Wo bí àwọn obìnrin Afghanistan tíjọba Taliban fòfin dè pé wọn ò gbọdọ̀ gbá bọ́ọ̀lù ṣe di agbábọ́ọ̀lù nílẹ̀ òkèèrè

Awọn agbabọọlu Afghanistan marun un wọ aṣọ pupa, ọkan lara wọn to we sikaafi dudu na ọwọ soke

Oríṣun àwòrán, Phil Walter/Getty Images

Àkọlé àwòrán, Awọn agbabọọlu Afghanistan wọ aṣọ pupa
    • Author, Mahjooba Nowrouzi
    • Role, BBC News Afghan Languages
    • Reporting from, Auckland, New Zealand
  • Published
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Awọn agbabọọlu wa ninu yara ti wọn ti maa n paarọ aṣọ, awọn kan n de bata, nigba tawọn mii n di mọ ara wọn.

Fatima Haidari to jẹ agbabọọlu aaringbungbun sọ pe ''ẹ ṣe giri tori awọn obinrin orilẹede Afghanistan la n ṣoju.''

Ariwo ayọ sọ ninu yara tawọn agbabọọlu naa wa nibi ti asia Afghanistan ti wa loke.

Bi awọn kan ninu wọn ṣe n kọrin ni omi le roro loju awọn mii ninu wọn.

Ẹgbẹ agbabọọlu Afghanistan ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹtalelogun lọ n ṣe igbaradi lẹyin odi lẹyin ti wọn ti rinrin ajo lọ si orilẹede New Zealand nibi ti wọn yoo ti kopa ninu ere bọọlu ọlọọrẹsọọrẹ meji ni erekusu Cook Islands.

Igba akọkọ ree tawọn agbabọọlu naa lanfaani lati wa papọ lati igba ti ajọ FIFA ti sọ pe wọn le ṣoju orilẹede wọn ninu idije ere bọọlu lọjọ iwaju.

Awọn ọjẹwẹwẹ agbabọọlu bi ogun doyi yi tabili kan ka, wọn si fi ọwọ si ara wọn lejika

Oríṣun àwòrán, Afghan Women United

Lati ọdun 2021 ti awọn Taliban ti gbajọba ni wọn ti fofin de awọn obinrin wi pe wọn o gbọdọ kopa ninu ere bọọlu atawọn ere idaraya mii.

Bakan naa ni ijọba Taliban to fofin de awọn obinrin wi pe wọn o le lọ si ile ẹkọ alakọbẹrẹ to fi de ile ẹkọ giga fasiti.

Leyin naa lawọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu obinrin Afghanistan ti wọn da silẹ lọdun 2007 rinrin ajo lọ si awọn ilu okeere bii Australia, UK ati Portugal ti wọn si n gbe nibẹ.

Bayii ni awọn ọmọ ẹgbẹ agbabọọlu obinrin bẹre sii sọrọ tako igbesẹ yii titi ti wọn fi da ẹgbẹ agbabọọlu ẹyin odi silẹ.

Lẹyin naa ni ajọ FIFA dajọ wi pe ẹgbẹ agbabọọlu yii le kopa ninu idije ere bọọlu ti ajọ naa ba ṣe agbatẹru rẹ.

Inu awọn agbabọọlu naa n dun bayii lẹyin ti wọn tun ko ara wọn jọ ni New Zealand.

Manozh Noori to jẹ ọkan lara awọn agbabọọlu naa to ba BBC sọrọ sọ pe ọpọ eeyan lo maa n wo oun bi ọkunrin.

Manozh Noori to wọ ẹwu ti wọn maa n fi gbabọọlu pupa duro, awọn akẹgbẹ rẹ wa lẹyin rẹ
Àkọlé àwòrán, Manozh Noori bo ami ẹyẹ to gba mọlẹ ki o to sa kuro ni Afghanistan

Noori to n gbe ni Australia maa n gba bọọlu pẹlu awọn ọkunrin nigba to n dagba niluu Kabul.

O pada di agbabọọlu, koda, o gba idije liigi atawọn ami ẹyẹ ọlọdanni mii.

Noori maa n wọ ibori to ba n gbabọọlu tori o mọ pe awọn ẹgbọn rẹ ọkunrin yoo ba a wi ti wọn ba mọ pe o n gba bọọlu.

Amọ, ẹbi rẹ pada ri i wo lori ẹrọ amohunmaworan, buọda rẹ si binu si i gidi gan an.

O ni buọda oun sọ pe ṣe bi oun ṣe fẹ kawe di dokita ni bọọlu toun n gba kiri?

Noori ni mama oun bẹrẹ si sunkun tori buọda oun lo n ṣeramwọ owo fun ẹbi awọn

Manozh Noori to wọ iboju dudu n gbabọọlu pẹlu agbabọọlu to wọ ẹwu funfun

Oríṣun àwòrán, Manozh Noori

Àkọlé àwòrán, Noori wọ aṣọ olomi buluu

Noori kọkọ dẹkun bọọlu gbigba, amọ, o pada sẹnu rẹ nigba to ya.

O ni buọda oun kan to n gbe ni Germany ba oun fowo ranṣẹ ki ala oun le wa si imuṣẹ.

Noori sọ pe oun yoo pada si Afgahnistan lọjọ kan lati ju awọn ami ẹyẹ oun toun bo mọlẹ.

Noori sọ pe ere bọọlu lo ran oun lọwọ lati gbe mama ati aburo oun obinrin kuro ni Afghanistan.

Bi Noori ati awọn akégbẹ rẹ ṣe n gbaradi fun ere bọọlu ti wọn fẹ gba, wọn ni ere bọọlu lo doola awọn lọwọ ijọba Taliban ni Afghanistan.

Awọn agbabọọlu obinrin Afghanistan

Bi awọn agbabọọlu naa ṣe n gbaradi fun ere bọọlu meji ti wọn fẹ gba ni erekusu Cook, wọn ni ipinnu wi pe gbogbo ipa awọn lawọn yoo sa lati pegede.

Nigba to wa ni ọdọ, Najma Arefi, ti ṣe igbaradi ri lasiko ti oorun mu to iwọn 45C.

Doncaster ni Arefi n gbe bayii lapa ariwa England, lẹyin to de UK nigba ti Taliban gbajọba.

She describes herself as an extrovert and says she now has opportunities she never imagined growing up in Afghanistan.

Arefi ni ẹni to maa n sọrọ daadaa loun, oun si ti ni oriṣiiriṣii anfaani ni UK.

Najma Arefi to wọ aṣọ pupa n gba bọọlu lori papa iṣere.

Oríṣun àwòrán, Phil Walter/Getty Images

Àkọlé àwòrán, Najma Arefi to wọ aṣọ pupa n gba bọọlu.

Ẹkọ nipa idajọ ododo lori iwa ọdaran ni o kọ nipa rẹ nile ẹkọ giga.

O ni lọpọ igba ni inu oun ma an bajẹ toun ba ti ranti pe awọn obinrin ko ni ominira ni Afghanistan.

O wa dupẹ lọwọ Khalida Popal to da ẹgbẹ agbabọọlu Afghanistan silẹ lẹyin odi ti o si ri pe FIFA buwọlu u.

Nigba ti BBC bi adari ere idaraya ni Afghanistan, Ahmadullah Wasiq, leere nipa bi FIFA ṣe buwọlu idasilẹ ẹgbẹ agbabọọlu obinrin fun Afghanistan lẹyin odi, o kọ lati sọrọ.

Ẹwẹ, ẹgbẹ agbabọọlu Cook Islands lo gbegba oroke pẹlu ami ayo 1-0 ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọọrẹsọọrẹ akọkọ ti ẹgbẹ agbabọọlu Afghanistan gba.

Lẹyin naa ni wọn tun fidirẹmi pẹlu ami ayo 3-0 ninu ere bọọlu keji ti wọn tun gba pẹlu Cook Islands.

Amọ, awọn agbabọọlu obinrin Afghanistan ko ri nnkan to ṣẹlẹ gẹgẹ bii ijakulẹ.

Ohun ti wọn n ro ni anfaani ti wọn tun ni lati pada kora wọn jọ gba bọọlu lẹyin odi lẹyin ọpọ ọdun ti wọn ti fi sa kuro lorilẹede wọn.

Aworan to n sọ nipa awọn obinrin kaakiri agbaaye.