You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Nǹkan mẹ́wàá pàtàkì tí máà ṣe fún aráàlú bí mo bá di gómìnà Osun rèé- Iwaloye
Oludije sipo gomina ipinlẹ Osun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC, Ọnarebu Najeem Folasayo Salaam, ti jẹ ko di mimọ pe koko ohun mẹwaa pataki loun ni lọkan lati ṣe fun araalu, eyi ti yoo mu idagbasoke ba eto ọrọ aje ipinlẹ naa.
Ọnarebu Salaam tọpọ awọn eeyan tun n pe ni Iwaloye lo ṣalaye fun BBC YORUBA lasiko akanṣe itakurọsọ fun awọn oludije sipo gomina nipinlẹ Osun, eyi to waye nirọlẹ ọjọ Ẹti, ọsẹ yii.
Agba oloṣelu naa sọ pe lara awọn nnkan pataki to n jẹ oun logun, to si wa ninu akọsilẹ ohun mẹwaa toun fẹẹ ṣe gẹgẹ bii gomina ni ti idagbasoke ti yoo de ba ọrọ ina mọnamọna, igbayegbadun awọn ọdọ ati oṣiṣẹ, to fi mọ irolagbara awọn agbẹ.
Nigba to n sọrọ, Salaam sọ pe gẹgẹ bi ẹni to ti di ipo oṣelu mu nigba kan ri nipinlẹ naa, o loun kaju oṣuwọn lati dari ipinlẹ Osun, nitori pe awọn ohun ti ko ṣẹlẹ ri loun fẹẹ mu wa fawọn araalu.
Ẹni tó bá yẹ lóyè ló n joyè, èmi ni ipò gómìnà ìpínlẹ̀ Osun tọ́ sí
O lawọn ni ki awọn eeyan foju silẹ daadaa lati yan ẹni to yẹ nipo gomina, to si loun ti fi awọn ohun pataki toun fẹẹ ṣe sita fun awọn eeyan.
"Ẹni to ba yẹ loye lo n joye, ẹni to ba mọ ọna lo n tọ ọ. Awọn nnkan ti mo fẹẹ ṣe, ti mo ti polongo rẹ, ti mo si ti fi sita, to yatọ si ohun ti wọn ti n ṣẹlẹ, tabi eyi ti wọn n ṣe lọwọlọwọ, lo jẹ ki n jade sita, lo jẹ ki n gbagbọ, ti Osun si fi duro ti mi wi pe emi ni mo yẹ loye naa ni ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii."
Nkò bu ẹnu àtẹ́ lu ẹnikẹ́ni
Ọnarebu Salaam sọ pe latigba toun ti n ṣe oṣelu, paapaa latigba toun ti bẹrẹ ipoloongo lati du ipo gomina, oun ko bu ẹnu atẹ lu ẹnikẹni tabi iṣejọba kankan, bi ko ṣe pe oun gbajumọ awọn ohun pataki toun fẹẹ ṣe fun araalu ati idagbasoke eto ọrọ aje ipinlẹ Osun.
"Latigba ti mo ti bẹrẹ ipolongo mi, nko bu ẹnu atẹ lu ẹnikẹni tabi ijọba kankan, ohun ti mo fẹẹ ṣe fun araalu lo jẹ mi logun, ati pe ki ni maa ṣe lọna to yatọ, eyi to yatọ si awọn ohun ti a ti n foju ri," oludije naa sọ eyi di mimọ.
O tẹsiwaju pe, "Ni akọkọ, ni ipinlẹ Osun lonii, emi ni oludije akọkọ to sọrọ nipa ina mọnamọna wi pe bi mo ba loore ọfẹ lati de ipo yii, ina mọnamọna wa ko nii ṣẹju mọ, bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan naa ti n to lẹyin rẹ.
"Eleyi ko si ninu nnkan ti awọn ijọba wa ti ṣe nipinlẹ Osun. Ọdun 2023 ni wọn ṣagbekalẹ eto naa, pe ki awọn ipinlẹ kọọkan ṣeto ina wọn bo ṣe wu wọn.
"Mo rii pe o ti ṣẹlẹ lawọn ipinlẹ kan, ti ko si ṣẹlẹ lọdọ wa. To ba ṣẹlẹ lọdọ wa, ọrọ aje wa a lọ soke sii. Ina mọnamọna jẹ ọkan lara awọn ọpakutẹlẹ ti eto ọrọ aje wa fi n mẹhẹ. Tia ba ri ti ina ṣe, gbogbo nnkan maa duro deedee.
"Awọn to n lo ina a rii lo, ileeṣẹ a lo, ijọba yoo lo o, adani yoo lo – ti a ba rii ṣe, ti eto aabo si duro ninu awọn eto ti mo fẹẹ ṣe, o da mi loju pe a ko nii laagun pupọ ju lati gbe awọn olokoowo wọle lati wa da ileeṣẹ silẹ nipinlẹ Osun."
Mo jẹ ànfààní ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́, èmi náà yóò ṣe é
Iwaloye, gẹgẹ bi wọn tun ṣe maa n pe e, sọ pe awọn anfaani eto ẹkọ ọfẹ toun jẹ lasiko Oloogbe Obafemi Awolowo, ti awọn ọmọde asiko yii ko ri jẹ, kloun fẹẹ gbe dide, lati ran obi ati alagbatọ lọwọ.
O ni agbakalẹ ọhun ko nii jẹ ki ọmọ kankan wa nipinlẹ naa, ti ko nii lọ sile-ẹkọ lati kẹkọọ, to si ni gbogbo ohun elo patapata ni awọn akẹkọọ yoo jẹ anfaani rẹ lati ile-ẹkọ alakọbẹrẹ titi de girama.
"Ti a ba da ileeṣẹ silẹ, awọn ọdọ maa ri iṣẹ ṣe, agba ati gbogbo eeyan yoo ri iṣẹ lọkunrin ati lobinrin. Awọn nnkan wọnyi la ko tii dawọ le lori tẹlẹ ree ti mo fẹẹ ṣe. Awọn nnkan ti a ti dawọ le lori tẹlẹ ree, ṣugbọn ti wọn ti lọ soko igbagbe.
"Mo jẹ anfaani eto ẹkọ ọfẹ lasiko baba Awolowo nigba ti a wa ni Oyo atijọ. Mo si rii pe awọn to n bọ lẹyin wa, ko ni anfaani yii jẹ. Emi fẹẹ mu eto ẹkọ ọfẹ lati ile-ẹkọ alakọbẹrẹ titi de girama wa. Bo ṣe ri nigba yẹn lati ori gege, iwe, baagi, tabili, aṣọ ni awọn ọmọ wa yoo maa gba lọfẹẹ, leyi ti yoo jẹ ki awọn ọmọ wa ni anfaani si eto ẹkọ to ye kooro latilẹ.
"Ẹ ma gbagbe pe ọmọ ti a ko kọ lo maa gbe gbogbo ohun ti a ba kọ ta, mo nii lọkan pe maa ṣe nnkan to maa yatọ ti ọmọ ile ko nii tori owo lati kẹkọọ. Koda nile ẹkọ giga, mo maa gbe igbimọ jade lati ṣe atunyẹwo lori owo ti wọn n san, lati ran awọn obi lọwọ."
Kò sí nnkan tó lè dá ṣíṣe iná mọ̀nàmọ́ná dúró
Nigba to n sọrọ nipa ọna to fẹẹ gba lati ṣe ina mọnamọna, o sọ pe "Osun kọ lo maa jẹ ipinlẹ to kọkọ ṣe e, wọn ti ṣe ni Abia, Niger to fi mọ awọn ipinlẹ miran, mo si rii pe ohun to rọrun lati ṣe ni. Ninu iwadii mi, mo ti lọ siwaju lati ṣagbeyẹwo ọna ti a le fi gba ṣe e, nnkan ti a maa ṣe ni, ti gbogbo Osun yoo si gbadun rẹ.
"Ko si nnkan ti ko ṣee ṣe, gbogbo awọn to n ṣe ina to fi n duro, paapaa lawọn ilu to sunmọ wa, ọpọ wọn lo jẹ pe ka pa ipinlẹ meji lọ. Awa naa ni ọpọlọ, a si kawe, ohun teeyan ba fẹẹ ṣe, to ba ti fi sọkan, o maa rọrun lati ṣe. Mo fi sọkan, a si maa ṣe e pẹlu aṣẹ Ọlọrun," o fi kun ọrọ rẹ.
Adélàjà nìkan ló lè dẹ́kun wàhálà àti jàgídíjàgan l'Osun
Oludije sipo gomina sọ pe gẹgẹ bi ẹni to nifẹ alaafia, to si n ṣe igbelarugẹ fun un loorekoore, oun ko ba wọn lọwọ si iwa ipa to le da wahala silẹ ri.
Salaam ni gbogbo agbekalẹ oun lati dẹkun iwa ipa ati jagidijagan ni lati jẹ ki gbogbo ọdọ ni ohun ti wọn n ṣe, ti wọn ko si nii ri ọrọ dida wahala silẹ ro.
O wa sọ pe ọna kan ṣoṣo lati dẹkun gbogbo iwa janduku ni lati dibo fun Adelaja tii ṣe ẹgbẹ oṣelu ADC lati de ipo gomina.
"Ọna kan ṣoṣo ti iwa janduku le gba dawọ duro ni ki awọn ọmọ ipinlẹ Osun dibo fun ẹgbẹ oṣelu ADC, nitori pe nnkan ti a ba n ṣe lonii, ni yoo ṣapejuwe ohun ti a maa ṣe ni ọla. Apejuwe wa ni pe ẹgbẹ alaafia ni ẹgbẹ wa. Mi o tiẹ ba wọn bu eeyan debi wi pe ma gba eeyan leti, debi wi pe maa ri ara mọ jagidijagan, ẹ ko si le gbọ ọ pe ọmọ ẹgbẹ mi n ja nibikankan.
"Mo n lọ ni mẹlọmẹlọ, ohun ti mo fẹẹ ṣe lo jẹ mi logun, kii ṣe ọọ ija. Ti a ba ti ni adari to mọ ohun to fẹẹ ṣe fun awọn eeyan, ko nii si wahala. Ti ọrọ aje ba n lọ daadaa, ti gbogbo eeyan n ri nnkan ṣe, ti wọn n ri nnkan jẹ, ko nii si wahala. Ko nii sẹni to maa ronu jagidijagan.
"Gbogbo awọn eto aabo to yẹ ka ṣe ni amuyẹ, paapaa awọn eyi to ti wa nilẹ to jẹ ti ijọba apapọ, ti a maa tun ṣe aṣekun rẹ. Awọn to n lọ sile ẹkọ giga ati girama, ko ni sẹni ti yoo raaye iwa ipa.
"Ti ẹ ba ti fi ẹni to n fẹ alaafia ṣe adari, alaafia yoo wa niluu, ko sẹni ti ko mọ pe awa ni gbogbo eeyan n pe ni Adelaja. Bi wọn ba ti dibo fun Adelaja, ko nii si ohun to n jẹ wahala mọ nipinlẹ Osun."
O tẹsiwaju pe "State Boys ti a da silẹ nigba naa lo jẹ ki awọn to n ṣe janduku duro jẹ, wọn si n tẹle ofin. Ko si ibi ti awọn eeyan ko ti n fẹ ṣe girigiri.
"Ọpọ awọn 'State Boys' yẹn ni wọn ti wa lẹnu iṣẹ ijọba, ti wọn si ti kuro nigboro. Wọn ko jẹ ki ọwọ wọn dilẹ.
"Ọna ti wọn gba mu nigba yẹn ti yatọ si bi wọn ṣe n ṣe e bayii, ko sẹni to n ra ibọn f'ẹnikan, ẹ ko si le gbọ wi pe wọn n ja loke tabi pe wọn n ja nisalẹ, nitori pe ijọba ṣeto ti igbayegbadun wọn fi n rọrun.
"Ohun ti ijọba ṣe ni lati fi opin si iwa ọdaran, ti ko si ṣẹlẹ nigba yẹn. Ko sẹni to le sọ pe ohun to ṣẹlẹ nigba yẹn lo jẹ ki a wa niru ipo ti a wa lonii, ko jọ ara wọn.
"Eto ti mo ni lọwọ lai ṣagbekalẹ 'State Boys', ni ki gbogbo ọdọ ri iṣẹ ti wọn maa ṣe, nigba ti mo sọ pe laaarin ọgọrun ọjọ akọkọ, a maa gba awọn to to ẹgbẹrun lọna ogun si iṣẹ, ina n bọ, itakun si n bọ.
"Ileeṣẹ n bọ ni Osun lati gba awọn eeyan si iṣẹ, nigba to gbogbo eyi ba de, ko ni saaye fun jagidijagan, paapaa nigba ti awọn eeyan ba n lọ si iṣẹ booji-o-ji mi, ti owo n wọle deedee, ti atijẹ ko si ni wọn lara."
Àwọn olùdíje ni bàbá àti ìyá ìsàlẹ̀ mi
Bakan naa, nigba to n dahun ibeere lori ọrọ baba isalẹ ninu ẹgbẹ oṣelu, oludije sipo gomina Osun sọ pe oun ko ni baba isalẹ nibikibi.
Salaam jẹ ko di mimọ pe awọn toun n ri gẹgẹ bii baba ati iya isalẹ ni awọn oludibo, to fi mọ adẹdaa ti wọn jẹ alatilẹyin oun.
O sọ pe iṣejọba oun ko le lọwọ baba isalẹ kankan ninu, nitori pe oun ti wa nipo oṣelu ri, toun si mọ ọna lati tukọ iṣakoso ipinlẹ Osun.
"Ohun ti wọn n pe ni Baba Isalẹ da duro oju teeyan fi wo o. Ko si ẹgbẹ kan laye ti kii ni oludari tabi agba ẹgbẹ. Ti ẹ ba wo ipolongo ti mo n ṣe kaakiri nipinlẹ Osun, ẹ maa rii pe emi ati awọn eeyan to nifẹ si ẹgbẹ wa la n kaakiri lai ni baba isalẹ.
"Ko si nnkan to n jẹ baba isalẹ ju awọn to wa lẹgbẹ mi lọ. Awọn oludije ni baba ati iya isalẹ mi. ni temi, Ọlọrun nikan ni mo ni baba ogun ati baba isalẹ to n bẹ lẹyin mi.
"Ni ipinlẹ Osun, awọn eeyan mọ pe mo lorukọ, mo si da orukọ yẹn jẹ ni, nko si fẹ ko bajẹ. Nko kọ imọran lati ọdọ ẹnikẹni, bẹẹ ni nko ṣe ijọba to jẹ pe ẹnikan lo maa paṣẹ rẹ. Gbogbo ohun ti mo fẹẹ ṣe ni mo ti fi sita, o si di dandan ki n ṣe e," Salaam ṣalaye.
Ìrólágbára àwọn àgbẹ̀ jẹ mí lógún
"Ti mo ba ni anfaani lati tukọ ipinlẹ Osun, awọn to n ṣowo nipinlẹ wa, yatọ si owo iranwọ lati fun awọn olokoowo, agbegbe ti a maa fi silẹ jẹ ki gbogbo ọlọja ta, eto ọrọ aje wa yoo lọ sọdọ awọn ọlọja.
"Eto ti mo ni fawọn agbẹ nipinlẹ Osun, yoo jẹ ki wọn le duro nita gbangba lati fọwọ sọya pe agbẹ ni awọn. A maa ran awọn agbẹ lọwọ debi pe wi pe ko nii si ipinlẹ naa ni ayika wa, ti ko nii jẹ pe ọdọ wa ni wọn yoo ti maa wa ra ounjẹ ti wọn yoo maa jẹ.
"Ti a ba da ounjẹ ileewe ọfẹ pada fun wọn, gbogbo ọlọja ni yoo maa ta patapata, ti gbogbo rẹ yoo si pada lọ sọdọ awọn agba. Eyi ko nii jẹ ki awọn eeyan maa ro pe owo oṣu awọn oṣiṣẹ nikan lo n yika.
"Ni ọdun akọkọ ti mo ba de ipo ijọba, mo ti ni owo ayasọtọ lati fi ṣe iranlọwọ f'awọn obinrin l'Osun lati jẹ ki iṣẹ wọn gbooro. Nnkan ti a ti ṣe ri ni, ti gbogbo eeyan ba lowo latii fi ṣiṣẹ, ipinlẹ wa yoo yi orukọ pada kuro ni ipinlẹ awọn oṣiṣẹ."
Gbogbo òṣìṣẹ́ ni yóò di onílé lórí
"Afojusun mẹwaa ni mo fi sita wi pe mo fẹẹ ṣe, ti mo ba si maa ri gbogbo rẹ ṣe, mo gbọdọ tọju awọn oṣiṣẹ, nitori pe awọn ni yara ẹnjiini fun gbogbo gidagbasoke ti mo fẹẹ ṣe.
"Mo ti ṣe awọn eto to jẹ pe awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Osun ko tii ri iru rẹ ri, eyi ti yoo mu inu wọn dun, ti yoo si jẹ koriya lati tẹsiwaju ninu iṣẹ isin wọn.
"Awọn ohun ti mo fẹẹ ṣe fawọn oṣiṣẹ pọ, mo ni eto to jẹ pe awọn oṣiṣẹ to wa lati ipele akọkọ lọ soke yoo di onile lori, lai yọ awọn olukọ silẹ. Loorekoore lawọn oṣiṣẹ yoo maa gba idanilẹkọọ lati jẹ koriya f'awọn oṣiṣẹ.
"Atunṣe lori ọrọ bi wọn ṣe n ya owo ọkọ ati owo ile ni mo ti ṣe leto kalẹ, ti maa si fi dun awọn oṣiṣẹ ninu nipinlẹ Osun, bi Ọlọrun ba ka mi yẹ lati de ipo," o fidi rẹ mulẹ.