Wanted by EFCC: Mompha fèsì Ó ní ìdúnkokò ni wọ́n ń ṣe láti gba N140m lọ́wọ́ òun

Published

Gbajumọ ori ayelujara nii, Ismail Mustapha,Mompha to ni ẹjọ pẹlu ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra EFCC ni Naijiria ti fesi si ọrọ ajọ naa to kede faraaye pe awọn n wa.

Ninu ọrọ rẹ to kọ soju opo ayelujara,Mompha ni ọrọ́ ko ri bẹẹ bi kii ṣe pe EFCC n dun koko mọ oun lati le fi ri owo gba lọna eru ni.

Lọjọru yi ni ajọ naa kọ soju opo wọn nipa atẹjade ti Wilson Uwajaren to jẹ agbẹnusọ wọn fi sita.

Ninu rẹ o sọ pe awọn n wa Mompha lori ẹsun iwa ọdaran.

Esi to Mompha si fọ pada loju opo rẹ ni Instagram to pe akọle rẹ ni ododo nkan to ṣẹlẹ lori pe EFCC n wa mi, o ni EFCC fẹ lo agbẹjọro wọn Rotimi Oyedepo lati yi oun lọwọ sẹyin gba owo.

Mompha sọ loju opo rẹ pe''lẹyin ti wọn kọkọ mu mi lọsiwaju adajọ ile ẹjọ giga ni Eko lọjọ kẹwaa osu Kejila 2021,adajọ ni ki wọn da ago ati awọn nkan miran ti wọn gba lọwọ mi pada.Wọn ni wọn ko gba wọn lọna ẹtọ''

Gbajumọoju ayelujara yi wa sọ pe itara ti EFCC ni lo jẹ ki wọn tun gbe oun lọ ksiwaju adajọ lẹẹkeeji nitori idajọ ti tẹlẹ ko tẹ wọn lọrun.

O fikun pe nigba toun lọ gba awọn ago ati nkan ini rẹ ti wọn gba lawọn EFCC mu oun mọlẹ ti wọn si wọ ohun lọ siwaju iadajọ mii ti wọn jijọ mọ ara wọn,

O fikun pe nibẹ ni adajọ yi ti gbe awọn ilana igba oniduro to ṣesẹ gbe kalẹ.

O ni aitete ribi tẹle ilana oniduro ti wọ́n gbe kalẹ yi mu oun pẹ latimọle.

Asẹyimwa aṣẹyinbọ, o ni oun pada ri oniduro yanju toun si kan si awọn mọlẹbi to wa ni ilẹ ọkẹre toun ti ri tipẹ.

140 million tabi 40 million, ewo ni EFCC fẹ gba gaan lọwọ Mompha?́

Afihan awọn iwe ipẹjọ kan taa ri loju opo Mompha fihan pe EFCC kọkọ sọ pe ki o mu owo idunadura ẹṣẹ taa mọ si plea bargain.

Iye ti iwe yi ti Mompha sọ pe agbẹjọro EFCC n dunkoko mọ oun lati gba jẹ 140m

Naira ṣugbọn oun kọ lati san owo yi.

O fi kun pe niṣe ni agbẹjọro yi n hale pe ti oun ko ba san iye owo yi, awọn yoo tu aṣiri fun adajọ pe o ti sa kuro ni Naijiria.

Abalọ ababọ, Mompha yi kanna lo fi iwe ipẹjọ miran han nibi ti adajọ ti gba pe ki oun san ogoji miliọnu Naira.

Bẹẹ ni wọn tun gbe awọn ilana mii kalẹ ninu rẹ taa ti ri pe ki Mompha ṣe ẹwọn ọdun kan lori ẹsun ti wọn fi kan an.