Lóòtọ́ ni Prigozhin ti dágbére fáyé – Ìwádìí Sáyẹ́ńsì jáde!

Prigozhin

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published

Iroyin ti jade pe adari ikọ ajagunta Wagner, Yevgeny Prighozin ti dagbere faye lootọ lẹyin awuyewuye to waye pe o ku ninu ọkọ baalu kan to ja lulẹ lọsẹ to kọja.

Ikọ aṣewadii Russia (SK) lo gbe abajade akanṣe ayẹwo onimọ sayẹnsi jade nipa awọn oku ti wọn wa ninu ọkọ baalu to ja ọhun lỌjọru ọsẹ.

Ọkọ baalu Prighozin ja walẹ ni iha Ila Oorun-Ariwa Moscow ni Ọjọ Karunlelọgbọn Osu Kẹjọ to si pa gbogbo awọn arinrinajo to wa ninu baalu naa.

Ikọ SK ni iwadi to lu mọ iwa ọdaran ṣi n lọ lọwọ.

“Gẹgẹ bi abọ iwadii to jade, oju awọn mẹwẹẹwa to wa ku ti hande.

Lara wọn ni awọn ọgagun ninu ikọ Wagner, ikọ ajagunta ilẹ Russia kan ti Prigozhin ṣe agbekalẹ rẹ ti wọn maa n jagun ni Ukraine, Syria atawọn apa ibi kan ni Afirika.

Lara wọn ni Dmitry Utkin to n ṣakoso ieto ijagun fun Wagner.

Orukọ awọn mii ti wọn jọ n kọwọ rin lati Moscow lọ si St. Petersburg ni awọn ọmọ ikọ Wagner: Valery Chekalov, Sergei Propustin, Yevgeny Makaryan, Alexander Totmin ati Nikolay Matuseyev.

Awakọ baalu Alexie Levshin ati igbakeji rẹ, Rustam Karimov lo wa ọkọ ofurufu naa ti oṣiṣẹ inu baalu kan, Kristina Raspopova naa si wa lara wọn.

Bi ọkọ baalu yii ṣe ja lulẹ n waye lẹyin oṣu meji ti Prigozhin dari ikọ Wagner kan lati kọlu awọn ologun Russia ti wọn si gbajọba ẹkun Guusu ilu Rostov ti wọn tun leri lati kogun lọ Moscow.

Amọ oju ogun naa rọlẹ lẹyin adehun kan to mu ki Prigozhin ati ikọ rẹ ṣi lọ si Belarus.

Ẹwẹ, Aarẹ orilẹede Russia, Vladimir Putin ṣapejuwe iku rẹ bii “fifi ọbẹ ẹyin jẹ eeyan ni iṣu.” Bẹẹ si ni awọn kan ti n woye wipe o ṣeeṣe ki awọn ikọ ogun Russia lọwọ ninu iku Prigozhin lọna kan tabi omiran.

Bakan naa ni ọjọ Ẹti ni agbẹnusọ fun Kremlin, Dmitry Peskov sọ pe irọ gbaa ni awuyewuye n jade pe ejo lọwọ nnu nipa iku Ọgagun naa.

Aarẹ Putin ti fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si ẹbi awọn to jade laye to si tun ṣapejuwe Prigozhin gẹgẹ bi “ẹni to ni ẹbun gidi gan to ṣe ọpọlọpọ aṣiṣe ni igbesi aye rẹ”.

Ta ni Yevgeny Prigozhin tí àgbáyé ń pariwo ikú rẹ̀ báyìí?

Aworan Prigozhin

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ni ọjọru ni iroyin jade pe baluu kan ja lorilẹede Russia.

Iroyin naa sọ siwaju pe gbogbo awọn eeyan to wa ninu rẹ lo ti jẹ ipe Eleduwa.

Amọṣa, ohun kan to wa gbode lori ijamba buruku yii ni orukọ Ọgbẹni kan, Yevgeny Prigozhin to ni ileeṣẹ ajagunta kan lorilẹede Russia.

Ileeṣẹ ajagunta yii kun ara awọn ti ijọba Russia n lo lorilẹede Ukraine.

Ileeṣẹ naa pẹlu n kopa ninu oniruru awọn ogun to n lọ lọwọ lorilẹ Afrika.

Ibeere ti ọpọ wa n beere ni pe, ta ni arakunrin Prigozhin yii to fi di ẹni ti gbogbo agbaye n fẹ mọ boya lootọ lo wa ninu baluu naa gẹgẹbi iwe orukọ awọn to wa ninu baluu ọhun ṣe fihan.

Tani Yevgeny Prigozhin to doloogbe?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Prigozhin ni adari ikọ ajagunta Wagner mercenary group ti o da silẹ ni ọdun 2014

O jẹ ọlala kan ti wọn ti fi ẹsun iwa ọdaran kan ri, ti o si ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi olounjẹ aarẹ Putin ri.

Ni Oṣu Kẹfa ọdun yii lo dari awọn ikọ ọmọogun rẹ lati gbiyanju lati ditẹ gba ijọba Russia, amọ to jawọ lẹyin iṣẹju diẹ.

Labẹ iditẹ gbajọba naa ni wọn ti dari gbogbo ẹṣẹ rẹ jii, to si kuro nibẹ lọ si agbegbe Belarus.

Lati igba naa ni ko ti si ẹni to gburo rẹ ko to di pe fidio jade pe o wa ni ilẹ Afrika.

Ààrẹ ilẹ̀ Russia, Vladmir Putin kọ̀ láti sọ̀rọ̀ lórí ìkú ajaguntà, Prigozhin

Aworan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarẹ orilẹede Russia, Vladimir Putin ti kọ lati sọrọ lori bi ajagunta, Yevgeny Prigozhin.

Eyi waye lẹyin ti ọkọ baalu ti Prigozhin wọ ja lulẹ ni agbegbe to sunmọ orilẹede Russia.

Putin ọun lo sọrọ lori ẹrọ ayelujara lasiko to n kopa ninu ipade ajọ BRICS to waye ni Johannesburg, lorilẹede South Africa.

Putin dupẹ lọwọ aarẹ Cyril Ramophosa fun ipade naa, ati fun gbigba awọn orilẹede marun un laaye lati darapọ mọ wọn.

Ajọ Brics naa fi iwe pe orilẹede Argentina, Egypt, Iran, Ethiopia, Saudi Arabia ati United Arab Emirates lati darapọ mọ wọn.

Minisita fun ọrọ ilẹ okeere, Sergiv Lavrov to ṣoju Putin nibi ipade naa ni orilẹede South-Africa lo wa nibi ipade naa amọ ko ba awọn eniyan sọrọ.

Iru iṣẹ wọ ni ileeṣẹ Wagner Mercenary Group n ṣe?

Aworan

Oríṣun àwòrán, Reuters

Yevgeny Prigozhin lo da ileeṣẹ naa silẹ ni ọdun 2014

Ti wọn si kọkọ bẹrẹ iṣẹ ni ila oorun Ukraine lasiko ija laarin ikọ ọmọogun Ukraine ati Russia ni agbegbe Donbas.

Bakan naa ni wọn ti jagun ta ni awọn agbegbe ni Syria ati awọn agbegbe kan ni ilẹ Afrika.

Prigozhin to doloogbe to jẹ adari ikọ naa ni awọn fun awọn ẹlẹwọn lati Russia to le ni ẹgbẹrun marunlelaadọta lati lọ ja pẹlu orilẹede Ukraine.

Olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ ajaguntà Wagner Group, Yevgeny Prigozhin jáde láyé

Ọga agba ileeṣẹ ajagunta Wagner group, Yevgeny Prigozhin, ti jade laye.

Iku ọkunrin naa lo waye lẹyin ti ọkọ ofurufu to wa ninu ja lulẹ.

Iṣẹlẹ yii lo n waye lẹyin oṣu meji to gbiyanju lati gba ijọba lọwọ Aarẹ orilẹ-ede Russia, Vladmire Putin.

Ninu fidio kan to ti n milẹ titi lori ayelujara bayii, a ri ọkọ ofurufu naa bo ṣe gbina loju ofurufu, to si ja lulẹ lagbegbe Bologovsky.

Awọn onwoye gbagbọ pe o ṣeeṣe ki ọkunrin naa ma si ninu ọkọ ofurufu ọhun lasiko to ja lulẹ.

Amọ ileeṣẹ iroyin Daily Mail ilẹ Gẹẹsi jabọ pe ileeṣẹ to n ri si irinna ọkọ ofurufu ni Russia, Rosaviatsiya, sọ pe ologbe naa wa lara awọn ero ọkọ ofurufu naa lasiko to ja lulẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Iroyin ni o kere tan, eeyan mẹsan an lo wa ninu ọkọ ofurufu ọhun lasiko ti ijamba naa waye.

Oṣe yii lo pe oṣu meji gerege ti oloogbe naa gbiyanjuu lati ditẹ gbajọba lọwọ Aarẹ Putin.

Ti ẹ ko ba gbagbe, awọn ọmọ ẹgbẹ ajagunta ọkunrin naa n ṣatilẹyin fun awọn ologun to ditẹgbajọba lorilẹ-ede Niger, eyii to ti da rogbodiyan silẹ ni iha iwọ oorun Afrika.