Akẹ́kọ̀ọ́ tí wọn gbà fóònù rẹ̀ bínú dáná sún ilé-ẹ̀kọ́ èèyàn 19 pàdánù ẹ̀mí wọn

Aworan ile to jona

Oríṣun àwòrán, Guyana Presidency

Published

Ijamba ina kan to ṣẹlẹ ni aaye ibugbe awọn akẹkọọ ni Guyana lo da bi ẹni pe akẹkọọ kan to n fapa janu pe wọn gba foonu lọwọ rẹ lo wa nidi rẹ.

Eeyan mọkandinlogun pupọ ninu wọn obinrin lo padanu ẹmi wọn ninu ijamba ina yi lowurọ kutu ọjọ Aje.

A gbọ pe wọn ti ilẹkun aaye ibusun awọn akẹkọọ yi ti ọpọ ferese rẹ si wa ni pipade.

Eleyi lo mu ki awọn to farapa ma ṣe ribi sa jade.

Ọdọbinrin yi wa ni ile iwosan fun itọju ina to jo ara rẹ to si ti jẹwọ pe lootọ loun dana sun ile ibugbe akẹkọọ yi.

Awọn alaṣẹ n gbero bayii boya ki wọn fẹsun kan an gẹgẹ bi ọkan lara awọn oṣiṣẹ ijọba ṣe sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP.

Agbegbe ile iwẹ ni ina yi ti ṣẹyọ to si ran kaakiri gbogbo ile naa ti wọn fi pako kọ.

Akẹkọọ mẹtadinlọgbọn lo wa ninu ile yi lasiko ijamba ina ọhun.

Awọn to moribọ ninu iṣẹlẹ yi nilu Mahdia to wa laarin gbungbun ilẹ naa sọ pe ṣadede lariwo ati igbe ta awọn ji laarin oru.

Wọn fẹsun kan ọmọdebinrin naa pe o halẹ pe oun yoo dana sun ileẹkọ naa lẹyin ti wọn baa wi pe o yan ọkunrin to dagba ju lọ lọrẹkunrin.

Iroyin fi han pe alamojuto ile ẹkọ naa- ti ọmọ rẹ ọdun marun un padanu ẹmi rẹ ninu ijamba ina yi-ko mọ ibi ti kọkọrọ wa nitori ibẹrubojo to de ba.

Awọn panapana pada fọ ferese wọle ni lati le doola awọn eeyan.

Yatọ si awọn ọmọbinrin to padanu ẹmi wọn yi,ọpọ eeyan lo farapa ninu ijamba naa.

Wọn gbe wọn lọ si ileewosan awọn kan wa ni olu ilu ilẹ naa Georgetown tawọn mii si wa ni ipo to lewu gidi gaan.

Ina to jo awọn to ku lagbara debi pe wọn ni lati lo DNA ki wọn to le da oku onikaluku mọ.

Aarẹ ilẹ naa Irfaan Ali ṣapejuwe ijamba ina yi gẹgẹ bi ewu to lagbara gidi gaan.

Aworan ile to jona

Oríṣun àwòrán, Getty Images