Olubadan fojú hàn fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn ìròyìn tó ní ó ti wàjà

Oríṣun àwòrán, @Oyoaffairs
Olubadan ilẹ Ibadan, Oba (Dr.) Akinloye Owolabi Olakulehin ti fi oju han nita gbangba fun igba akọkọ lẹyin ọjọ meloo kan ti iroyin ofege gbode kan nipa ilera Ọba alade naa.
Olubadan ṣe agbekalẹ idanilẹkọ fun awẹ Ramadan ni aafin rẹ to n bẹ ni Oke Aremọ, lọjọ Abamẹta, nibi ti awọn alaawẹ, oloye, aṣoju ijọba, ati awọn ọba to n bẹ labẹ Olubadan ti pejupesẹ.
Idanilẹkọ naa jẹ nnkan manigbagbe nitori Kristẹni ni Olubadan.
Ninu ọrọ ti o sọ nibi ipejọpọ naa, Olubadan dupẹ lọwọ ọgọrọ eeyan to kopa nibi idanilẹkọ naa, gẹgẹ bi o ṣe n fi idi itara rẹ mulẹ fun ibagbepọ alaafia laarin ọkanojọkan ẹsin to n bẹ nilẹ Ibadan.
Kabiyesi ni, "Mo ri ara mi gẹgẹ bii Baba fun gbogbo eeyan lai fi ti ẹsin tabi ẹya ṣe."
Otun Olubadan tilẹ Ibadan, Ọba (Sẹnatọ) Rashidi Adewolu Ladoja naa kin ọrọ Olubadan lẹyin pẹlu alaye wi pe lati ọjọ pipẹ ni ilẹ Ibadan ti fi aye gba ọkanojọkan ẹsin lai si ija tabi ikunsinu.
Ṣaaju ni iroyin ti kọkọ gbode pe Olubadan ti waja lẹyin aisan ranpẹ, ti iroyin naa si milẹ titi ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin.
Amọ iwadii BBC Yoruba fi han pe irọ lasan ni iroyin naa ati pe ko si nnkankan to ṣe Oba Olakulehin.
Ninu ifọrọwerọ BBC pẹlu ọkan lara awọn ọmọ ori ade naa, o "ko si nnkan to ṣe baba o, baba n sun lọwọ."



























