Afunrasí ọ̀daràn gé orí ọmọ ọdún kan àbọ̀ l'Ondo, bàbà ọmọ faraya

Oríṣun àwòrán, NP ONDO STATE
Inu idarudapo ati iyọnu nla ni awọn olugbe ilu Idanre wa bi afunrasi ọdaran kan ṣe ge ori ọmọ oṣu mejidinlogun nibẹ.
Lasiko iṣẹlẹ naa, awọn olugbe agbegbe ọhun ri wipe wọn ti ge ori ọmọ naa lọ, lai mọ ẹni to sọsẹ ọhun.
Baba ọmọdebinrin naa, ọgbẹni Bright Kalu sọ pe iṣẹlẹ yi waye ni aba oko Agọti niluu Idanre lọjọ Aje, ọjọ karundinlogun, oṣu Kẹfa 2026 ọdun yi.
Ọgbẹni Kalu ẹni to faraya to si banujẹ gidigidi lori ọrọ naa wa pe fun idajọ to yẹ fun ẹni to ge ori ọmọ rẹ ti ko ti pe ọdun meji loke eepẹ.
Bi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé
Baba ọmọ naa ẹni to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Abia ṣalaye pe ohun fi ọmọ naa silẹ pẹlu iya rẹ sinu aba, ti ohun si n ṣiṣẹ ni oko aba miran to jina diẹ si aba ti ọmọ ati iya wa.
Ọgbẹni Kalu sọ pe ni kete ti oun pada de aba ti ọmọ ati iya rẹ wa, oun ba iya ọmọ naa to n sun ẹkun to si sọ fun oun pe ẹnikan ṣe akọlu si awọn, ti oun si gbiyanju lati doola ẹmi awọn mẹta ninu ọmọ wọn, ṣugbọn afunrasi naa gbe ọkan lọ ninu awọn naa.
Baba ọmọ ọhun ṣalaye siwaju si pe bi iyawo oun ṣe ṣalaye ọrọ tan loun kesi egbọn oun, Ifeanyi Kalu, ti wọn si wa gbogbo ayika aba naa lati ṣawari ọmọ naa.
O ni iyalẹnu nla lo jẹ pe lẹyin ọpọlọpọ akitiyan, ẹya ara ọmọ naa ni wọn ri, ti wọn si ti ge ori rẹ lọ.
Kalu wa rawọ ẹbẹ si ijọba lati fi ẹni to ṣọsẹ yi jofin.
O si fi idi rẹ mulẹ pe wọn ti fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ ọlọpaa Olofin to wa niluu Idanre leti, ti wọn si ti gbe ọrọ naa lọ olu ileeṣẹ ọlọpaa niluu Akure fun iwadii lori ọrọ naa.
Kí ni Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà?
Lasiko ti BBC kan si ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo lori iṣẹlẹ naa, alukoro ileeṣẹ ọhun DSP Abayomi Jimoh fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Alukoro ṣalaye pe, ọrọ naa jẹ ohun to ba ni ninu jẹ pe eniyan ge ori ọmọ kékeré lai ni imọlara kankan.
Jimoh sọ pe ọwọ ṣinku ọlọpaa ti tẹ afunrasi ọdaran to ṣọsẹ naa.
O sọ pe kete ti wọn ba pari iwadii wọn, awọn yoo gbe afunrasi naa lọ ile ẹjọ fun idajọ to yẹ.


























