Àwọn agbébọn ló dojú ààbò ilẹ̀ Yorùbá délẹ̀, digbí là wá lẹ́yìn Sunday Igboho - Afenifere

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ẹgbẹ Afenifere ilẹ Yoruba ti ke si awọn to n dunkoko mọ Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho lori erongba rẹ lati ri daju pe awọn agbebọn atawọn agbeṣumọmi fi ilẹ Yoruba silẹ patapata.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ egbẹ Afenifere, Jare Ajayi fi sita lọjọbọ, ọjọ Kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2026 sọ pe Igboho ko dunkoko mọ iran kankan bikoṣe awọn eeyan ati ẹgbẹ ti wọn n da alaafia ilẹ Yoruba laamu.

Ẹ o ranti pe latari ijinigbe ati ipaniyan to n waye ni agbegbe Igboho, Igbeti ati Kisi ni Oke Ogun ipinlẹ Oyo, Sunday Igboho ṣabẹwo si ilu rẹ to jẹ ilu Igboho to si fun awọn agbebọn to ji awọn obinrin kan ati ẹbi rẹ gbe ni ilu naa ni wakati meji lati tu awọn ti wọn ji gbe silẹ tabi ki wọn ri pinpọn oju oun.

Igboho tun ba awọn olori Fulani to wa ni agbegbe naa sọrọ pe ki wọn ba awọn eeyan to n ṣiṣẹ laabi ni agbegbe naa sọrọ, to si tun ṣekilọ fawọn ọmọ Igboho ati ọmọ Yoruba kankan to n ba ṣe atilẹyin fawọn ajinigbe pe oun maa pa ẹni naa ni.

"Ko si nnkan to buru ninu nnkan ti Igboho ṣe lati da aabo bo awọn eeyan ilẹ Yoruba"

Igboho ninu fidio mii n beere fun atilẹyin awọn ọba ilẹ Yoruba lati le gbogbo awọn ajinigbe ati ọdaran kuro ninu igbo ilẹ Yoruba, to si ni ajoji to ba fẹ maa gbe nilẹ Yoruba nilo lati kuro ninu igbo ki wọn bọ si igboro nibi ti oju ti maa ka gbogbo wọn.

Ẹwẹ, lẹyin idunkoko Igboho yii, awọn ẹgbẹ lẹkun ariwa Naijiria bii Arewa Consultative Forum, ACF, Northern Elders Forum, Coalition of Northern Groups ati Concerned Fulani People of Nigeria bu ẹnu atẹ lu Sunday Igboho fun gbedeke to fun awọn Fulani naa.

Wọn fẹsun kan Sunday Igboho pe niṣe ni o n fi oju awọn perete to n wu iwa ibajẹ wo gbogbo iran Fulani, to si n pe gbogbo wọn ni ọdaran.

Bakan naa ni wọn ni ki Aarẹ Bola Tinubu ati Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde lati fa Igboho leti ko yẹ pe gbogbo iran Fulani ni ọdaran.

Amọ ẹgbẹ Afenifere ni ko si nnkan to buru ninu nnkan ti Igboho ṣe lati da aabo bo awọn eeyan ilẹ Yoruba.

Wọn ni niwọn igba ti Igboho ko ti ṣe ohun to lodi si ofin, pipe awọn alaṣẹ lati fiya jẹ ẹ tabi koju oro si jẹ ojuna lati tabuku ohun to n ja fun lati da aabo ilẹ Yoruba.

"Aabo to daju wa nilẹ Yoruba tẹlẹ, awọn darandaran to n daran jẹ oko awọn eeyan lo da gbogbo rẹ ru"

Afenifere tun woye pe jẹ ọkan lara awọn ẹkun ti alaafia jọba nibẹ julọ tẹlẹ ni gbogbo Naijiria, to si fi aaye gba tolori tẹlẹmu, to fi mọ awọn eeyan lati ilẹ ariwa lati fi agbegbe yii ṣe ibujokoo ati dokoowo nibẹ.

Wọn ni amọ ayipada ti n ba eyi nigba ti awọn Fulani darandaran kan ti n da ẹran jẹ oko awọn eeyan nilẹ Yoruba, ti ijinigbe lati fi gba owo fi n peleke si, to fi mọ lile awọn awọn eeyan kuro ninu ilu wọn.

Bakan naa ni ẹgbẹ naa tun sọ pe iwadii tun ti fi han pe awọn to n ṣe iwakusa lọna aitọ ni wọn ti fidi rẹ mulẹ pe wọn n ṣe agbatẹru igbeṣumọmi, ti wọn si maa n le awọn eeyan kuro nile wọn ki wọn le ri iṣẹ ibi wọn ṣe.

Ajayi ninu atẹjade naa fi kun pe awọn ẹṣọ aabo ti ṣaaju sọ pe awọn agbeṣumọmi ti wọn le kuro ni igbo Sambisa ti ọpọ wọn jẹ Fulani ni wọn sa wa si ẹkun Guusu, ti wọn si n da ilẹ Yoruba atawọn ibomii laamu.

O fi kun pe kii ṣe gbogbo iran Fulani ni Igboho n daju itara kọ bikoṣe awọn to n lọwọ ninu ipaniyan ati ijinigbe lati fi gba owo ni ilẹ Yoruba.

O wa rọ agbaagba ẹkun Ariwa lati ṣayẹwo ohun to n mu kawọn agbeṣumọmi maa ri awọn eeyan gba sinu iṣẹ ibi wọn nirọrun ni ẹkun naa, to fi mọ awọn ọdọ ti ko lọ sile ẹkọ lati ri daju pe opin de ba igbeṣumọmi ni ẹkun naa ati ile Naijiria lapapọ.

A kan saara si Aarẹ Bola Tinubu fun fifi aba idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ ṣọwọ sile aṣofin

Ajayi tun kan saara si Aarẹ Bola Tinubu fun fifi aba idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ ṣọwọ sile aṣofin, to si tun gboriyin fawọn aṣofin naa bi wọn ṣe tete buwọlu u.

O parọwa sawọn ile aṣofin ni ipinlẹ kọọkan lati tete buwọlu aba naa ni kete ti wọn ba ti fi ṣọwọ si wọn, to si ni kawọn gomina ipinlẹ kọọkan tete ṣe idasilẹ awọn ọlọpaa naa ni kiakia.

Bakan naa lo ni ki wọn ṣaridaju rẹ pe wọn gba awọn eeyan ti ko akọọlẹ iwa ọdaran, ki wọn ṣe idanilẹkọọ to peye fun wọn, ki wọn si fun wọn ni ohun elo to ye lati fi ṣe iṣẹ wọn bo ṣe tọ ki alaafia le jọba laaarin ilu.

Ọ̀pọ́ ẹ̀ṣọ́ ààbò Iru Ekun farapa bí wọ́n ṣe fìjà pẹ́ẹ́ta pẹ̀lú àwọn agbébọn nínú igbó Old Oyo National Park

Ọpọ awọn ọmọ egbẹ Iru Ekun to jẹ ẹṣọ aabo Oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho farapa yannayanna nigba ti wọn fija pẹẹta pẹlu awọn agbebọn ninu igbo Old Oyo National Park.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin Nigerian Tribune ṣe sọ, iṣẹlẹ naa waye lasiko tawọn ẹṣọ aabo Iru Ekun n gbiyanju lati tọpinpin awọn agbebọn naa lọ ninu igbo Old Oyo National Park.

Wọn ni awọn ẹṣọ aabo naa gbiyanju lati lo duroonu lati fi ṣawari ibi ti awọn agbebọn naa wa ki wọn to tọ wọn lọ.

Ṣugbọn iṣẹlẹ naa di wahala nigba ti awọn afurasi agbebọn naa ti wọn ti gọ sibikan ṣina ibọn bolẹ fun awọn ẹṣọ aabo Iru Ekun naa ti awọn mejeeji si fija pẹẹta ninu igbo naa.

Wọn ni eyi ṣokunfa bi ọpọ awọn ẹṣọ aabo farapa yannayanna bi o tilẹ jẹ pe a ko tii le fidi iye eeyan to farapa ninu iṣẹlẹ naa mulẹ.

Titi di asiko ti a n ko iroyin jọ, ileeṣẹ ọlọpaa atawọn ẹṣọ aabo Iru Ekun ko i tii sọ ohunkohun lori ikọlu naa.