Wo kókó ohun márùn-ún tó ń fa àìgbọ́raẹniyé láàárín tọkọtaya

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bi ko ba si ifọkantan ati igbagbọ ninu ibaṣepọ, o le mu ki igbe aye gẹgẹ bii lọkọlaya di orisun wahala tabi iporuru ọkan, leyi to le ṣokunfa iyapa laaarin wọn.
Ọpọ ohun lo si maa n ṣẹlẹ nigba ti ọkan lara awọn ololufẹ, tabi awọn mejeeji ko ba nigbagbọ tabi le gbe ara le ara wọn. Fun apẹẹrẹ, ọkọ le ma nigbagbọ ninu iyawo rẹ lasiko to ba jade lọ, tabi pe iyawo naa ma nigbagbọ ninu ọkọ rẹ.
Ni eyi to fi ara pẹ ẹ, bi ọkunrin ati obinrin ba n ba ara wọn dọrẹ, gẹgẹ bii ọrẹkunrin ati ọrẹbinrin, obinrin naa le fi ẹsun agbere kan ọrẹkunrin rẹ, tabi ọkunrin naa fi ẹsun iwa agbere kan ọrẹbinrin rẹ.
Ibeere naa ni pe, 'ki lo n fa ainigbagbọ ninu ara ẹni, eyi to maa n fa ipinya tabi iyapa laaarin tọkọtaya ti wọn n gbe papọ?'
BBC ba Maryam Hassan Baba, ẹni to jẹ akọṣẹmọṣẹ lori ọrọ to nii ṣe pẹlu idile, ẹni to ni oju opo ayelujara "The Northern Therapist" sọrọ.
Àwọn ohun tó n fa ainifẹ-ara-ẹni
Akọṣẹmọṣẹ naa tọka si ohun marun-un pataki to maa n finna mọ ainigbagbọ ninu ololufẹ meji, awọn si ni:
1. Aisi ibanisọrọ to to:
Lọpọ igba, ọkọ ati aya, tabi ololufẹ meji maa n lakaka lati maa ba ara wọn sọrọ atigbadegba, paapaa nigba ti wọn ba ni gbolohun asọ tabi ija. Nigba ti otitọ ba fara sin, tabi ki wọn ma le sọ bi nnkan ṣe ri lọkan ara wọn, o maa n fa aigbọra-ẹni-ye, to si tun maa n yọri si aile gbagbọ ninu ara wọn.
2. Ikuna lati mu awọn ileri ṣẹ:
Ikuna lati mu awọn ileri wa si imuṣẹ, didalẹ, tabi aigbagbọ ninu ara ẹni maa n pa ipilẹ igbagbọ ninu ololufẹ meji run.
3. Irọ pipa lati igbadegba:
Irọ pipa atigbadegba, paapaa lati maa fi ọrọ to ṣe pataki pamọ fun ara ẹni, maa mu iyemeji dani, to si maa n fa ainigbagbọ ninu ara ẹni.
4. Apọju owu jijẹ ati ifurasi:
Bi eeyan ba n jowu lapọju, o maa n fa ibẹru lati padanu ololufẹ ẹni, to si le yọri si ifẹsunkan ti ko lẹsẹ nilẹ, eyi to maa n ba ibaṣepọ jẹ.
5. Aibọwọ funra ẹni:
Aibọwọ fun ololufẹ ẹni, sisọrọ abuku si wọn, tabi aigba erongba wọn, maa n fa erokero nipa ibọwọ funra ẹni, to si maa n fa kudiẹkudiẹ nipa gbigba ara-ẹni gbọ laaarin ololufẹ.
Ni apapọ, gbogbo awọn iwuwasi yii lo bẹrẹ pẹlu ẹkunrẹrẹ, ṣugbọn bi ko ba tete ni abojuto, o le pa ipilẹ ibaṣepọ run patapata.
Wo àwọn ọ̀nà láti borí àwọn ìṣòro laarin tọkọtaya
Maryam Hassan Baba, to jẹ akọṣẹmọṣẹ lori ọrọ to nii ṣe pẹlu idile, ẹni to ni oju opo ayelujara "The Northern Therapist" ṣalaye ọna mẹrin lati ṣe atunṣe lori ibaṣepọ to ni ipenija:
Ẹ ni ibara-ẹni-sọrọ nirọwọ irọsẹ, ati nipa iwa otitọ:
O ṣe pataki ki ololufẹ meji ba ara wọn sọrọ nirọwọ irọsẹ, lai fi ohunkohun pamọ funra wọn, ati nipa erongba lati gbọ ara wọn ye.
Agbekalẹ nipa otitọ ati mimu ileri ṣẹ:
Lati maa wa ni otitọ, ati lati rii daju pe a n mu ileri wa ṣẹ, maa n ṣe anfaani pupọ lati da igbagbọ ninu ara ẹni pada.
Bibọwọ fun ara-ẹni ni gbogbo ọna: Bibọwọ fun erongba ati imọlara ololufẹ ẹni ati iru eeyan ti ẹni naa jẹ, jẹ ipilẹ to ṣe pataki si atunṣe ibaṣepọ to ti n dẹnukọlẹ.
Wa amọran nigba ti iṣoro naa ba le koko:
Nigba ti awọn iṣoro ba ti n de ibi to ni apẹẹrẹ, iranlọwọ awọn akọṣẹmọṣẹ tabi olugbani-nimọran lori ọrọ mọlẹbi le jẹ ọna abayọ nla.
Ohun mẹ́fà tí tọkọtaya kò gbọdọ̀ sọ sí ara wọn Ọpọ awọn eeyan lo maa n lo oniruuru ọrọ lati ṣafihan si ololufẹ wọn wi pe wọn n la iṣoro ailera ọpọlọ kọja. Ṣugbọn sibẹ, wọn maa n ṣe awọn nnkan wọnyi nitori pe wọn n wa ohun miran ninu elomiran.
Akọṣẹmọṣẹ naa tọka si awọn ọna mẹfa wọnyi:
Were/Ainironu Mo n ṣere Iwọ lo jẹ ki n ṣe bẹẹ. Bi o ba fẹ, o le ṣee funra rẹ. Gbogbo eeyan lo gba pẹlu mi, yatọ si iwọ nikan Iwo ni iṣoro nla naa.





























