Ìjọba Kwara pé Bukola Saraki lẹ́jọ́, wọ́n ló ní Gómìnà Abdulraman kò kàwé délé ẹ̀kọ́ girama

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ijọba ipinlẹ Kwara, labẹ akoso Gomina AbdulRahman AbdulRazak, ti pe gomina tẹlẹ nipinlẹ naa, Sẹnetọ Bukola Saraki, lẹjọ lori ẹsun ibanilorukọjẹ.

Ile ẹjọ giga ipinlẹ Kwara ni ijọba pe ẹjọ ọhun si.

Ẹsun ti ijọba Kwara fi kan Sẹnetọ Saraki ni pe wọn ni o sọ pe Gomina AbdulRahman ko kawe de ile ẹkọ girama.

Nibo ni wọn ni Saraki ti sọrọ naa?

Gẹgẹ bi ijọba Kwara ṣe ṣalaye, Saraki sọrọ naa ni nnkan bii ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹrin ọdun 2026, lori ẹka ayelujara ati awọn iwe iroyin.

Wọn tẹsiwaju pe awọn ọrọ naa kun fun eebu, abuku ati ede alufanṣaa.

"Pe Gomina AbdulRazaq ko kawe de ile ẹkọ girama, eyi ti o mọ pe ko ri bẹẹ, ṣugbọn o mọ-ọn-mọ gbe ọrọ naa jade, o si sọ ọ lọna ati tabuku Gomina ipinlẹ Kwara; Mallam AbdulRahman AbdulRazaq ati ijọba ipinlẹ Kwara.

" O ṣe eyi lọna to le da omi alaafia ilu ru, o si ṣe bẹẹ lufin ẹṣẹ to ni ijiya ninu labala 399 ofin ipinlẹ Kwara ti ọdun 2006."

Bẹẹ ni apa kan iwe ipẹjọ naa ka.

Adajọ sọrọ

Ninu ọrọ rẹ l'Ọjọbọ ti igbẹjọ waye, Agbẹjọro fun Saraki, Jimoh Mumeen (SAN),sọ fun kootu pe ki i ṣe ile ẹjọ giga lo yẹ ki igbẹjọ naa ti waye, ati pe ọna ti wọn gbe e gba ko tọna.

Mumeen ti T A Ahmed, ṣoju fun, rọ kootu lati ma ṣe gbọ ẹjọ naa.

Amọ Rafiu Balogun, agbẹjọrọ fun olupẹjọ, rọ kootu lati ma ṣe gba eyi wọle.

O ni agabangebe ni bi olujẹjọ ṣe n beere iru eyi.

Ninu idajọ rẹ, Adajọ M.O. Folorunsho, sọ pe ohun meje ti lọya olujẹjọ n beere ko le ri bẹẹ.

O ni kootu oun ni aṣẹ lati gbọ ẹjọ naa, oun yoo si gbọ o.

Adajọ sọ pe ẹsun ibanilorukọjẹ lo wa niwaju Sẹnetọ Bukola Saraki, yoo si jẹ ẹ.

O sun igbẹjọ si ọjọ kejilelologun, oṣu Keje ọdun 2026 yii.

Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?

Tẹ o ba gbagbe, ọrọ to de kootu yii bẹrẹ latari atẹjade kan to gba ori ayelujara kan lọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii lati ọwọ Sẹnetọ Bukola Saraki.

Atẹjade naa jẹ esi si eyi ti ijọba ipinlẹ Kwara ti kọkọ fi sita, eyi ti Saraki sọ pe wọn fi ta abuku oun.

Atẹjade ti Saraki fi sita yii ni ijọba Kwara ti wa sọ pe o kun fun ibanilorukọjẹ ati idunkooko mọni lori ayelujara.

Wọn ni Gomina Abdulrahman Abdulrazaq lo fi bu, to si fa a ti wọn fi pe olori ile igbimọ aṣofin tẹlẹ ni Naijiria naa lẹjọ wayi.