You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
A ti bẹ̀rẹ̀ dídá ìkọlù padà sí Russia – Ààrẹ Ukraine, Zelensky
Aarẹ orilẹede Ukraine, Volodymyr Zelensky, ti fidi rẹ mulẹ pe Ukraine ti bẹrẹ si doju ija kọ Russia bayii.
“Igbesẹ ikọlu ati idaabo bo ara wa ti bẹrẹ”
Amọṣa o fi kun un pe oun ko ni tu iṣu de isalẹ ikoko lori ipele ti igbesẹ ikọlu naa wa.
Ọrọ aarẹ Ukraine yii n waye lẹyin ti ina ogun tun fẹju sii lẹkun gusu ati ila oorun orilẹ-ede naa.
Iroyin n sọ pe awọn ọmọ ogun Ukraine ti kọja si agbegbe ila oorun orilẹede naa de itosi Bakhmut ati agbegbe Zaporizhzhia lẹkun gusu.
Ati pe wọn ti ju ọpọ ohun ija oloro kọlu awọn ibudo to jẹ ti Russia.
Aarẹ Russia, Vladimir Putin sọ ninu ifọrọwerọ ori fidio kan eyi to jade lọjọ Ẹti pe awọn ọmọ ogun Ukraine ti bẹrẹ si n ṣe ikọlu si Russia, amọ wọn ko ṣai ba ọpọ ijakulẹ pade nibẹ.
Ninu ọrọ to sọ lọjọ Abamẹta lẹyin ipade rẹ pẹlu olootu ijọba Canada ni ilu Kyiv , Zelensky ṣe akawe ọrọ Aarẹ Russia gẹgẹ bi eyi to dun un gbọ leti.
O ni o ṣe pataki pe orilẹede Russia funra rẹ gan ti n mọ ọ lara pe “akoko diẹ lo ku fun wọn.”