FEC:Báyìí ní ìpàdé ìdágbére ìgbìmọ̀ aláṣẹ Nàìjíríà lábẹ ìjọba Buhari ṣe lọ

Aarẹ Naijiria Muhammadu Buhari dari ijoko ipade idagbere igbimọ alaṣẹ Naijiria lỌjọru.
Ni iyara ipade to wa ni ile ijọba Aso Rock lo ti waye.
Ninu awọn to peju sibi ipade idagbere yi ni Igbakeji aarẹ ati awọn Minisita mẹrinlelogoji Naijiria.
Ni nkan bi ago mejila ọsan si ni ipade yi gbera sọ.
Lasiko ipade yi, wọn sọrọ lori irinajo Naijiria labẹ ijọba yi .
Lọjọ Kọkandinlọgbọon Oṣu Kaarun ọdun 2015 ni Aarẹ Muhammadu Buhari bẹrẹ saa rẹ akọkọ to si ṣe ileri lati bori agbesunmọmi Boko Haram,doju ija kọ iwa ajẹbanu ati mimu adinku ba iṣẹ ati oṣi ni Naijiria.
Awọn nkan ti yoo ṣẹlẹ lẹyin ipade idagbere yii
Bẹrẹ lati Ọjọru, gbogbo awọn Minisita labẹ ijọba Buhari ni wọn gbọdọ gbe akoso idari ileeṣẹ wọn fun akọwe agba wọn.
Nibi ipade ti wọn ṣe lỌjọru yi, igbimọ buwọlu awọn ijiroro ipade mẹta ti wọn ṣe sẹyin.
Lẹyin igba naa aarẹ burawọle sipo fawọn kọmiṣana meje tuntun labẹ ajọ ton risi bi ijọba ṣe n ṣeto owo to n wọle si akoto iyẹnRevenue, Mobilization, Allocation and Fiscal Commission (RMAFC).
Bakan naa ni Igbakeji Aarẹ Yemi Osinbajo gbe abajade igbimọ itẹsiwajueto ilera ni Naijiria le aarẹ Buhari lọwọ.
Haruna Tangaza akọroyin BBC to wa nibi ipade yi sọ pe tẹrin tọyaya ni ipade yi fi waye.
Iroyin to tẹwa lọwọ sọ pe pupọ awọn Minisita lo ti n ko ẹru wọn kuro lawọn ọfisi wọn ti wọn siti n gbe akoso le awọn to yẹ lọwọ.



























