You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹgbẹ̀rún kan lé nígba ni àwọn dókítà tó ṣẹ́kù l'Ógùn – NMA pariwo síta
Ẹgbẹ awọn oniṣegun oyinbo nilẹ Naijiria, NMA, ẹka tipinlẹ Ogun ti sọ pe iwọnba ni awọn dokita to ku lawọn ile iwosan ijọba kaakiri ipinlẹ naa.
NMA sọ pe awọn dokita to le diẹ ni ẹgbẹrun kan (1,200) pere lo ku lawọn ile iwosan ijọba, to si jẹ pe awọn ni wọn n da awọn olugbe ati araalu to le ni miliọnu mẹsan lohun.
Ẹgbẹ naa ṣekilọ pe alafo naa ti ko ọpọ iṣẹ sori awọn oṣiṣẹ eleto ilera, to si ni ipinlẹ naa nilo ẹgbẹrun marun-un dokita lati pese eto ilera to pe ye.
Nigba to n sọrọ nibi ọsẹ awọn eleto ilera ti ọdun 2026, eyi to waye niluu Abeokuta tii ṣe olu-ilu ipinlẹ Ogun, alaga ẹgbẹ naa, Dokita Luqman Ogunjimi sọ pe iye awọn dokita to wa nilẹ lasiko yii kere si ohun ti araalu nilo fun itọju.
Nibi ọsẹ naa ti wọn pe akori rẹ ni "Didaabo bo awọn eleto ilera: Wiwa ọna abayọ si iwa ipa si awọn dokita ati irolagbara ilana eto ilera to wa labẹ aabo," ni wọn ti yannayanna awọn adojukọ ti wọn n dojukọ lẹnu iṣẹ.
Àkóbá fún ẹ̀ka ètò ìlera Nàíjíríà
Gẹgẹ bo ṣe sọ, bi awọn dokita ilẹ Naijiria ṣe n sa kuro lọ soke okun n ṣe adinku ba ilana iṣẹ eto ilera, leyi to n jẹ ki iṣẹ wọ awọn to ṣẹku lọrun.
O ni awọn dokita igba-le-lẹgbẹrun kan (1200) ni awọn dokita ti wọn n ṣiṣẹ fun ipinlẹ naa, to si jẹ pe dokita kan ṣoṣo lo n ṣe ojuṣe fun awọn eeyan to to bii égbẹrun meje aabo.
"Bi ẹ ba ṣagbeyẹwo iye awọn to to bii miliọnu mẹsan to n gbe nipinlẹ Ogun si awọn dokita bii ẹgbẹrun kan le n'igba to n ṣiṣẹ nipinlẹ Ogun lọwọlọwọ, ẹ maa rii pe nnkan naa ri bakan. Awọn ti wọn duro, ni wọn pinnu lati sin ilẹ baba wọn, pẹlu gbogbo ipenija yii," Ogunjimisọ bẹẹ.
Alaga NMA naa yoo nilo laaarin ẹgbẹrun marun-un si mẹwaa dokita lati le jẹ ki eto ilera ṣe ojuṣe wọn lọna to tọ, leyi ti yoo jẹ itẹwọgba.
"Ni ero wa, ipinlẹ Ogun nilo ẹgbẹ marun-un dokita. Bi a ba ni laaarin ẹgbẹrun marun-un si mẹwaa dokita, idagbaoske yoo waye daadaa. Iwọnba awọn dokita ti a ni, lo jẹ pe wọn n ṣe ohun gbogbo lati jẹ ki ẹka eto ilera ṣiṣẹ," o fi kun ọrọ rẹ.
Ìdúnkookò mọ́ àwọn dókítà lẹ́nu iṣẹ́ n kó ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá wa
Bakan naa lo tun sọ pe bi awọn araalu ṣe n dunkooko, ti wọn si n ṣe ikọlu si wọn lẹnu iṣẹ lo n jẹ ibanujẹ ọkan fun awọn, to si jẹ ko di mimọ pe awọn iwa naa n ko irẹwẹsi ọkan ba awọn dokita to ṣẹku lorileede yi.
O wa fi ẹsun kan wi pe awọn dokita to n ṣiṣẹ lawọn agbegbe to sunmọ ẹnubode bii Ọta, Mowe ati Ogijo ni awọn agbofinro n fọwọ ofin gbe lori awọn ohun to yẹ ko jẹ pe ajọ eleto ilera tii ṣe Medical and Dental Council of Nigeria lo yẹ ko yanju rẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni aikiyesara lẹka eto ilera lo yẹ ki ileeṣẹ tabi ajọ tọrọ naa kan lẹka eto ilera ṣe iwadii rẹ finifini, dipo ko jẹ pe awọn agbofinro ni yoo sọ ọ di iwa ọdaran.
"Ilana agbekalẹ wa fun iṣẹ iwadii lori aikiyesara lẹnu iṣẹ. Ajọ MDCN lo ni ojuṣe yii lọwọ. A ko faramọ ki awọn agbofinro maa fọwọ ofin mu ohun to nii ṣe pẹlu eto ilera lai tẹle ilana,"Ogunjimi kọminu.
O wa sọ pe ọpọ iṣẹlẹ lawọn ti da si, leyi to nii ṣe pẹlu ki awọn eeyan maa fi ọlọpaa gbe dokita lẹyin ti alaisan ba ku, to si ni iku alaisan kii ṣe ka maa sọ ọ di iwa ọdaran fun awọn eleto ilera.
"Awọn dokita ko le maa ṣiṣẹ wọn, ki awọn agbofinro wa lọ si ile iwosan lati lọ gbe wọn, nitori pe alaisan ku. Itọju eto ilera nilo agbeyẹwo atigbadegba, ati pe iwadii to yẹ ni lati waye ko to di pe wọn fi kọ ẹnikẹni lọrun," o jẹ ko di mimọ.
Nigba to n sọ pe bo tilẹ jẹ pe ojuṣe awọn dokita ni lati pese eto ilera to pe ye, sibẹ, ko si akọṣẹmọṣẹ eleto ilera to le fi ọkan gbogbo alaisan balẹ.
"A n sa gbogbo ipa wa lati pese eto ilera to pe ye, ṣiugbọn eyi to ju nibẹ ni pe, awa dokita kii ṣe Ọlọrun. Nibi to ba ti yẹ ki awọn eeyan fi ẹjọ sun, awọn ile iwosan ni ileeṣẹ alabojuto to faaye gba wọn, bii SERVICOM, lati da si i. A ko fọwọ si lilu tabi idunkooko mọ awọn eleto ilera," o fi kun ọrọ rẹ.
Àwa òṣìṣẹ́ elétò ìlera nílò ààbò tó pé ye
Alaga ẹgbẹ NMA wa jẹ ko di mimọ pe awọn ti bẹrẹ igbesẹ ofin ni awọn irufẹ ibi ti awọn eleto ilera ti dojukọ kọ idunkooko lẹnu iṣẹ, ati pe awọn yoo tẹsiwaju lati maa ṣe ilanilọyẹ loorekoore lori redio, iwe iroyin, amohunmaworan to fi mọ ori ayelujara lati mu adinku ba iwa ipa lodi si awọn oṣiṣẹ eleto ilera lẹnu iṣẹ.
O rọ ijọba ati awọn araalu lati pese agbegbe to ni aabo to pe ye fun awọn dokita, lati jẹ ki wọn pinu lati duro ni Naijiria, dipo ki wọn salọ soke okun.
"Ile wa ni Naijiria, bẹẹ la si farajin lati ṣiṣẹ sin awọn eeyan wa. Gbogbo ohun ti a n beere fun ni pe ki ijọba ati awọn araalu ṣatilẹyin fun wa, ki wọn si daabo bo gbogbo awọn oṣiṣẹ ati akọṣẹmọṣẹ eleto ilera," Dokita Ogunjimi rawọ ẹbẹ.
O wa gbe oṣuba kare fun Gomina Dapọ Abiọdin tipinlẹ naa, lori biwuwọ lu awọn owo ẹtọ lẹnu iṣẹ, eyi tii ṣe Professional Allowance Table and Specialist Allowance fun awọn dokita, to si jẹ ko di mimọ pe igbesẹ naa wu wọn lori.
O ni bo tilẹ jẹ pe awọn ṣi n reti ọpọ idagbasoke, ṣugbọn to ni igbesẹ tuntun yii ṣafihan ifarajin ijọba lati dide si awọn ipenija to n koju awọn oṣiṣẹ eleto ilera.
Ọna abayọ si iwa ipa to n koju awọn eleto ilera
Nigba toun naa n sọrọ, igbakeji gomina ipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Noimot Salako-Oyedele riro eto aabo lagbara lawọn ile iwosan ati aabo ofin fun awọn dokita lẹnu iṣẹ jẹ ọna abayọ kan ṣoṣo to le dena gbigbogun ti awọn oṣiṣẹ eleto ilera lẹnu iṣẹ wọn lorileede Naijiria.
Salako-Oyedele sọ ọ di mimọ pe ijọba, ajọ eleto ilera, ajọ ati ẹgbẹ akọṣẹmọṣẹ, ileeṣẹ eleto aabo ati araalu ni lati maa ṣiṣẹ papọ lati dẹkun iwa ipa si awọn oṣiṣẹ eleto ilera.
O ni bi ifọwọsowọpọ naa ba wa, yoo ri daju pe aabo wa fun awọn oṣiṣẹ eleto ilera kaakiri.
Igbakeji gomina ọhun sọ pe gẹgẹ bi iṣẹ wọb, ojuṣe awọn oṣiṣẹ eleto ilera ni lati fi gbogbo aye wọn jin fun didaabo bo ẹmi, dida alailera pada sipo ilera to pe ye, to si jẹ pe oniruuru iṣoro ni awọn naa n koju, paapaa lẹnu iṣẹ.
O jẹ ko di mimọ pe gẹgẹ bi akọsilẹ iwadii ajọ eleto ilera agbaye, WHO, ida mejidinlogoji ni awọn oṣiṣẹ eleto ilera ti wọn n koju iwa ipa lẹnu iṣẹ wọn.
"Ko yọ Naijiria silẹ, gẹgẹ bo ṣe jẹ pe kaakiri agbaye ni iwa ipa ti n ṣẹlẹ; abọ iwadii ṣafihan pe awọn dokita, awọn nọọsi ati awọn akọṣẹmọṣẹ eleto ilera ni wọn koju iwa ipa bii lilu ati idunkooko, nitori iku awọn alaisan ti wọn n tọju, lasiko ti wọn ba wa lẹnu iṣẹ," igbakeji gomina sọ bẹẹ.
O wa sọ pe ẹka eto ilera jẹ ọkan pataki lara awọn ẹka ti ipinlẹ Ogun mu lọkunkundun, paapaa labẹ iṣakoso Gomina Dapo Abiodun, pẹlu bo ni ijọba n gbiyanju lati rii pe ẹka naa duro digbi.