nigeria police force

  19. Àwọn jàndùkú s'èèyàn mẹ́ta dèrò ọ̀run ọ̀sán gangan níbùbó ìdìbò nílùú Lokoja

    Àkọlé fídíò, Ìbànújẹ́ dorí àgbà kodó lẹ́yìn táwọn jàndùkú yìnbọn pàyàn mẹ́tní Kogi

    Ọfọ nla ṣẹ niluu Adankolo ni Lokoja lẹyin tawọn janduku kan dabọn bolẹ nibi eeyan mẹta ti dero ọrun ọsan gangan.

    Awọn eeyan to ba BBC sọrọ ṣalayẹ pe niṣe lawọn janduku naa ṣadeede yabo ibudo idibo tawọn ti n dibo, bẹẹ ni wọn si bẹrẹ si ni yinbọn.

    Ọpọ eeyan laa gbọ pe wọn si n gba itọju nile iwosan bo tilẹ jẹ pe onikaluku fẹsẹ fẹẹ nigba tawọn kọlọnbiti ẹda naa de.

  20. Ìdìbò ti parí ní ìpínlẹ̀ Kogi àti Bayelsa tí ìbò gómìnà ti wáyé

    Awọn oṣiṣẹ INEC

    Ni bayii, awọn eeyan ti dibo tan nipinlẹ Kogi ati Bayelsa.

    Lẹyin ọpọ faakaja to ṣẹlẹ lawọn ibudo idibo kan nipinlẹ mejeeji ti ibo gomina ti waye, kika ibo lo ku bayii.

    O ṣeni laanu pe awọn janduku ṣekupa eeyan mẹta niluu Adankolo ni ipinlẹ Kogi.