Lẹ́yìn ọdún méje tí àwọn aráàlú dáwọ́ jọ lu ọmọ ogun Maxwell Mahama pa, ìdájọ́ òdodo wáyé

MAJOR MAXWELL ADAM MAHAMA

Oríṣun àwòrán, FACEBOOK/MAJOR MAXWELL ADAM MAHAMA

Published

Lẹyin ọdun meje ti wọn ti n ṣe ẹjọ, ile ẹjọ giga kan lorilẹ-ede Ghana ti dajọ ẹwọn gbere fun eeyan mejila lẹyin ti wọn jẹbi ẹsun ṣiṣe iku pa ọmọ ogun kan.

Awọn ọdaran naa dero ile ẹjọ lẹyin ti wọn fẹsun kan wọn pe wọn kọlu ọgagun Maxwell Mahama lagbegbe Denkyira Obuasi, ni aringbungbun Ghana.

Ile ẹjọ ni wọn jẹbi igbimọpọ lati gbẹmi eeyan, wọn tun jẹbi ẹsun ipaniyan.

Lara awọn ọdaran to fi ẹwọn gbere jura ni ọmọ ile igbimọ aṣofin, William Baah.

Awọn to ku ni Bernard Asamoah, Akwasi Baah, Kwame Tuffour, Joseph Appiah Kubi, Kofi Nyarko, Michael Anim, Emmanuel Badu, John Bosie, Akwasi Baah, Charles Kwaning ati Kwadwo Anim.

Ṣugbọn ile ẹjọ naa ni ki awọ meji kan, Bismark Donkor ati Bismark Abanga, maa lọ nitori iwadii fi han pe wọn ko mọ ohunkohun ipa iṣẹlẹ ọhun.

Bi iku Maxwell Mahama ṣe waye

Ohun ti a gbọ ni pe ọmọ ogun naa kuro nibi to n gbe lati lọ ṣere idaraya, bo tilẹ jẹ pe ko wọ aṣọ ologun, ibọn ilewọ rẹ wa lẹgbẹ rẹ.

Iroyin ni ibi to ti duro lati ra ounjẹ lẹba ọna ni ẹni to n ta ounjẹ naa ti ri ibọn ilewọ naa lẹgbẹ ṣokoto rẹ.

Olounjẹ ọhun lo pe aṣofin William Baah lori aago pe ọkunrin kan n gbe ibọn rin kiri adugbo wọn.

Ṣugbọn aṣofin ọhun ko ṣe ọfintoto lati mọ boya ologun ni oloogbe naa ko to ko awọn eeyan mọra pe ki wọn da seria fun un.

Awọn eeyan naa korajọ lati lu Maxwell niluu bara lai bere irufẹ ẹni to jẹ.

Wọn lo igi, ọkọ, atawọn nnkan ija oloro mii lati kọlu ologun ọhun ki wọn to da epo si lara lati sọ ina si.

Lẹyinorẹyin, ẹmi bọ lẹnu Maxwell.

Wayi o, awọn mọlẹbi oloogbe naa ti sọ pe inu awọn dun si idajọ ti ile ẹjọ fun awọn ṣekupa ọkunrin naa.