Gómìnà Abdulrasaq, Emir Ilorin kẹ́dùn ìpapòdà Oloro ìlú Oro, Ọba Oyelaran tó wàjà

Oríṣun àwòrán, Others
Ẹmọ ku oju opo di, afiribojo ku ẹnu isa n ṣọfọ, Oloro ti ilu Oro ni ijọba Ibilẹ Irepodun, ipinlẹ Kwara Ọba AbduRafiu Ọlaniyi Ajiboye Oyelaran kiini ti waja.
Kabiyesi naa to waja lowurọ kutu oni ọjọ Satide ọjọ kẹtalelogun oṣu Keji ọdun 2024.
Atẹjade Alaga afunṣọ ijọba ibilẹ Irepodun, Jide Oyinloye sọ pe kabiesi naa lo fidi rẹ mulẹ pe Ọba Oyelaran ti tẹri gbaṣọ.
Ninu ọrọ ibanikẹdun rẹ, gomina Ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq juwe Ọba alaye naa gẹgẹ bi ẹni to ti kopa manigbagbe ni ilu na ati Ipinlẹ Kwara lapapọ.
Gomina Abdulrasaq ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ, Rafui Ajakaye fi sita ni titi laye ni ara ilu Oro yoo maa ṣe iranti ọba Oyelaran.
Bakan naa ni Emir ilu Ilorin, Alhaji Ibrahim Silu-Gambari lasiko to n kẹdun ipapoda Ọba Oyelaran to darapọ mọ awọn babanla rẹ ni igbe aye to dun-un kọṣe ni ọba naa gbe nigba aye rẹ .
Oloro ti ilu Oro kingdom ọba AbduRafiu Ọlaniyi Ajiboye Oyelaran Kiini waja lẹyin ọdun mejidinlọgọrin (78) loke eepẹ.
Ọba Oyelaran gun ori itẹ awọn Baba rẹ lọjọ Kejilelogun, oṣu keji ọdun 2002.
Lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́ ni ọba náà tẹri gbaṣọ.



























