You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Mó tí ṣé ìwọ̀n tí mó lé ṣé fún àwọn ọmọ Naijiria – Buhari
Aarẹ orilẹede Naijria, Muhammadu Buhari ni ti iṣejọba oun ti ṣe iwọn to le ṣe fun ilọsiwaju orilẹede Naijiria.
O sọ eleyi nigba to ki akọwe agba fun Abu Dhabi, Sheikh Al-Mahfoudh Bin Bayyah ati igbakeji rẹ, Pasitọ Bob Roberts ti ilẹ USA, ti wọn wa ki i ni Washington nilẹ Amẹrika.
“Ilu to tobi ni wa, ti eeyan si pọ, a koju ọpọlọpọ ijakulẹ ṣugbọn ni gbogbo ọna, a ti n gbinyanju lati bii ọdun meje ati abọ sẹyin, mo ti ṣe iwọn ti mo le ṣe.”
Gẹgẹ bii o ṣe sọ ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Garba Shehu fi lede, aarẹ ni bi awọn ṣe n wa ojutu si awọn iṣoro to ni ṣe pẹlu awọn ọdọ ti fihan pe ọjọ ọla wọn yoo dara.
O ni o ṣe pataki pe ki awọn ọdọ parapọ dide lati mojuto ọjọ ọla wọn, Aarẹ wa rọ awọn adari naa lati mu awọn ọdọ ni pataki nitori awọn ni ọjọ ọla ile aye.
“Isẹ yin ṣe pataki fun riran awọn ọdọ lọwọ lati ni oye to to ati lati ni iwuri nipa ibi ti wọn ti wa.
“Ilana ti ẹ gbẹ kalẹ yii ni yoo wulo fun awọn ọdọ lati gbe igbe aye irọrun pẹlu alaafia. Ni ọdọ ti wa, a oo tẹsiwaju lati maa wa ojutu si awọn iṣoro naa.”