Wo bí àjọyọ̀ ṣe ń lọ lọ́wọ́ ní Kogi 'toríi Yahaya

Ẹ kaabọ si oju opo BBC Yoruba. Wọnyii ni ohun ti awọn akọ̀ròyìn wa to ti wa ni ikalẹ ni ipinlẹ Kogi ati Bayelsa.

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Yetunde Olugbenga

  1. Àwọn agunbanirọ ti ko awọn ohun eelo kuro lọ si ibudo idibo ni Bayelsa, Iṣẹ eto idibo ti bẹrẹ ni kikun ni ipinlẹ Bayelsa

    Awọn agunbanirọ lọkunrin lobinrin ni wọn n sin ilẹ Baba wọn nipa kikopa ninu eto idibo to n lọ lọwọ ni bayelsa

    Àkọlé fídíò, Iṣẹ eto idibo ti bẹrẹ ni kikun ni ipinlẹ Bayelsa
  2. Idibo ṣi n lọ lọwọ ni wọọdu kinni ẹka 033 ni Kogi, Awọn oludibo ti jade wa yan ẹni to wu wọn ni Kogi

    Agbegbe Attah Frontage ti ibudo idibo yii wa ni Lokoja ni ọpọ ero ti to lọwọọwọ wa yan ẹni ti ọkan wọn fẹ.

    kogi
    Àkọlé àwòrán, Awọn oludibo ni ipinlẹ Kogi ti n yan ẹni to wu wọn sipo lasiko yii
    kogi
    Àkọlé àwòrán, Awọn oludibo ti jade wa yan ẹni to wu wọn ni Kogi
    kogi
    Àkọlé àwòrán, Agbegbe Attah Frontage ti ibudo idibo yii wa ni Lokoja
  3. Awọn ọkọ ṣi n rin lopopona marosẹ ni Kogi, Opopona Lokoja si Osaba ree tawọn awakọ n wakọ wọn laisi wahala

    Awọn awakọ n ba iṣẹ oojọ wọn lọ ni opopona Kogi

    kogi
    Àkọlé àwòrán, Opopona Lokoja si Osaba ree tawọn awakọ n wakọ wọn laisi wahala
    kogi
    Àkọlé àwòrán, Awọn awakọ n ba iṣẹ oojọ wọn lọ ni opopona Kogi
  4. Saraki: Kò sí ẹni tó máa n borí nínú ìdìbò, orilẹ-ede ati ipinlẹ lo maa n pegede!, Ko yẹ ki eto idibo maa mu ẹni ati dukia awọn eeyna dani- Saraki

    Bukola Saraki to jẹ aarẹ ile igbimọ Aṣofin Naijiria tẹlẹ ti gba awọn oludibo ni imọran lati ṣọra ṣe ki wọn wa ni alaafia.

    Skip X post
    Allow X content?

    This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

    Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

    End of X post

  5. Awọn oludibo to lọwọọwọ ni Okenne, INEC ni idibo wọn ti bẹrẹ ni pẹrẹwu

    Awọn eniyan Okenne ti bẹrẹ idibo ni pẹrẹwu- INEC

    Skip X post
    Allow X content?

    This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

    Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

    End of X post

  6. Ọ̀kan mí balẹ pé má jáwé olubori-Gómìnà Yahaya Bello, Idibo ti bẹrẹ ni ilu Gomina Yahaya Bello

    Awọn oludibo ti bẹrẹ si ni tẹka foludije to wu wọn ni ilu Gomina Yahaya Bello ti ṣe Okene.

    Gomina naa ati iyawo rẹ na si ti tẹka.

    Lẹyin to tẹka tan ni ibudo idibo rẹ to wa ni unit 11 Okene Eba Agasa Ahache ni ijọba ibilẹ Okene o sọ fawọn akọroyin pe ọkan ohun balẹ pe oun yoo jaweolubori.

    Akọroyin wa jabọ pe awọn oludibo ni Unit 34 Okene paapa julọ awọn obinrin tete jade lati wa dibo ti awọn kan si ti dibo lẹyin ayẹwo to peye lati ọdọ awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo to wa nibẹ.

    Kogi Elections
    Àkọlé àwòrán, Gomina Yahaya Bekllo ati Iyawo rẹ nibi to ti tẹka
    oludibo Kogi
    Àkọlé àwòrán, Aworan awọn oludibo Kogi
    Idibo Kogi
    Àkọlé àwòrán, Aworan awọn oludibo to n tẹka
  7. Awọn agunbanirọ ti bẹrẹ iṣẹ akọni fun orilẹ-ede wọn ni ipinlẹ Bayelsa, Agunbanirọ ti gba awọn ohun eelo ti wọn nilo lati fi ṣeto idibo oni ni Bayelsa

    Awọn akọni ọmọ Naijiria ti n ṣiṣẹ sin orilẹ-ede baba wọn lati kopa ninu eto idibo oni ni Bayelsa

    Bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Agunbanirọ ti gba awọn ohun eelo ti wọn nilo lati fi ṣeto idibo oni ni agbegbe BDGS ni Ovom ni ipinlẹ Bayelsa
    Bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Awọn akọni ọmọ Naijiria ti n ṣiṣẹ sin orilẹ-ede baba wọn lati kopa ninu eto idibo oni ni Bayelsa
    Bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Tọkunrin tobinrin agunbanirọ lo n ṣiṣe ni Bayelsa
    Bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Agunbanirọ ti gba awọn ohun eelo ti wọn nilo lati fi ṣeto idibo oni ni Bayelsa
    Bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Awọn akọni ọmọ Naijiria ti n ṣiṣẹ sin orilẹ-ede baba wọn lati kopa ninu eto idibo oni ni Bayelsa
    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Agunbanirọ ti gba awọn ohun eelo ti wọn nilo lati fi ṣeto idibo oni ni Bayelsa
  8. Ìdìbo ko ti i bẹ̀rẹ̀ ni Kogi

    Bó tílẹ̀ jẹ́ pé ààgo mẹ́jọ ti lù, ìdìbò ko ti i gbéra sọ láwọ́n ibùdó ìdìbò kọ̀ọ̀kan ni Lokoja

    Àwọn oludibo
    Àkọlé àwòrán, Awọn èrò to n dúró láti dibo ni Yaragi
    Awon ènìyàn Kogi ni Lokoja
    Àkọlé àwòrán, Ggbogbo awon to n reti ki ìdìbò bẹ̀rẹ̀ lágbegbe wọ́n lo n duro rororo
  9. Gbogbo ọna lo dá páropáro ni Bayelsa lataarọ oni, Opopona marosẹ Sani Abacha lo da wẹ́mú yìí!

    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Opopona marosẹ Sani Abacha lo da wẹ́mú yìí!
    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Bi eṣinṣin ba kọja lọna aitọ ni opopona marosẹ Sani abacha yii, awọn agbofinro a wọ́n ọn!
    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, 'Fly over' opopona olori oke kan ṣoṣo to wa ni Bayelsa ree ti gbogbo ẹ dakẹ jẹjẹ nibẹ laarọ yii
    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Opopona Madeford Okilo to jẹ marosẹ ti ẹsẹ kii gba ero nibẹ tẹlẹ lo da to bayii laarọ nitori idibo oni
  10. 923, 182 ni àwọn oludibo to forukọ silẹ ni Bayelsa lati dibo loni- INEC, Ijọba ibilẹ mẹjọ ni Bayelsa ni, nibẹ naa ni awọn oludibo a ti ni agbara lati dibo yan gomina tuntun ti wọn ba fẹ sipo loni

    Ibudo iforukọsilẹ marun le lọgọrun un ni wọn ti ṣeto iforukọ silẹ ni Bayelsa.

    Ibudo idibo 1,804 ni eto idibo ti maa waye loni ni Bayela.

    oludibo 889, 308 lo ti gba kaadi idibo.

    Egbẹ oṣelu marundinlaadọta lo maa kopa pẹlu awọn oludije wọn.

    Bayelsa
    Àkọlé àwòrán, oludibo 889, 308 lo ti gba kaadi idibo.
    Bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Ibudo idibo 1,804 ni eto idibo ti maa waye loni ni Bayela.
    Bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Ibudo iforukọsilẹ marun le lọgọrun un ni wọn ti ṣeto iforukọ silẹ ni Bayelsa.
  11. Awọn eniyan lẹkun ori omi naa ti n reti awọn oṣiṣẹ eleto idibo ni Bayelsa

    Awọn oṣiṣẹ eleto idibo ti gori omi lati lọ sawọn ẹkun

    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Awọn oṣiṣẹ eleto idibo ti ko awọn ohun eelo idibo kaakiri Bayelsa
  12. Awọn eeyan Kogi fẹ ijọba to nifẹ ara ilu

    Ṣaaju idibo ni Kogi,ikọ BBC ba awọn ara ilu sọrọ nipa afojusun wọn lori idibo ti wọn fẹ kopa ninu rẹ.

    Ẹ gbọ ohun ti wọn sọ ninu fọnran fidio to wa labẹ yi.

    Àkọlé fídíò, Ohun tawọn eeyan Kogi n sọ saaju idibo Gomina
  13. Awọn oṣiṣẹ eleto idibo ti ko awọn ohun eelo idibo kaakiri Bayelsa, Awọn kaadi idibo ati awọn ohun eelo ẹlẹgẹ ati eyi ti kii ṣe ti ẹlẹgẹ ti n tẹ awọn oṣiṣẹ eleto idibo lọwọ ni Bayelsa

    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Awọn oṣiṣẹ eleto idibo ti ko awọn ohun eelo idibo kaakiri Bayelsa
    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Awọn oṣiṣẹ eleto idibo ti ko awọn ohun eelo idibo kaakiri Bayelsa
  14. Kò sí aàyè fún ìbò rírà àti títà ni Kogi àti Bayelsa- IGP, Oga agba awọn ọlọpaa ni Naijiria, Mohammed Adamu lo fi ọrọ yii sita pe ko ni si aaye fun magomago kankan lasiko eto idibo to m bọ yii.

    O ni oun n kilọ fawọn to ba n gbero lati fa wahala kankan lasiko idibo sipo gomina to m bọ lọna ni ipinlẹ Kogi ati Bayelsa.

    Adamu Mohammed ni ọwọ ofin yoo mu ẹnikẹni to ba n gbiyanju lati ta tabi ra ibo gomina ni ipinlẹ mejeeji ti idibo ti m bọ lọna.

    igp
    Àkọlé àwòrán, Mahmood Yakubu ni awọn ipinlẹ mejeeji lo ti n ri iṣẹlẹ awọn to n niwa ipa nibi ti aya awọn mii ti fẹ maa ja.
  15. Awọn oṣiṣẹ eleto idibo ti n gbe awọn ohun eelo idibo lọ kaakiri ipinlẹ Bayelsa, Kogi àti Bayelsa 2019: ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ náà ti fọ́nká sí ìgboro Kogi

    Awọn oṣiṣẹ eleto aabo ti n gbe awọn ohun eelo idibo lọ kaakiri ijọba ibilẹ mẹjo to wa ni ipinlẹ Bayelsa

    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Awọn oṣiṣẹ eleto aabo ti n gbe awọn ohun eelo idibo lọ kaakiri ijọba ibilẹ mẹjo to wa ni ipinlẹ Bayelsa

  16. Aarẹ Buhari ko fẹ ki idibo Kogi ati Bayelsa waye lẹyin rẹ, Aarẹ Buhari tajo de ṣaaju idibo Kogi ati Bayelsa

    Aarẹ Muhammadu Buhari naa yoo foju ri bi idibo Kogi ati Bayelsa yoo ti ṣe lọ ni ọjọ Abamẹta lẹyin to tajo de lalẹ ọjọ Eti.

    Oluranlọwọ rẹ lori ọrọ ibaraẹnisọrọ lori ayelujara Bashir Ahmad lo fi aworan ati fọnran fidio ibi ti aarẹ Buhari ti balẹ nilu Abuja.

    Ṣaaju ni aarẹ Buhari ti parọwa sawọn oludije ati eeyan ipinlẹ wọn yi lati dibo ni irọwọrọsẹ.

    Skip X post
    Allow X content?

    This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

    Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

    End of X post

  17. Kogi & Bayelsa Polls: Buhari ní ìdìbò gómìnà gbọdọ̀ lọ nírọwọ́ rọsẹ̀, Buhari parọwa fun awọn eniyan ipinlẹ Kogi àti Bayelsa

    Ṣaaju idibo gomina nipinlẹ Kogi ati Bayelsa lọjọ Satide ọsẹ yii, Aarẹ Muhammadu Buhari ti kilọ fawọn oṣiṣẹ eleto aabo lati dena awọn janduku to ba fẹ ji apoti idibo gbe.

    Buhari ninu atẹjade to fi sita lati ọwọ oludamọran pataki lori ọrọ iroyin, Garba Shehu, sọ fawọn oṣiṣẹ eleto aabo pe ki wọn ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ, ki wọn rii pe awọn eeyan dibo gẹgẹ bi ẹtọ wọn.

    Aarẹ ni ẹnikẹni ko gbọdọ dunkoko mọ ẹnikan tabi dena ẹnikẹni lati dibo gẹgẹ ẹtọ wọn.

    Bakan naa ni aarẹ Buhari kepe awọn oludibo nipinlẹ Bayelsa ati Kogi lati ṣe jẹẹjẹ nibudo ibudo idibo, ki wọn si dibo lalaafia gẹgẹ bi ofin ti laa kalẹ.

    buhari
    Àkọlé àwòrán, AarẹBuhari parọwa fun awọn eniyan ipinlẹ Kogi àti Bayelsa
  18. Lati ana, ọjọ kẹẹdogun ni wọn ti n pin awọn nkan eelo, Awọn agbofinro ni Bayelsa ti bẹrẹ iṣẹ ni Bayelsa

    Bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Awọn agbofinro ni Bayelsa ti bẹrẹ iṣẹ ni Bayelsa
  19. Awọn oṣiṣẹ eleto aabo ti n gba awọn ohun eelo idibo ni Banki Naijiria, Yenogoa to jẹ olu ilu ipinlẹ Bayelsa ni wọn ti n gba a

    Banki Naijiria ti wọn ti n gba awọn ohun eelo idibo ni yii

    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Yenogoa to jẹ olu ilu ipinlẹ Bayelsa ni wọn ti n gba a
  20. Bi nkankan ba ṣẹlẹ ni idibo Kogi,Yahaya Bello ni ki ẹ dimu-Fayose

    Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹri Ayodele Fayose ti figbe ta ṣaaju idibo Kogi pe Gomina Yahaya Bello ko fẹ ki idibo lọ ni irọwọ rọsẹ.

    Loju opo Twitter rẹ lo fi ọrọ yi si ti o si pẹlu bi wọn ti ṣe n dunkoko mọ oludije ẹgbẹ SDP Natasha Akpoti ati Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo ṣe afihan pe nnkan ko le rọgbọ.