You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
'Mo ti ṣe ìlànà ètò ìsìnkú mi sílẹ̀' : ìtàn Obìnrin tó gbé pẹ̀lú kòkòrò àrùn HIV fún ọgbọ̀n ọdún
- Author, Beldeen Waliaula
- Reporting from, Nairobi
- Published
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3
O ti le ni ọgbọn ọdun ti Margaret Lavonga, to jẹ ẹni ọdun marunlelaadọta ti n gbe pẹlu arun HIV.
Lọdun naa lọhun, awọn eeyan maa n ṣe idẹyẹsi awọn to ni arun HIV.
O ni "Lọdun naa lọhun, o jẹ asiko ti a maa n ri aworan awọn oku eeyan nibi gbogbo, pẹlu ori nla ati egungun.
"Nigba ti wọn sọ fun mi pe mo ni arun naa, mo ro pe ọjọ keji ni mo maa ku."
Lasiko ti ayẹwo fi han pe Margaret ni HIV, ko tii si awọn oogun rẹ ni Kenya, eyii to mu ko pa ẹnu mọ nipa ipo to wa titi to fi bi ọmọ lọdun 1999, amọ o ṣeni laanu pe ọmọkunrin naa dagbere faye lẹyin oṣu meji."
"O ṣoro fun mi lati bi ọmọ nile iwosan lasiko naa nitori niṣe lawọn eeyan bẹrẹ si n yẹra fun mi.
Lẹyin eyii ni ilera rẹ bẹrẹ si n dẹnukọlẹ, fun nnkan bii ọdun meji lo fi wa lori akete aisan.
Fun ọpọ igba lo fi n dero ile iwosan ko to janfani oogun awọn to ni arun HIV.
Ọdun 1984 ni wọn kọkọ ṣawari ẹni akọkọ to ni arun HIV lorilẹede naa, fun ọpọ awọn to ni arun naa nibẹ lọdun naa lọhun, ọjọ ori wọn n kuru.
Amọ fun Margartet, lati ọdun 1999 to ti ni arun ọhun, o ṣi wa laaye.
O ni awọn oogun to n gbogun ti arun naa, antiretroviral drugs (ARVs) ti wọn n ṣe lode oni ni anfani ju ti atijọ lọ nitori kii fi bẹẹ pa awọn to n lo o lara.
Nigba to n ṣalaye irinajo rẹ, o ni oun ro pe idajọ iku ti de ni. O padanu iwọn kilo mẹrinlelọgbọn, nigba ti awọn obi rẹ gbọ pe o ti ni arun kogboogun, wọn bẹrẹ si n murasilẹ fun eto isinku rẹ.
Lasiko kan, o kọ lati maa lo oogun rẹ lẹyin to ni oun ti gba iwosan, amọ lẹyin ti ilera rẹ bẹrẹ si n kuna pada lo bẹrẹ oogun naa.
Sẹẹli funfun inu ẹjẹ eeyan ni HIV maa n dojukọ to si maa n mu irẹwẹsi ba ohun elo to n daabo bo agọ ara.
Eyii maa n mu ko rọrun fun awọn to ba ni HIV lati ni awọn arun mii bii ikọ efee, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Wayi o, ko rọrun lati gbe ati lati dọjọ ogbo pẹlu arun HIV.
Margaret sọ pe bo tilẹ jẹ pe oun ti ni igboya lati sọrọ lori arun naa bayii, ọpọ igba loun maa n ti ilẹkun mọri ti oun a si maa wa ẹkun mu ninu ile.
Iṣoro to n koju lọwọ yii ni awọn aisan to maa n kọlu ẹda ti ọjọ ogbo ba ti n de, toun ti arun HIV to wa lara rẹ tẹlẹ.
O ni oniruru aisan bii mẹrin lo n ba oun nikan ṣoṣo finra bayii o si ni ko rọrun lati maa loogun oun lojojumọ gẹgẹ bii ẹni to n gbe pelu HIV.
Obirin naa ti wa rọ awọn to ni arun HIV ki wọn maa lo oogun wọn dede.
O pari ọrọ rẹ pe afojusun oun ni lati pe ni ẹni ọdun 120 loke eepẹ gẹgẹ bii ẹni to ni arun HIV.