Wike, Fubara tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn bí Tinubu ṣe padà dá sí aáwọ̀ òṣèlú ìpínlẹ̀ Rivers

Oríṣun àwòrán, Sir Siminalayi Fubara/Facebook
Aawọ oṣelu to n lọ lọwọ nipinlẹ Rivers lo ṣeeṣe ko ti dopin pẹlu bi awọn tọrọ kan ṣe tọwọ bọ iwe adehun alalaafia lalẹ ọjọ Aje.
Eyi lo waye lẹyin ipade ti Aarẹ Bola Tinubu ṣe pẹlu gomina ipinlẹ Rivers, Siminalaye Fubara; igbakeji rẹ, Ngozi Odu; gomina tẹlẹ ri nipinlẹ Rivers, Peter Odili ati gomina ana nipinlẹ naa to tun jẹ minisita fun olu-ilu orilẹede yii, Nyesom Wike, atawọn miran tọrọ naa kan.
Minisita fun olu-ilu orilẹede yii, Wike, tawọn eeyan wi pe o ṣe atilẹyin fun Gomina Fubara atawọn miran lati jawe olubori nipinlẹ Rivers, lo de si ile aarẹ ni ankan bii aago meje aṣalẹ, ti wọn si muu wọ ọfiisi aarẹ nibi ti ipade naa ti waye.
Lara awọn to wa nibi ipade naa ni igbakeji aarẹ, Kashim Shettima, olubadamọran fun aarẹ lori eto abo. Nuhu Ribadu, ati olori oṣiṣẹ lọfiisi aarẹ, Femi Gbajabiamila.
Gẹgẹ bii ohun to wa ninu afẹnukosi wọn lẹyin ipade ọhun lalẹ ọjọ Aje, aarẹ wi pe ki Fubara atawọn alatilẹyin rẹ o yọwọ ninu gbogbo ẹjo ti wọn pe sileẹjọ lori gbogbo rogbodiyan naa.
Awọn ti wọn fọwọ si afẹnukosi naa ni Fubara, igbakeji rẹ, Wike, Ribadu, adari igun kan nile aṣofin ipinlẹ Rivers, Martin Amaewhule; alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Rivers, Aaron Chukwuemeka ati ojugba rẹ lẹgbẹ APC, Tony Okocha.
Lara ohun to wa ninu afẹnukosi naa ni pe ki Fubara o pada gbe abadofin eto iṣuna ipinlẹ naa kalẹ niwaju ile aṣofin ni kikun.
Bakan naa ni awọn ọmọ ile aṣofin ipinlẹ naa ko gbọdọ gbe igbesẹ kọkan lori yiyọ Fubara nipo.
Kini awọn koko to wa ninu afẹnukosi naa?
Awọn koko mẹjọ ti wọn fẹnu ko si ni pe:
- Gbogbo ẹjọ ti gomina ipinlẹ Rivers, Sir Fubara, atwọn eeyan rẹ pe sile ẹjọ nipa rogbodiyan oṣelu nipinlẹ Rivers ni ki wọn yọwọ nibẹ lẹsẹkẹsẹ.
- Gbogbo igbesẹ iyọnipo tile aṣofin ipinlẹ Rivers gbe tako Gomina Fubara ni ki wọn pinwọ rẹ lẹsẹkẹsẹ.
- Idari ile aṣofin ipinlẹ Rivers labẹ Abẹnugan Martin Amaewhule atawọn aṣofin mẹtadinlọgbọn to kuro lẹgbẹ PDP ni ki wọn damọ.
- Awọn ajẹmọnu ati ẹtọ awọn aṣofin naa atawọn amugbalẹgbẹ wọn ni ki ijọba o san ni kia, ki gomina o si yọwọ ninu eto iṣuna ati inawo ile aṣofin ipinlẹ naa.
- Ile aṣofin ipinlẹ Rivers ni yoo yan ibi ti wọn yoo ti maa jokoo lati ṣofin, ti igbimọ iṣejọba ko si nii da sii.
- Gomina Fubara ni yoo tun aba eto isuna gbe kalẹ niwaju ile aṣofin ipinlẹ naa ni kikun.
- Orukọ gbogbo awọn kọmiṣona to kọwe fiposilẹ nitori wahala oṣelu yii ni gomina yoo pada fi ṣọwọ sile aṣofin ti wọn yoo si pada sipo wọn.
- Ko gbọdọ si alaga fidihẹ lawọn ijọba ibilẹ nipinlẹ Rivers. Bi gomina ṣe fọwọ osi juwe ile fun awọn alaga ni ko tọna to si otubantẹ.



























