You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìjọba Ondo gbẹ́sẹ̀lé èsì ìdánwò akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́tàdínlógún torí fídíò àṣemáṣe tó gba orí ayélujára
Ni opin ọsẹ to kọja ni awọn fidio awọn akẹkọọ ti wọn n kẹkọọ jade iwe mẹwaa ni ipinlẹ Ondo gba ori ayelujara.
Ninu fidio naa ni awọn akẹkọọ ti wọn pari idanwo WAEC n ṣayẹyẹ pe awọn ti pari iwe mẹwaa wọn amọ tawọn fidio naa fa oniruuru awuyewuye tawọn eeyan si n sọ ariwisi lori rẹ.
Ohun to mu awọn eeyan maa sọrọ nipa fidio naa ni awọn iwa tawọn akẹkọọ naa wu ninu awọn fidio naa.
Lara awọn fidio naa ṣafihan bi awọn akẹkọọ ọkunrin ṣe bẹrẹ si ni da gbogbo igboro ru lẹyin ti wọn pari idanwo naa, ti wọn si lọ ba awọn akẹkọọ ni ile ẹkọ mii ja.
Fidio mii ṣafihan báwọn akẹkọọ to ṣẹṣẹ pari idanwo asejade ti n jo, tawọn ọkunrin si n bu awọn obinrin lọyan nita gbangba
Fidio mii tun ṣafihan ibi tawọn akẹkọọ to ṣẹṣẹ pari idanwo naa ti n jo awọn oriṣiriṣi ijo tawọn ọkunrin si n bu awọn obinrin lọyan nita gbangba.
Ọpọ eeyan lo tib u ẹnu atẹ lu awọn fidio yii paapaa bi wọn ṣe woye pe ọmọde ni awọn akẹkọọ ọhun ti ko si tọna lati maa ba irufẹ iwa bayii lọwọ awọn akẹkọọ paapaa awọn to ṣẹṣẹ n pari iwe mẹwaa.
Eyi mu ki ọpọ awọn eeyan maa pe akiyesi ijọba ipinlẹ Ondo lati mojuto eto ẹkọ ni ipinlẹ naa bi wọn ṣe woye pe o yẹ ki ijọba fi iya to tọ jẹ awọn akẹkọọ to wa nidii iwan aa paapaa awọn ti wọn gbe iru fidio bẹẹ sori ayelujara.
Ijọba ipinlẹ Ondo ti wa fesi bayii, ti ijọba si ni awọn ko ni fun awọn akẹkọọ mẹtadinlogun ninu awọn to kopa ninu iwa ibajẹ to gba ori ayelujara ni esi idanwo ati iwe ẹri pe wọn jade nile ẹkọ wọn.
Iléeṣẹ́ eto ẹ̀kọ́ l'Ondo ni káwọn ọ̀gá ile ẹkọ girama ṣagbekalẹ irufẹ ijiya yìí fawọn akẹkọọ mii ti wọn ba tun ṣawari to tun n huwa aitọ
Wọn awọn akẹkọọ ti ijọba gbẹsẹle esi idanwo wọn naa jẹ awọn akẹkọọ lati ile ẹkọ Oyemekun Grammar School, Aquinas College, Akure ati CAC Grammar School.
Atẹjade ti ileeṣẹ to n ri si eto ẹkọ, sayẹnsi ati imọ ẹrọ ni ipinlẹ Ondo fi lede sọ pe awọn akẹkọọ naa kopa ninu awọn iwa aitọ bii yiya aṣọ ile ẹkọ wọn, kikọ awọn orin ti ko ba eti mu, sisọ awọn kobakungbe ọrọ lẹyin ti wọn pari idanwo wọn.
Ileeṣẹ naa lẹyin ti wọn pari ipade kan ti wọn ṣe ni ilu Akure sọ pe wọn fẹnuko lati gbẹsẹ le esi idanwo ati iwe ẹri awọn akẹkọọ mẹtadinlogun ti wọn da mọ ninu fidio naa ati pe orukọ awọn akẹkọọ ọhun maa wọnu iwe dudu ijọba.
Wọn dari awọn alaṣẹ ile ẹkọ girama ni ipinlẹ naa lati ṣagbekalẹ irufẹ ijiya bayii fun awọn akẹkọọ mii ti wọn ba tun ṣawari to tun n huwa aitọ.
Bakan naa ni wọn tun dari rẹ pe akẹkọọ ti wọn ba tun ṣawari rẹ pe o kopa ninu fidio naa ti kii si ṣe lara awọn to n kẹkọọ ki wọn le kuro nile ẹkọ patapata.
Kọmiṣanna fun eto ẹkọ ipinlẹ Ondo, Ọjọgbọn Igbekele Ajibefun sọ pe ijọba ipinlẹ naa ko ni fi aaye gba iwa ailẹkọ laaarin awọn akẹkọọ ati titabuku ilẹ ẹkọ ati ipinlẹ naa.
Ajibefun ni bi o tilẹ jẹ pe awọn akẹkọọ ni anfaani lati ṣayẹyẹ ti wọn ba pari ẹkọ amọ ti wọn gbọdọ ṣe e pẹlu ilana to yẹ lai huwa ibajẹ.
O tẹmpẹlẹmọ pe ijọba ni ifarajin si mímú ìgbéga bá ètò ẹ̀kọ́ ní ìpínlẹ̀ náà.
Bákan náà ló rọ àwọn òbí àti alágbàtọ́ láti máa ṣe atọ́nà àwọn ọmọ wọn láti yé kópa nínú àwọn nǹkan tó le bá ọjọ iwaju wọn jẹ.