Wo bí àjọyọ̀ ṣe ń lọ lọ́wọ́ ní Kogi 'toríi Yahaya

Ẹ kaabọ si oju opo BBC Yoruba. Wọnyii ni ohun ti awọn akọ̀ròyìn wa to ti wa ni ikalẹ ni ipinlẹ Kogi ati Bayelsa.

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Yetunde Olugbenga

  1. Ayédèrú sọ́jà yìnbọn pa èèyan mẹ́ta níbùdó ìdìbò Adankolo ní Kogi

    Awọn oludibo

    Ibanujẹ dori agba kodo niluu Adankolo nigba tawọn ayederu ọmọ-ogun yinbọn pa eeyan mẹta.

    Niṣe lawọn eeyan n sunkun ti wọn n fẹsẹ janlẹ niluu ọhun.

    Akọroyin BBC ṣalaye pe wọn ti ọkan lara awọn toku lọ si ile igbokusi

  2. Àwọn jàndùkú dojú àpótí ìbò bolẹ̀ ní Lokoja

    Àkọlé fídíò, Àwọn jàndùkú dojú àpótí ìbò bolẹ̀ ní Lokoja

    Ọrọ di bo o lọ, o ya n mi lẹyin tawọn ọmọ gọnfe da ibudo idibo lagbegbe Madabo ru niluu Lokoja.

    Awọn janduku yii laa gbọ pe wọn doju apoti ibo bolẹ tawọn eeyan si fẹsẹ fẹẹ.

  3. Lákọlákọ ni ìbọn n ro ni ibudo idibo Dino Melaye ni Kogi

    Ibrahim Issa to jẹ akọroyin BBC to wa ni ibudo idibo naa ni ayetoro ni ipinlẹ Kogi ṣalaye pe ko pe wakati kan lẹyin ti Dino Melaye dibo tan ni awọn kan deede wọle ti wọn si da ibọn bolẹ nibẹ.

    O ni wọn de ninu ọkọ Hilux ati Honda kan ti wọn si n ṣina bolẹ ti wọn si lọ gbe apoti ibo.

    O ni ibọn ba ọdọmọkunrin kan ti awọn eeyan gba pe o n jẹ Dami lejika ti wọn si ti gbe e lọ sile iwosan.

    oludibo
    Àkọlé àwòrán, O ni wọn ko pada ri apoti ibo naa gbe lọ ṣugbọn ko sẹni to le sunmọ ibẹ nitori onikaluku dori ẹ mọ.
    kogi
    Àkọlé àwòrán, O ni wọn de ninu ọkọ Hilux ati Honda kan ti wọn si n ṣina bolẹ ti wọn si lọ gbe apoti ibo.
  4. Eto idibo ti n pari ni awọn ibudo idibo kọọkan ni Lokoja ni ipinlẹ Kogi

    Awọn ibudo idbo kọọkan ni Lokoja to jẹ olu ilu ipinlẹ Kogi ti n pari idibo ti wọn bayii.

    Kogi
    Àkọlé àwòrán, Awọn ibudo idbo kọọkan ni Lokoja to jẹ olu ilu ipinlẹ Kogi ti n pari idibo ti wọn bayii.
    kogi
    Àkọlé àwòrán, Awọn ibudo idbo kọọkan ni Lokoja to jẹ olu ilu ipinlẹ Kogi ti n pari idibo ti wọn bayii.
  5. Gomina Seriake Dickson to n kuro lori aleefa ni ipinlẹ Bayelsa bayii naa ti dibo

    Gomina Dickson dibo rẹ ni Toru Orua ijọba ibilẹ Sagbama ni ipinlẹ Bayelsa fun gomina to wuu lati gba ipo oun

    bayelsa

    Oríṣun àwòrán, Bayelsa state house

    Àkọlé àwòrán, Gomina Dickson dibo yan ẹni to fẹ ko rọpo rẹ nile ijọba ni Yenagoa
  6. INEC- fopin si eto idibo to n lọ lọwọ ni Ologi ni ipinlẹ Bayelsa

    Ogbeni Nwanchukwu Orji o jẹ alamojuto eto idibo ijọba ibilẹ Ogbia ti kede pe bo tilẹ jẹ pe eto idibo naa lo deede lawon agbegbe naa ṣugbọn bẹẹ kọ lọmọ ṣori ni Ologi ni ipinlẹ Bayelsa.

    Nwanchukwu ni awọn ọmọ ita ya bo agbegbe Ologi ti wọn si ko awọn ohun eelo idibo to yẹ ki wọn ko lọ sibudo idibo ti wọn si sun wọn nina.

    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Awọn ọmọ ita ti sun ohun eelo idibo nina ni agbegbe Ologi nijọba ibilẹ Ogbia ni Bayelsa
  7. Oludije ADP ni Bayelsa, Patrick A Felegha naa ti dibo

    Patrick dibo ni wọọdu kẹsan an, ni ijọba ibilẹ Guusu Ijaw ni ipinlẹ Bayelsa.

    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, O ṣapejuwe eto idibo naa pe o lọ ni irọwọrọsẹ.
  8. Goodluck rọ awọn ọdọ ipinlẹ mejeeji pe ki wọn maa fi ifẹ ati ootọ inu wa ogo orilẹ-ede wọn.

    Jonathan ni ki awon eniyan Bayelsa gba alaafia laaye

    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Jonathan ni ki awon eniyan Bayelsa gba alaafia laaye
    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Jonathan ni ki awon eniyan Bayelsa gba alaafia laaye
  9. Aarẹ àná, Goodluck Jonathan ba awọn eniyan Bayelsa sọrọ léyin to dibo yan gomina to fẹ tan!, Awọn Onwoye idibo ni ipinlẹ Bayelsa wa niwaju ile aarẹ Ana, Goodluck Jonathan

    Akoroyin BBC to wa ni Bayelsa, Karina àti Dan ṣalye pe Goodluck gba awọn eniyan Bayelsa ati Kogi nimọran pe ki wọn gba alaafia laaye.

    O ni abuku awọn ajọ eleto idibo kaakiri agbaye ni ti eto naa ko ba lọ bi wọn ti ṣe kede rẹ ninu irir oun gẹgẹ bii onwoye lagbaye.

    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Goodluck ti de si ibudo idibo lati aago mẹjọ kọja iṣẹju diẹ to yẹ ki idibo naa ti bẹrẹ ṣugbọn ko si nkankan nilẹ lasiko naa.
  10. Èsì tí mò n gbọ́ lórí ìdìbò òní ń tẹ́mi lọ́rùn-Yahaya Bello, Kogi vs Bayelsa: Ajọ INEC n gbiyanju di asiko yii

    Yahaya Bello: Ipinlẹ Kogi gbagbọ ninu INEC

    Mo mọ pe maa jawe olubori- Yahaya Bello

    Àkọlé fídíò, Kogi vs Bayelsa: Ajọ INEC n gbiyanju di asiko yii
  11. Aarẹ àná, Goodluck Ebele Jonathan ti dibo yan gomina to wu u ni Otuoke bayii, Goodluck dibo yan ẹni to fẹ ni Bayelsa

    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Goodluck dibo yan ẹni to fẹ ni Bayelsa
  12. Fónrán fídíò ibí tí Dino tí n pin owó lu síta

    Fonran fidio kan ti o ṣe afihan ibi ti oludije ipo Sẹnẹtọ labẹ asia ẹgbẹ PDP ti n pin owo lọjọ idibo ti lu sita.

    Ile iṣẹ iroyin The Cable lo fi fidio yi si oju opo Twiter wọn

    Sẹnẹtọ Dino Melaye to n du ipo Sẹnẹtọ ninu idibo atundi iwọ oorun Kogi ni fidio naa fihan bi o ti ṣe ko owo fun iya kan ti o n ta nkan ipanu.

    Ko daju boya nibudo idibo rẹ ni o ti pin owo naa ṣugbọn aṣọ to wọ nigba to lọ dibo lọjọ Abamẹta naa ni o wọ ninu fidio naa.

    Ofin idibo Naijiria ko faye gba ki eeyan maa pin owo lọjọ idibo ti ajọ to n mojuto iwa jegudujẹra ni Naijiria EFCC a si maa mu awọn to ba hu iru iwa bẹ.

    Skip X post
    Allow X content?

    This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

    Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

    End of X post

  13. Ìdí tí ètò ìdìbò ìpínlẹ̀ Kogi fi yàtọ̀!, Ipinlẹ Kogi jẹ eyi ti wọn n pe ni Confluence state nitori pe olu ilu rẹ, Lokoja ni odo Benue ati Niger wa papọ

    Lọjọ Kejilelogun, oṣu kọkanla ni ajọ eleto idibo Naijiria, INEC kede esi idibo nini ijọba ibilẹ mọkanlelogun ni Kogi pẹlu ero pe o ṣeeṣe ki iṣẹlẹ ija wa.

    Ọmọọba Abubakar Audu ti APC ni INEC kede 240, 867 fun nigba ti Captain Wada Idris to jẹ gomina tẹlẹ ni PDP ni 199, 514 nipo keji.

    Ogbeni Emmanuel Kucha to jẹ adari eleto idibo lasiko naa fun ipinlẹ Kogi sọ pe idibo naa ko kẹsẹ jari bo ṣe yẹ nitori pe ibo 41, 353 lo wa laarin awọn mejeeji bẹẹ ibo 49, 953 ni wọn wọgile ni eyi to fi jẹ pe ibo ibuso idibo mọkanlelaadọrun un ni wọn ṣi nilo.

    Leyin eyi ni ọgbẹni Kucha kede esi pe APC ni 6, 885 ibo ti apapọ ibo APC fi jẹ 247, 752.

    Nigba ti PDP ni 5, 363 ninu atundi ibo mọ eyi to wa nilẹ to fi jẹ 204, 877 ibo lapapọ.

    Lẹyin iku Abubakar Audu to dupo labẹ APC ni APC fa Yahaya Bello kalẹ ti wọn si kede Yahaya Bello lọjọ kejilelogun, oṣu kọkanla.

    APC ni wọn gbee fun Yahaya Bello tori oun lo ṣe ipo keji Audu laisko idibo abẹlẹ ninu ẹgbẹ APC.

    kogi
    Àkọlé àwòrán, Eyi lo sọ asiko idibo ipinlẹ Kogi di adá tatọ sawọn ipinlẹ guusu ati aarin gbungubn to ku.
  14. Wọn ti ko awọn ohun eelo idibo de si awọn ibudo idibo kan ni Otuoke ni Bayelsa bayii

    Awọn ọṣiṣẹ eleto idibo kọọkan ti ṣetan iṣẹ ni Otuoke

    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Awọn ọṣiṣẹ eleto idibo kọọkan ti ṣetan iṣẹ ni Otuoke
    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Awọn agunbanirọ ṣetan iṣẹ ni Otuoke ki awọn oludibo le ni oore ọfẹ lati yan ẹni to wu wọn sipo
    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Wọn ti ko awọn nkan eelo idibo de wọọdu kẹtala ni Otuoke
    Bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Awọn oṣiṣẹ eleto idibo ti n ko nkan de ibudo idibo ni ẹka kọkandinlogoji ni Otuoke ni ipinlẹ Bayelsa
  15. Aṣoju ẹgbẹ oṣelu SDP miran ni Kogi ni wọn tun ti ṣọṣẹ fun lori

    Ariwo ni oludije Natasha Akpoti ti ẹgbẹ oṣelu SDP n pa pe ọṣẹ yii pọ

    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Ariwo ni oludije Natasha Akpoti ti ẹgbẹ oṣelu SDP n pa pe ọṣẹ yii pọ
  16. Fidio ṣe afihan arakunrin to n ba awọn oludibo tẹka

    Ṣaaju idibo ni awọn ajọ eleto idibo Naijiria ti n fi ikilọ sita lori bo ti ṣe yẹ ki awọn eeyan ṣe ni ibudo idibo.

    Ko ye wa ohun tarakunrin yi n ṣe nibi ti awọn eeyan ti n dibo ni ibudo idibo Gomina Yahaya Bello Kogi lọjọ idibo gangan.

    Boya ẹle lawa lọyẹ.

    Àkọlé fídíò, #KogiDecides2019:Fidio arakunrin kan to n bawọn oludibo tẹka
  17. Eto idibo ko tii bẹrẹ ni awọn agbegbe kan bii Otuoke ni Bayelsa, Awọn eniyan n jade lati lọ si ibudo idibo wọn ni Otuoke

    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Awọn eniyan n jade lati lọ si ibudo idibo wọn ni Otuoke
    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Awọn oludibo n duro ni Otuoke ki wọn le dibo yan ẹni ti ọkan wọn fẹ
    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Awọn eleto idibo ni RAC ṣẹṣẹ yanju awọn ohun eelo idibo wọn tan bayii ki idibo le bẹrẹ
    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Awọn oludibo ti n duro ni Imiringi ni ijọba ibilẹ Ogbia ni Bayelsa ki wọn le dibo.
    bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Onikaluku lo yọ kaadi idibo rẹ dani ti wọn ti ṣetan lati dibo
    Bayelsa
    Àkọlé àwòrán, Awọn oṣiṣẹ eleto idibo ti ṣetan ni wọọdu kẹjọ, ẹka karun un ni Imiringi ni ijọba ibilẹ Ogbia
  18. Wọn ṣegi iya fawọn aṣoju SDP ni ibudo idibo Natasha Akpoti, Natasha Akpoti ko ribi tẹka sinu idibo

    Iduro ko si ibẹrẹ ko si fun Natasha Akpoti to jẹ oludije ẹgbẹ oṣelu SDP pẹlu bi ko ti ṣe raaye jade lati lọ dibo ni ibudo idibo rẹ.

    Akọroyin wa to wa ninu ile pẹlu rẹ Dooshima Abu jabọ pe Natasha ni ọkan oun ko balẹ nitori pe awọ́n kan ti ṣegi iya fawọn aṣoju ẹgbẹ rẹ ni ibudo idibo oun.

    Kogi Election
    Kogi Election
    Àkọlé àwòrán, Natasha Akpoti
  19. Wada ẹgbẹ PDP naa ti tẹka ni Kogi

    Oludije ipo Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP Musa Wada ti tẹka ninu idibo Gomina to n lọ lọwọ nipinlẹ Kogi.

    Loju opo Twitter ẹgbẹ PDP ni aworan ibi to ti tẹka wa.

    Skip X post
    Allow X content?

    This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

    Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

    End of X post

  20. Dino Melaye,Natasha Akpoti ko ti dibo

    Ṣẹnẹtọ Dino Melaye ti ẹgbẹ oṣelu PDP to n du ipo Sẹnẹto ninu idibo atundi ẹkun ila oorun ipinlẹ Kogi ko ti dibo lasiko ta n 'ṣe akojọpọ iroyin yi.

    Bakanna la gbọ pe obinrin kan ṣoṣo to n du ipo Gomina Natasha Akpoti ti ẹgbẹ SDP naa ko ti jade kuro ninu ile rẹ lati dibo.

    Iroyin to n tẹwa lọwọ sọ pe niṣe ni ẹru n ba pe ki wọn ma ṣe leṣe ti o ba jade.

    Skip X post
    Allow X content?

    This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

    Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

    End of X post

    Kogi Election

    Oríṣun àwòrán, Gold Rahaman

    Àkọlé àwòrán, Dino Melaye