Ẹ ràn mí lọ́wọ́! Ìyá ń jẹ èmi àti àwọn ọmọ láti ìgbà tí Rolling Dollar ti kú - Iyawo

Fatai Rolling Dollar ati Iyawo rẹ

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Published

Iyawo gbajugbaja akọrin Highlife, Olóògbé Fatai Olagunju 'Rolling Dollar' , ti sọ pe lati igba ti ọkọ oun ti kú, ni ìṣòro airowo ná ti n ba ẹbi rẹ finra.

Fatai Olagunju 'Rolling Dollar' kú ní ọjọ kejila, oṣù Kẹfà, ọdún 2013 ni ẹni ọdun marunlelọgọrin.

Arabinrin Zainab Olagunju sọ eyi ninu ifọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan to ṣe lati ṣàmí ọdun kẹwàá ti Rolling Dollar kú.

O ni iṣẹ́ agbalẹ ojupopo ni oun n ṣe pẹlu ìjọba ipinlẹ Eko.

"Iṣẹ́ naa ti dá aisan si mi lara, débi pe òògùn ni mo n ná owo to pọ̀ si."

Arabinrin Olagunju, to bi ọmọ meji fun oloogbe sọ pe eeyan perete lo n beere oun ati àwọn ọmọ òun, tabi ṣe iranlọwọ fun wọn.

O ni oun ko ri owo san owo ile ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ.

Iyawo Fatai Rolling Dollar

Oríṣun àwòrán, OTHERS

Wo igba ewe Fatai Rolling Dollar

Fatai Rolling Dollars

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹgẹ bi ọmọ idile oye, wọn bi i lọdun 1927 si idile Oloye Olagunju ni Ede, ipinlẹ Oṣun.

Lọdọ awọn akẹgbẹ rẹ akẹkọọ lo ti ri alajẹ orukọ to n jẹ, nigba naa lọhun o ṣi jẹ bii ọmọ ọdun mẹsan an pere.

Eyi waye tori bo ṣe ni iwa ko ṣa a ma a ko owo shile meji ti baba rẹ maa n fun un gẹgẹ bii owo ti yoo fi ra nkan awọn aburo rẹ meji nigba ti baba wọn ba ti ṣe iṣẹ lọ si Ghana gẹgẹ bii awakọ.

Owó Shile meji yii pọ ju oun ti awọn ẹlẹgbẹ rẹ maa n ni lọwọ nigba yẹn torinaa ni wọn ṣe kuku fi jẹ oye ẹni ti yoo maa yi owo ẹyọ onidẹ lasiko ti wọn ba fẹ gba eree bọọlu.

Bawo ni Fatai Rolling Doller ṣe bẹrẹ iṣe orin gangan?

Fatai Rolling Dollars àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ rẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ko lee lọ ileewe mọ lọdun 1944 nigba ti baba rẹ ku, lo ba bẹrẹ si ni kọ iṣẹ mọkaliiki.

Fatai Rolling Dollar gba ọna ojú omi sa lọ pelu ọkọ ojú omi kan nigba to wa lọmọ ọdun mokandinlogun.

Eyi to mu ki iya rẹ ni ki wọn ti i mọ ile ẹ̀kọ́ṣe kan nitori iwa ipanle rẹ.

Nibẹ lo ti kọ iṣẹ ọwọ tuntun nípa orin kiko sugbọn nigba to sú u, o pinnu láti bẹ̀rẹ̀ isẹ orin kíkọ.

Bo ṣe bẹ̀rẹ̀ gẹgẹ bii alu ohun eelo orin ninu gbajugbaja ẹgbẹ́ olorin "Kokomba bands" ni 1940s niyii.

Nigba ti aṣọ Kokomba bands ko wọ igba mọ, lo ba bẹrẹ si ni lu ìlù "Agidigbo".

Lẹyin ìgbà díẹ̀ to ṣe laalaa nilu Eko, o ri isẹ lati maa lu Agidigbo pẹlu ẹgbẹ́ "Willie Payne band" lẹ́yìn eyi to darapọ mọ ẹgbẹ́ akọrin "JO Araba band" lọdun 1953.

Ogo rẹ bá bẹ̀rẹ̀ si nii tán, o bẹ̀rẹ̀ si ni ṣeré orin lori itage fún iléese Nigeria Broadcasting Corporation.

Amosa, pupọ owó tó bá wọlé nígbà náà lọhun, ọwọ oga orin lo máa ń lọ táwọn ọmọṣe elegbe kan máa ń rí taataata.

Ìhà ti Fatai yara kọ sí eyi ni pe o bẹ̀rẹ̀ si kọ ara rẹ bí wọn ṣe ń lu ohun eèlò orin "gìtá" eyi to bẹ̀rẹ̀ lọdun 1955 pẹlu gita tí kii lo batiri tabi iná ayafi afẹ́fẹ́.

Bawo ni ẹgbẹ Fatai Rolling Dollars ṣe bẹrẹ?

Fẹrẹẹ, nigba to fi di ọdun 1957, o ti da ẹgbẹ́ "Fatai Rolling Dollar & African Rhythm Band" silẹ.

Ko si pẹ rara lẹyin eyi, wọn ti bẹ̀rẹ̀ si ni ṣe àwo orín fun ilé isẹ Philips West Africa Record ti wọn si ti fi orúkọ ẹgbẹ́ rẹ silẹ láti ṣeré lọjọ òmìnira orílẹ̀èdè Naijiria lọdun 1960.

Lara awọn àgbà olorin to tun jẹ gbajugbaja to darapo mọ ẹgbẹ́ orin Fatai Rolling Dollar lọdun 1958 ni Ebenezer Obey, to di ọkan gbòógì lára àwọn Irawọ olorin Juju ni Naijiria.

Lara awọn orin ti Fatai Rolling Dollars kọ ni: Wọn kere si Number, Ori wa a dara, Saworo, Eko Akete, Baba Wa, To ba fe mo Dollar, Aduke, Feso Jaiye, Iyawo Ma pa mi, ati bẹẹbẹẹ lọ.