NÍ YÀJÓYÀJÓ, Àkójọpọ̀ ìròyìn bó ṣe ń lọ nínú ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti

Ìròyìn àtìgbàdégbà nípa ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

  1. Etò òdìbò ti gbérasọ káàkiri ìpínlẹ̀ Ekiti

    Iya to wọ aṣọ olomi aro n tẹka

    Eto idibo ti bẹrẹ ni ipinlẹ Ekiti lati yan ẹni ti yoo di ipo gomina mu ni ipinlẹ naa fun saa ọlọdun mẹrin miran.

    Kaakiri awọn ibudo idibo ti ikọ BBC News Yorùbá kan si lawon ilu bii Ado Ekiti, Ilawẹ, Ikọgosi ati bẹẹ bẹẹ lọ lawọn oludibo ti jade lasiko lati dibo wọn.

    Ni ibudo idibo to wa ni ileẹko alakọbẹrẹ Odo Primary school ni wọọdu kẹwaa ni ileto Odo ni Ado Ekiti awọn oludibo kọminu lori bi awọn ẹrọ aṣayẹwo kaadi idibo BVAS ṣe n pẹ ko to ṣiṣẹ.

    Wọn rọ awọn alaṣẹ INEC lati wa nnkan ṣe si eyi ki idibo naa le lọ nirọwọrọsẹ.

    Ọkunrin to fẹ fi iwe idibo sinu apoti ibo
    Awọn eeyan to n wo orukọ wọn
    Awọn eeyan to n wo orukọ wọn

    Ni unit7, ward 10 Okesa, nilu Ado Ekiti, eto iforukọsilẹ awọn oludibo ti gberaso.

    Awọn oṣiṣẹ agbofinro, oṣiṣẹ ajọ eleto idibo INEC, awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu pẹlu awọn oludibo tiwa nibi, bẹẹ ni nkan si n lọ ni mẹlọ mẹlọ.

    Ayafi bo se soro fawọn oludibo agbalagba kọọkan lati ṣawari orukọ wọn wo loju iwe tiwọn lẹ mọ ara ogiri.

    Awọn agbalagba ni wọn kọkọ da lohun lati tẹ ika

    Kehinde Boboye ati Grace Oguntinoye sọrọ wọn ni inu awọn dun lati jade wa dibo ṣugbọn wọn ko raaye se eto iforukọsilẹ oludibo.

  2. Ọlọ́pàá àtàwọn ọ̀dọ́ wọ̀yá ìjà, èèyàn kan kú àwọn ọ̀dọ́ dána sun àgọ́ ọlọ́pàá

    Ọkunrin kan wa niwaju agọ ọlọpaa to n jo

    Oríṣun àwòrán, Isaac Fayose/Facebook

    Niṣe ni ọrọ di bo o lọ yago fun mi ni ilu Isan Ekiti ni ìjọba ibilẹ Oye nipinlẹ Ekiti nigba ti wahala bẹ silẹ laaarin awọn ọlọpaa atawọn ọdọ ilu naa ti eeyan kan padanu ẹmi rẹ.

    Gẹgẹ bi ohun ti a ri gbọ aṣalẹ ọjọ Ẹti, ọjọ Kọkandinlogun, oṣu Kẹfa, ti eto idibo sipo gomina ipinlẹ Ekiti ku aarọ ni laasigbo naa waye.

    Ohun ta a rí gbọ ni pe ọlọpaa kan yinbon pa eeyan kan, ti eyi si mu kawọn ọdọ ilu naa yawọ ọfiisi ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Isan Ekiti, ti wọn si dana sun-un.

    Bakan naa, fọnran tí a rí lori ayelujara eyi ti aburo gomina tẹlẹri nipinlẹ Ekiti gbe síta safihan asiko ti awọn ọdọ naa yawọ ileeṣẹ ọlọpaa pẹlu ariwo pe awọn ko fẹ ọlọpaa mọ ni ilu naa.

    Ikọ BBC News Yoruba kan si ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ekiti lati fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ni iroyin naa ko tii de ọdọ wọn.

    Akitiyan si n lọ lọwọ lati ba ileeṣẹ ọlọpaa sọrọ lori iṣẹlẹ naa.

  3. Ẹ kú ojúmọ́

    A ku ojumọ!

    BBC News Yoruba ti wa ni ipinlẹ Ekiti nibi ti eto idibo sipo gomina ipinlẹ naa ti n waye lonii.

    Ẹ maa bawa bọ bi a o ṣe maa mu awọn iroyin nipa ohun to n ṣẹlẹ ni ipinlẹ naa wa fun-un yin.