Akeredolu pàṣẹ òfin kónílé ó gbélé ní ìlú Ikare-Akoko nítorí rògbòdìyàn

Oríṣun àwòrán, Others
Gomina ipinlẹ Ondo, Oluwarotimi Akeredolu ti kede ofin konile- o gbele ọlọjọ kan fun gbogbo agbegbe ijọba ibilẹ Ikare-Akoko.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ gomina naa, Richard Olatunde fi lede ni gomina ti salaye igbesẹ naa.
Eyi ko ṣẹyin bi ẹgbẹ ọdọ meji ṣe bẹrẹ si ni ṣekọlu si ara wọn ni ayẹyẹ ibẹrẹ ọdun ni ilu ọhun.
Ko gbọdọ si irinna kankan ni ilu Ikare-Akoko titi ti rogbodiyan yoo fi rọlẹ - Akeredolu
Lasiko ikọlu naa ni awọn eniyan kan ku, ti wọn si dana sun awọn ṣọọbu ati ohun ini awọn eniyan.
‘’Lẹyin ikọlu laarin awọn ọdọ lati bi ọjọ mẹta ṣẹyin nitori awọn to n ṣatilẹyin fun olori meji ni agbegbe ọhun’’
‘’Awọn alatilẹyin Olukare ti Ikare, Oba Akadiri Momoh ati Owa Ale ti Iyometa, Oba Adeleke Adegbite ni wọn n koju ara wọn.’’
Bakan naa ni Gomina ni awọn ẹṣọ alaabo ti wa nikalẹ ni pese, lati ri pe rogbodiyan dopin ni agbegbe naa, ki alaafia le jọba.
Akeredolu tun fikun un pe iwadii ti bẹrẹ ni pese lati mọ ki lo fa ikọlu naa.

























