Wo ewu tó wà nínú kí nǹkan ọmọkùnrin rẹ nàró ju ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lọ

Ọkunrin kan din ṣokoto rẹ mu

Oríṣun àwòrán, others

Published

Ọjọgbọn imọ nipa iṣẹ abẹ kan ni fasilti ilu Ilọrin, Ademọla Popoọla ti ṣekilọ pe o lewu ki nnkan ọmọkunrin o ṣi duro lẹyin ọgbọn iṣẹju lẹyin ibalopọ.

Ọjọgbọn Popoọla ṣekilọ lasiko to fi n gbe idanilẹkọ idasilẹ fasiti naa, aladọta o le igba iruẹ (250th Inaugural lecture) kalẹ eyi to pe akọle rẹ ni, “Ki gbogbo eeyan le ma tọ pẹlu alaafia.”

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, “Bi nnkan ọmọkunrin eeyan ba ti n le ju ọgbọn iṣẹju lọ, ki ẹni bẹẹ tete yara kọri si ile iwosan ni.”

Ọjọgbọn naa ni dokita to kọṣẹmọṣẹ gbọdọ tete dẹkun diduro tangi nnkan ọmọkunrin bẹẹ.

Akọṣẹmọṣẹ imọ nipa iṣẹ abẹ naa to woye pe lootọ lo dara ki nnkan ọmọkunrin maa duro nitori ibalopọ to dara, sibẹ bi nnkan ọmọkunrin ba le laleju o le kan tabi ko fa ipalara.

Ọjọgbọn Popoọla ni, “Iwadii fihan pe apa ọtun nnkan ọmọkunrin a maa tete kan ju apa osi rẹ lọ.”

O fi kun un pe itọ titọ le wa di iṣoro fun iru ọkunrin bẹẹ eyi si tun le pada ja si iku.