Ìjọba àpapọ̀ pàṣẹ kí ọlọ́pàá mú ẹni tó ni ilé alájà méjì tó dàwó l’Abuja

buildingn colapse in Abuja

Oríṣun àwòrán, bbc

Published

Àwọn ènìyàn mẹ́tadínlógójì ni ori ti ko yọ bayii, nigba ti àwọn ènìyàn míràn sì farapa yẹ́lẹ-yẹ̀lẹ nínú ìsẹ̀lẹ̀ ilé tó wó lulẹ̀ ní agbègbè Garki, nílùú Abùjá.

Ìsẹ̀lẹ̀ náà wáyé ní déédé aago méwàá alẹ Ọjọru.

Ọ̀kan lára olùgbé ilè náà, Gideon Agada ni oun lọ, amọ nigab ti ou yoo fi maa pada bọ nile, gbi ni oun gbọ ti ile ọhun ti da wo lati oki si isalẹ.

Ó tẹ̀síwájú pé, ní kete ti ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ ni awọn pe ilé iṣẹ́ panápaná, àjọ tó ń sàmójútó ìsẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì, NEMA àti àwọn ọlọ́pàá láti wá dóòlà àwọn ènìyàn to ha sibẹ.

Ijọba apapọ paṣẹ ki ọlọpaa mu ẹni to ni ile naa to dawo

Minisita fun ilu Abuja, Nyesom Wike ti paṣẹ ki ileeṣẹ ọlọopaa fi ṣikun ofin mu eni to ni ile naa to dawo.

Wike lo fi ọrọ ọhun lede lasiko to ṣabẹwo si ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye lọjọbọ.

Iroyin ni eeyan mọkandinlogoji lo wa ninu ile naa, awọn meji ti jade laye, nigba ti wọn doola eeyan mẹtadinlogoji to ti n gba itọju lọwọ bayii.

Nnkan bii aago mọkanla alẹ Ọjọru ni ile naa, to wa lagbegbe Lagos Crescent, ni Garki, dawo lẹyin ojo kan to rọ ṣaaju.

Wike sọ nibẹ pe ibi eto ti wa nilẹ lati ko awọn oluigbe agbegbe naa kuro nibẹ ṣaaju iṣẹlẹ ọhun, amọ iyalẹnu nla lo jẹ ijọba ko ko wọn kluro nibẹ.

Ilé alájà méjì wó lulẹ̀ ní ìlú Abuja, èèyàn méjì kú, ọ̀pọ̀ há sí abẹ́ àwókù ilé!

Aworan

Oríṣun àwòrán, NTA/Twitter

Ko din ni eeyan meji to ti ku nibi iṣẹlẹ ijamba ile alaja meji kan to da wo ni ilu Abuja, olu ilu Naijiria.

Ọpọlọpọ eeyan miran lo si tun ṣi ha si abẹ awoku ile to dawo naa lagbegbe Lagos Street ni Garki.

Ọga agba ajọ to n moju to iṣẹlẹ pajawiri ni ilu Abuja, Abbas Idris ṣalaye fun BBC pe eeyan mẹtadinlogoji ni wọn ti doola kuro labẹ awoku ile naa.

Ọgbẹni Abbas ni awọn oṣiṣẹ ajọ naa n ṣiṣẹ takuntakun bayii lati doola ọpọ eeyan to ṣi wa labẹ awoku ile ọhun.

Aworan

Oríṣun àwòrán, NTA/Twitter

Ninu atẹjade ti oluranlọwọ fun Minisita ilu Abuja tẹlẹ, Mohammed Bello fi si oju opo Twitter rẹ lo ti sọ bẹẹ.

Bakan naa ni iroyin ọhun fikun un pe o ṣeeṣe ki eniyan meji ti ku ninu iṣẹlẹ naa.

Aworan

Oríṣun àwòrán, NTA/Twitter

Aworan

Oríṣun àwòrán, NTA/Twitter