Mọ̀lẹ́bí Kola Oyewo kéde bí ètò ìsìnkú rẹ̀ yóò ṣe wáyé

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Awọn mọlẹbi agba oṣere tiata Yoruba to di oloogbe, Oloye Kola Oyewo, ti kede bi eto isinkun rẹ yoo ṣe lọ.

Ninu atẹjade kan ti mọlẹbi naa fi sita ni wọn ti kede pe ilu Ile Ife ati Oba-Ile ni wọn yoo ti ṣeto isinku naa.

Aarin ọjọ karun un si ọjọ keje, oṣu Kejọ, ọdun 2026 yii ni eto isinku naa yoo waye.

Bi eto isinku Kola Oyewo yoo ṣe waye

Ọjọ karun un oṣu Kẹjọ

Lọjọ karun un oṣu Kẹjọ ni eto orin aṣalẹ onigbagbọ yoo waye nile ijọsin St Mary's Catholic Church, Igboya, Ile-Ife laarin aago marun un irọlẹ si aago meje alẹ.

Ọjọ kẹfa oṣu Kẹjọ

Lọjọ kẹfa oṣu Kẹjọ ni wọn yoo ṣeto isin ninu ijọ St Mary's Catholic Church, Igboya, Ile-Ife kan naa laarin aago mẹwaa aarọ si aago mejila ọsan.

Lọjọ kan naa ni awọn oṣere yoo ṣe ẹyẹ iranti fun ni gbagede Oduduwa Hall to wa ninu ọgba fasiti OAU ni Ile Ife laarin aago mẹta ọsan titi di aago mẹjọ alẹ.

Afihan awọn iṣẹ Kola Oyewo yoo waye laarin aago kan ọsan titi di aago mẹrin irọlẹ ọjọ keji to jẹ ọjọ keje, oṣu Kẹjọ yii kan naa ni gbagede Pit Theatre, African Studies Building, Ile Ife.

Ọjọ Keje oṣu Kẹjọ

Ọjọ Ẹti yii ni ọpọ ọkọ ayọkẹlẹ yoo tẹle ara wọn lọ siluu Oba-Ile pẹlu oku oloogbe laago meje aarọ.

Wọn yoo tẹ oku si gbagede ile Ese Ila bẹrẹ lati aago mẹwaa ku iṣẹju mẹẹdogun aarọ.

Eto isin yoo waye ninu ijọ St Joseph Catholic Church, Oba-Ile laago mọkanla aarọ.

To ba di aago kan ọsan ku iṣẹju mẹẹdogun, wọn yoo sin oku rẹ ni Labaluyegbe Villa, Oba-Ile.

Wọn ni awọn mọlẹbi atawọn to sunmọ oloogbe nikan ṣoṣo ni wọn yoo wa nibi iboji naa.

Lẹyin eyii ni wẹjẹwẹmu yoo waye ni gbagede Aderonmu Grammar School, Oba-Ile lati aago kan ọsan.

Taa ni Kola Oyewo

Alẹ ọjọ Ẹti, ọjọ kejila, oṣu Karun un, ọdun 2026 yii ni awọn oṣere mii, Kunle Afod ati Yomi Ọlọrunlaiye kede iku rẹ.

Ọjọ́ kẹtadinlọgbọn oṣù kẹta ọdún 1946 ni olóògbé Kola Oyewo dele aye.

Ìlú Oba Ile nipinlẹ Osun ni wọn bi i si, to si bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ère tíátà pẹlu ẹgbẹ́ òṣèré Oyin Adejobi.

Kola Oyewo ṣe ere tíátà fún bíi ọgọ́ta ọdún, lára ere to tí kopa ni Sango, Koseegbe àti Super Story.

Bákan náà, olùkọ́ àgbà ní olóògbé Oyewo, to si gbà oye ọmọwe nìdí ere sise ni fásitì Ibadan.

Fásítì Obafemi Awolowo ni olóògbé náà tí ṣiṣẹ olùkọ́ni, ó si tún ṣiṣẹ ni Fásítì Redeemer áti Elizade.