You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ènìyàn 12 kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìbúgbàmù ní ìpínlẹ̀ Rivers
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Rivers ti fi idi rẹ mulẹ pe eniyan mejila lo gbe ẹmi mi ninu iṣẹlẹ ibugbamu to waye ni ipinlẹ naa.
Ni owurọ Ọjọ Ẹti ni iṣẹlẹ ibugbamu naa waye ni agbegbe Rumuekpe ni ijọba ibilẹ Emoha nipinlẹ naa.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa naa, Grace Iringe-Koko ninu atẹjade to fi lede ni iwadii fihan pe awọn to ku ninu ibugbamu naa n gbiyanju lati wa epo bẹntirol ni ko to bu gbamu mọ wọn.
SP Grace ni ibi agbegbe ti wọn ti n wa epo naa lo gbina ni ẹṣẹkẹṣẹ ti awọn mejila si gbẹmi mi.
Iroyin to jade ṣaaju ni ibugbamu naa waye nigba ti ọkọ to gbe epo naa gbina.
Asiko ti wọn n kuro ni agbegbe ti wọn ti lọ ji epo naa ni iṣẹlẹ ọhun waye.
‘’Titi di asiko yii, iwadii fihan pe eniyan mejila ni wọn ti jona raurau, amọ ti wọn ko i tii si ẹni to da wọn mọ.’’
Bakan naa ni ọkọ marun un ati kẹkẹ marun un to wa nibẹ jona raurau.
Nibayii, ileeṣẹ ọlọpaa ti kesi awọn araalu lati ṣọra nipa gbigbe epo rọọbi lọna aitọ ati ki wọn maa jigbe.