Ṣé lóòtọ ni Elon Musk jẹ́jẹ̀ẹ́ láti ti Peter Obi lẹ́yìn nínú fídíò tó wà lórí ayélujára?

Published

Iwadii BBC  ti fihan pe ayederu ni iroyin kan to n lọ kaakiri ori ayelujara pe ẹni to lowo julọ ni agbaye, ọmọ ilẹ America, Elon Musk ti buwọlu oludije fun ipo aarẹ lati inu ẹgbẹ osẹlu Labour Party, Peter Obi.

Ọjọ Iṣẹgun ni fidio kan, ti ko ju iṣẹju aaya mọkanlalọ, jade si ori ayelujara, ti ọpọ eeyan si ti n pin kaakiri ni Facebook, Twitter ati Whatsapp.

Ninu fidio naa ni Musk ti sọ pe ‘ẹni ti oun bọwọ fun pupọ ni Peter Obi, oun si ti ṣetan lati ṣe atilẹyin fun’.

Amọ iwadii ẹka ileeṣẹ BBC to ma n tọpinpin ayederu iroyin, fihan pe wọn dọgbọn si fidio naa ni.

Fidio naa jẹ eyi ti wọn ge lara odindi fidio ifọrọwanilẹnuwo kan ti Ọgbẹni Musk ṣe pẹlu agbohunsafẹfẹ, Sam Attman tileeṣẹ Y Combinator, loṣu Kẹsan-a, ọdun 2016.

Ninu fidio ti wọn dọgbọn si naa, wọn pa oun Ọgbẹni Musk mọlẹ, wọn si fi awọn ọrọ to jẹ mọ Peter Obi, rọpo rẹ pẹlu oun Musk ti wọn dọgbọn si.

Fidio naa ti n fa ariyanjiyan lori ayelujara, ti awọn alatilẹyin Peter Obi kan si n dunnu si ibuwọlu ayederu naa

Amọ awọn kan n kọminu lori boya ayederu ni tabi otitọ.

Iwadii BBC tun fihan si i pe, oju opo ni wọn ti ṣe ayederu fidio naa.

Oju opo itakun agbaye yii ma n fi aaye silẹ fun eeyan lati ṣe ẹ̀dà tabi dọgbọn alumọkọrọyi si awọn aṣayan fidio Elon Musk, ti wọn o si pa ọrọ to sọ dà.

Lootọ ni fidio naa yoo ni ami idanimọ ni apa oke rẹ bii ti eyi to jade nipa Peter Obi, ṣugbọn ọna miran tun wa lati yọ ami naa kuro ki aye ma ba mọ pe ayederu ni.

Ọgbẹni Peter Obi wa lara awọn oludije fun ipo aarẹ ninu idibo ọdun 2023 ni Naijiria. O si wa lara awọn to ni alatilẹyin julọ.