Ilé-iṣẹ́ ọlọ́pàá gbé ọ̀gá ọlọ́pàá tuntun lọ sí ìpínlẹ̀ Osun ṣáájú ìdìbò gómìnà tó n bọ̀

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ Naijiria ti gbe ọga ọlọpaa tuntun lọ sipinlẹ Osun, ẹni ti yoo tukọ gbogbo eto aabo, paapaa eto idibo gomina to n bọ lọna.

Erale Samuel Etaifo ni orukọ ọga ọlọpaa tuntun naa, ẹni ti yoo ṣabojuto.

Ọga agba pata, Olatunji Disu lo kede sita fun gbogbo Naijiria, ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Abiodun Ojelabi fi sita niluu Osogbo lọjọ Ẹti.

Ojelabi sọ pe ni ibamu lati jẹ ki alaafia jọba, ati lojuna lati jẹ ki eto idibo lọ ni irọwọ irọsẹ lai ni wahala tabi ikunsinu ninu, lo jẹ ki wọn gbe ọga ọlọpaa tuntun naa wa.

Agbẹnusọ ọlọpaa naa fi kun ọrọ rẹ pe igbesẹ naa lo tun ṣafihan ojuṣe ileeṣẹ wọn lati rii pe eto idibo waye ni alaafia lai ni kọnun-kọhọ ninu, ati paapaa lati pese agbegbe ti yoo fi araalu ati oludibo, to fi mọ awọn oṣiṣẹ eleto idibo, awọn akọroyin lọkan balẹ kaakiri ipinlẹ naa.

Ojuṣe ọga ọlọpaa tuntun naa

Nigba to n tọka si awọn ojuṣe ọga ọlọpaa tuntun naa, Ojelabi sọ pe Etaifo yoo ṣakoso ati abojuto eto aabo lasiko eto idibo, nipa ifọwọsowọpọ pẹlu awọn ileeṣẹ eleto aabo yooku kaakiri ipinlẹ Osun.

Atẹjade naa sọ pe "Ọga ọlọpaa, Rilwan Olatunji Disu, ni ibamu pẹlu ifarajin rẹ si idaduro ati ṣiṣe iṣẹ lọna to tọ, ati lati ṣagbekale eto idibo alalaafia to ṣee fọkan tan, ti gbe ọga ọlọpaa eto idibo, Erale Samuel Etaifo, wa sipinlẹ Osun, lati ṣabojuto eto aabo lasiko etio idibo gomina to n bọ lọna.

"Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun fi ọkan awọn araalu balẹ wi pe gbogbo ohun to nii ṣe pẹlu eto aabo lo ti wa lojuṣe kaakiri ipinlẹ yii lati daabo bo ẹmi, dukia, ati gbogbo ohun elo idibo ṣaaju, lasiko ati lẹyin idibo.

"Gbogbo awọn ọlọpaa ti wọn ti fun ni ojuṣe lati ṣiṣẹ lasiko eto idibo ni wọn ti paṣẹ fun wi pe wọn ko gbọdọ fari apa kan, da apa kan si, ki wọn si ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ, bẹẹ si ni ki wọn bọwọ fun eto gbogbo araalu, lai wo ti ẹgbẹ oṣelu ti wọn wa," atẹjade naa ṣalaye.

Agbẹnusọ ọlọpaa wa ṣe ikilọ fun gbogbo awọn oloṣelu ati awọn alatilẹyin wọn, to fi mọ awọn alẹnulọrọ lati ko ara wọn nijanu, ki wọn si yago fun oniruuru iwa to le dabaru eto aabo aarin ilu.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, iwa ipa lasiko idibo, rira ibo, didunkooko mọ oludije, gbigbe ayederu iroyin, tabi oniruuru iwa ọdaran ni wọn yoo ba ipọnju ofin pade.

Ojelabi wa rọ awọn araalu lati maa tẹle ofin, ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu awọn oṣiṣẹ eleto aabo, bẹẹ si ni ki wọn tete fi to awọn eleto aabo leti, nigbakugba ti wọn ba kẹẹfin ohun to mu ifura dani.

Lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni eto idibo gomina yoo waye, nibi ti awọn oludije mẹrinla yoo ti kopa, to fi mọ Gomina Ademola Adeleke toun naa fẹẹ pada sipo lẹẹkeji.