You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìdí rèé tí mo fi ní kí wọ́n yọ Maryam Shetty nínú orukọ àwọn tó fẹ́ gba ipò mínísítà - Ganduje
Alaga ẹgbẹ oṣelu APC ni Naijiria, Abdullahi Umar Ganduje ti sọ idi ti oun fi gba wọn ni imọran lati yọ orukọ Maryam Shetty kuro ninu awọn ti wọn fi ọrukọ wọn ṣọwọ si wọn.
Umar Ganduje ni awọn ti wọn fi orukọ Maryam sọwọ fun aarẹ lati ipinlẹ Kano ko jẹ ki oun mọ nipa rẹ.
Amọ o ni aarẹ Tinubu ni aṣẹ lati yan ẹnikẹni to ba wu u gẹgẹ bi minisita ti yoo ṣiṣẹ ni abẹ rẹ.
Ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu awọn oniroyin ni opin ọṣẹ ni Ganduje ti ni oun ni adari ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Kano, nitori naa ko yẹ ki wọn gbe nkan gba ẹyin oun.
‘’Ẹni ti yoo di ipo minisita mu gbọdọ ni imọ nipa oṣelu ati iṣejọba’’
Ganduje ni oun ko mọ nkankan nipa Maryam Shetty, oun ko si mọ ọ ni ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Kano.
‘’Nitori naa a ko ni imọ to to nipa rẹ lati sọ boya o lee ṣe iṣẹ naa abi ko lee ṣe.’’
Bakan naa lo ni ohun ti awọn eniyan n sọ lori social media naa tun fikun un igbesẹ ti wọn gbe nipa rẹ.
O ni awọn kan sọ wi pe arabinrin naa klo kunjuwọn lati di ipo minisita mu ni naijiria nitori ko ni imọ kankan nipa eto oṣelu.
Alaga ẹgbẹ oṣelu APC ni awuyewuye yii lo de ọdọ aarẹ Buhari to si mu ki o beere imọran lọwọ ohun nipa rẹ.
Ganduje ni ipo minisita nilo ẹni to ni imọ pipe, to si lee ṣiṣẹ takuntakun ni imọ oṣelu ati iṣejọba.
Orisirisi iroyin lo ti jẹyọ lẹyin ti aarẹ Tinubu yọ orukọ arabinrin naa kuro ninu awọn orukọ awọn minisita to fi ṣọwọn si ile igbimọ aṣofin.