Àwọn ọ̀dọ́ ṣekúpa ‘Navy’ ní ìpínlẹ̀ Ondo, làwọn ológun bá ya wọ ìlú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn ọmọ-ogun ori omi ti ya bo ilu Idoani, nijọba ibilẹ Ose, nipinlẹ Ondo latari bi awọn janduku kan ṣe ṣekupa ọkan lara awọn ologun naa.
Iroyin to tẹ BBC News Yoruba lọwọ ni awọn ologun naa ya wọ ilu ọhun lati fi panpẹ ọba mu awọn to lọwọ ninu iṣekupani naa.
Eyi lo fa inu fuu aya fuu, leyi to mu ki ọpọ awọn ọlọja o gbe ibutaja wọn ti lati wa ibi ti wọn yoo fara pamọ si.
Ọpọ ọdọ ninu ilu naa ni wọn ti sa kuro nibẹ bi wọn ṣe ni awọn ologun naa ṣeleri lati gbẹsan iku akẹgbẹ wọn to padanu ẹmi rẹ ninu ilu ọhun.
Bi wahala naa ṣe bẹrẹ
Ọkan lara awọn olugbe ilu Idoani ti ọrọ naa ṣoju rẹ ni “ọmọ ologun ‘navy’ naa fi ọkọ rẹ ta omi si okunrin kan lara lori ọkada nibi to ti n gbiyanju lati ya fun koto”.
“Oloogbe ọun sọkalẹ ninu ọkọ rẹ lati bẹ ọlọkada ọhun ati ero rẹ amọ wọn ko feti si ẹbẹ ọkunrin naa.”
“Ọlọkada naa ti wọn pe orukọ ni Ayo, to si ni ọpọ janduku to n wari fun-un kesi awọn alatilẹyin rẹ lati waa fi iya jẹ ọmọ ologun naa.”
“Awọn janduku ọhun ya bo ologun naa ti ọkan ninu wọn si la irin mọọ lori leyi to mu ko wo lulẹ.”
Ọmọ ologun naa ni wọn wi pe wọn gbe digbadigba lọ ile iwosan ijọba to wa ni ilu naa amọ to ti dakẹ ki wọn too gbe debẹ.
Ọlọkada naa ni a gbọ pe wọn fa le awọn ọlọpaa lọwọ amọ ẹni to la irin mọ oloogbe lori lo fi ẹsẹ fẹẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami-Omisanya, to fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC News Yoruba wipe “ọkunrin kan to n jẹ Sunday Olaoluwa ni agbegbe Iyayu nilu Idoani lo fi ẹjọ sun awọn ọlọpaa pe ọrẹ ohun kan, M. Akingbohun to jẹ ‘Navy’ to wa pẹlu ile ẹkọ girama awọn ‘Navy’ nilu Imeri ni awọn mẹfa kan ti ‘Oyibo’ dari wọn ṣe akọlu si lẹyin ariyanjiyan to waye laarin wọn.”
“Ọkan lara awọn to ṣe akọlu sii naa la irin mọọ lori leyi to ṣe ipalara to pọ fun-un.”
“Awọn dokita fi idi rẹ mulẹ nile iwosan pe ọkunrin naa ti jade laye nigba ti wọn gbe debẹ.
“A ṣi n wa awọn afunrasi to lọwọ ninu iku ologun ọun.”
Ẹwẹ, alaga ijọba ibilẹ Ose, Dennis Adekunle, ti bu ẹnu atẹ lu iṣekupani naa to si juwe rẹ bii ohun to buru pupọ.
Adekunle, ninu atẹjade kan to buwọlu funra rẹ rọ awọn ‘Navy’ lati ṣe pẹlẹ nipa wiwa awọn to lọwọ ninu iṣekupani ọkan lara wọin ko ma baa di yanpọnyanrin.
Alaga kansu naa ran awọn ọmọ-ogun naa leti ajọṣepọ to dan mọran to ti wa laarin wọn ati awọn araalu agbegbe naa lati ọjọ ti wọn da ile ẹkọ naa silẹ di akoko yii.
Adekunle wi pe: “mo fi da awọn adari ile ẹkọ naa loju pe ijọba ibilẹ wa ati gbogbo araalu yoo ṣe atilẹyij to jọju fun wọn lati pinwọ laasigbo ni agbegbe naa”.
























