You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Peter Obi ti borí ètò ìdìbò Ààrẹ- Kenneth Okonkwo
- Author, Akinlabi Afolabi
- Role, Broadcast Journalist
- Published
Ọkan lara awọn agbẹnusọ fun ìpolongo ẹgbẹ oselu Labour Party. Kenneth Okonkwo ti ogun rẹ gbari pe oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu Labour Party, ti bori eto ìdibo aarẹ lọdun 2023.
Okonkwo, ẹni to jẹ gbajugbaja onitiata sísọ loju ọrọ naa nigba to kopa ninu ifọrọwerọ kan lori Channels TV.
Gẹgẹ bii o ṣe sọ, o ni Gomina ana ni Ipinlẹ Anambra ti le waju awọn oludije yoku saaju eto ìdibo aarẹ.
"Ani o ti bori, ẹ lọ wo iwadi ti a ti ṣe tí mo sọ fun yin, ẹ wo bi awọn eeyan ṣe dibo; esi ìdibo mẹta ti jade, ANAP, We-Together ati Bloomberg; to si bori ninu gbogbo wọn.
"Laipẹ, ki ìdibo to waye, awọn oludije meji yoo sisẹ pẹlu wa, ti yoo wa ku Peter Obi ati awọn yoku.
"Nitori to ba di asiko idibo, awọn oludije yii koni ni anfani lati ri ida marun un ibo, ti wọn ko ba ti rí ida marun-un, a le pe wọn ni awọn yooku."
Obi kó mú òṣèlú mọ ẹlẹ́yàmẹ̀yà bíi tàwọn yòókù
Okonkwo, ẹni to tun jẹ Agbẹjọro tẹsiwaju pe yatọ si awọn oludije miiran, Peter Obi kọ lati mu oselu mo ẹlẹyamẹya.
O ni pupọ lara awọn oludije yoku lo kaakiri pẹlu oṣelu ẹlẹyamẹya sugbọn Obi da yatọ, to si n wa isọkan ati ilọsiwaju Orilẹede Naijiria.
"Atiku lọ ilẹ Hausa, o ni ki wọn dibo yan ẹni to wa lati ilẹ Hausa, kí wọn si jina si awọn ẹya yooku. Àpẹẹrẹ dida ẹya si nìyẹn.
"Tinubu lọ ipinlẹ Ogun, o sọ asiko Yoruba lokan ati oun lo kan.
"Peter Obi lọ si ilẹ Igbo, o ni ki wọn ma dibo yan oun nitori oun jẹ igbo sugbọn nitori oun jẹ akikanju ọkùnrin ti isẹ ye. O ni ki ṣe asiko ẹnikẹni lati di aarẹ sugbọn o jẹ asiko fun awọn ọmọ orile-ede Naijiria lati yan adari wọn."