You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ láti dóòlà àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jí gbé nílùú Ipara l'Ogun
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti bẹrẹ iṣẹ lati doola awọn akẹkọọ tawọn janduku agbebọn ji gbe nilegbee wọn niluu Ipara nipinlẹ Ogun l'Ọjọru ọsẹ yii.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Oluseyi Babaseyi, salaye ninu atẹjade kan ti o fi sita wi pe awọn ọlọpaa n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn oṣiṣẹ eleto mii lati doola awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe naa.
DSP Babaseyi ni awọn ẹṣọ eleto aabo yoo lo gbogbo agbara wọn lati ri i wi pe awọn akẹkọọ ti wọn ji gbe gba ominira.
Bakan naa ni o tun sọ pe gbogbo awọn to wa nidii iṣẹlẹ ijinigbe naa ni ileeṣẹ ọlọpaa yoo fọwọ ofin mu.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti wa rọ awọn obi, akẹkọọ atawọn olugbe ilu Ipara wi pe ki wọn ma foya tori pe awọn ẹṣọ eleto aabo n bẹ lori iṣẹ.
Babaseyi tun rọ araalu wi pe ki wọn ye gbe irofin ofege eyi to le ṣakoba fun iwadii ti n ọlọpaa n ṣe kiri.
O wa rọ awọn araalu lati kan si awọn ẹṣọ eleto nigba kugba ti wọn ba ri ẹnikẹni tabi nnkan to mu ifura dani.
Alukoro ọlọpaa rọ araalu lati pe sori awọn nọmba pajawiri wọnyi, 0800 000 9111, 09164859299 ati 09154293464, ti wọn ba ni ohunkohun lati sọ .