Àwọn agbébọn tó ji wa gbé kò fẹ́ owó tàbí òfin Sharia, ohun tí wọ́n ń fẹ́ rèé... -Olùkọ́ àgbà ilé ẹ̀kọ́ Esinele sọ̀rọ̀ nínú fídíò tuntun

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Bi ọjọ ṣe n gori ọjọ lori awọn akẹkọọ ati awọn olukọ tawọn ajinigbe ji gbe ni ile ẹkọ ni awọn ilu Esinele ati Yawota ni agbegbe Ogbomoso ni ọsẹ mẹta ni oniruuru iroyin n jade nipa ohun tawọn ajinigbe naa n fẹ lati tu awọn eeyan naa silẹ.

Ni ọsẹ to kọja ni olori ile aṣofin ipinlẹ Oyo, Debo Ogundoyin sọ pe ijọba ko le fun awọn agbebọn naa ni ohun ti wọn n fẹ nitori awọn nnkan naa lagbara pupọ ti ijọba ko si le ṣe wọn.

Lara ohun ti iroyin gbe pe awọn ajinigbe naa n beere fun ni itusilẹ awọn akẹgbe wọn to wa ni ahamọ ijọba, owo biliọnu kan, siṣe amulo ofin Sharia ni ipinlẹ Oyo atawọn nnkan mii.

"Wọn o beere fun owo tabi ofin Sharia, wọn o beere fun nnkan ija ogun, nnkan ẹyọkan ti wọn n beere ni itusilẹ awọn eeyan wọn"

Amọ olukọ agba ile ẹkọ ti wọn ji gbe naa tun ti sọrọ ninu fidio mii tawọn ajinigbe naa gbe sita.

Ninu fidio naa ni Arabinrin Alamu ti rọ awọn akọroyin, atawọn to n gbe iroyin nipa ijinigbe naa lati ṣe pẹlẹ, ki wọn ye gbe ohun ti kii ṣe ootọ.

O ni awọn ajinigbe naa ṣafihan awọn nnkan fun awọn pe awọn eeyan n sọ pe awọn n beere fun ofin Sharia ni ipinlẹ Oyo ati owo lati gba itusilẹ awọn, obinrin naa ni ọrọ ko ri bẹẹ.

O ni niṣe ni awọn eeyan n mu ohun nira sii fawọn nitori awọn ajinigbe naa ni ohun ti awọn n fẹ ko ju lati gba awọn eeyan wọn to wa ni ahamọ silẹ lọ.

Alamu ni "oni lo pe ọjọ mẹrinlelogun ti a ti wa nibi yii, o dabi pe awọn kan n mu ki iṣoro wa peleke sii.

"Wọn fi awọn iwe iroyin kan han wa nibi ti wọn ti kọ sibẹ pe awọn to ji wa gbe n beere fun itusilẹ awọn eeyan kan, wọn beere fun ọkọ, wọn beere fun biliọnu kan naira ati imulo ofin Sharia.

"Awọn nnkan yii kii ṣe ootọ, wọn kan n da iṣoro kalẹ fun wa ni, ko si ẹni to fi tipa mu wa lati maa ṣẹsin Islam, wọn fi wa silẹ laaye wa.

"Wọn o beere fun owo tabi ofin Sharia, wọn o beere fun nnkan ija ogun nnkan ẹyọkan ti wọn n beere ni itusilẹ awọn eeyan wọn.

"A n bẹ awọn eeyan lati ma fi ẹmi wa ṣe oṣelu, a lero pe ijọba maa jiroro pẹlu wọn lati mọ awọn ti wọn fẹ itusilẹ wọn ki awọn naa le gba itusilẹ."

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣẹyin?

Ṣaaju ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo ti tako aba lati bawọn agbebọn ti wọn ji awọn akẹkọọ ati olukọ gbe l'Ogbomoso dunaadura.

Adari ile, Họnarebu Adebo Ogundoyin, lo fi idi ọrọ yii mulẹ lasiko ti ile jiroro lori ọrọ naa.

Ninu fidio kan to ṣafihan ijokoo ile igbimọ aṣofin Oyo ni adari ile ti sọ pe ijọba ko ni sanwo fawọn agbesunmọmi lati fawọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn ji gbe lominira.

Ogundoyin sọ ninu fidio naa wi pe ''ṣe to ba jẹ pe ẹyin ni gomina ipinlẹ Oyo, ṣe ẹ maa gba lati fun awọn agbesunmọmi ni owo gobọi, nnkan ijagun, ati agbekalẹ ofin ti ko ni tako wọn lọjọ iwaju?

Ṣe ẹyin maa fawọn agbesunmọmi lawọn nnkan yii ti wọn maa fi gbilẹ si i lagbegbe igberiko ti wọn ti n ṣọṣẹ?''

Adari ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo sọ pe ọpọ eeyan ni ko mọ ẹkunrẹrẹ nnkan tawọn agbebọn ti wọn ji awọn akẹkọọ ati olukọ gbe nijọba ibilẹ Oriire n beere fun.

Họnarebu Ogundoyin ṣalaye pe idi niyi tawọn eeyan fi ni lati ṣe suuru lori ọrọ yii.

O ni ijọba yoo fawọn agbesunmọmi ni igboya lati tubọ maa ṣọṣẹ si i ti wọn ba le fun wọn lawọn nnkan ti wọn n beere fun.

Oni ọjọ Ẹti ọjọ karun un oṣu Kẹfa lo pe ọsẹ mẹta ti wọn ti ji awọn akẹkọọ atawọn olukọ ti wọn gbe lọ nile ẹkọ ni Esinele ati Yawota l'Ogbomoso.

Ṣaaju ni Aarẹ Bola Tinubu ti bu ẹnu ẹtẹ lu bawọn agbebọn naa ṣe yinbọn pa ọkan lara awọn olukọ ile ẹkọ girama ti wọn ti ji awọn eeyan gbe ni Esinle.

Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo naa fidi rẹ mulẹ pe awọn agbebọn ọhun tun ṣekupa olukọ imọ iṣiro to wa lara awọn ti wọn ji gbe.

Lẹyin naa ni Aarẹ Tinubu paṣẹ fawọn ẹṣọ eleto aabo lati lọ doola awọn akẹkọọ atawọn olukọ naa.

Ẹgbẹ awọn olukọ ati oniruuru ẹgbẹ mii lo ti n ṣewọde lati pe fun itusilẹ awọn akẹkọọ atawọn olukọ to wa lakata ajinigbe naa.

Amọ, awọn eeyan yii ti wọn le logoji si wa lakata awọn ajinigbe titi di asiko ti a kọ iroyin yii.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Ẹti, ọjọ Kẹẹdogun oṣu Karun-un ọdun 2026 yii ni awon ajinigbe yabo ile ẹkọ mẹta niluu Ogbomoso.

Ahoro Esinele, Yawota ati Alausa ni wọn ti ṣiṣẹ ibi naa, ti wọn pa olukọ kan lasiko ikọlu, ko akẹkọọ mẹtadinlogoji, olukọ meje wọgbo lọ.

Lẹyin ọjọ diẹ ti wọn ko wọn lọ ni awọn ajinigbe naa fi aworan ibi ti wọn ti bẹ ori olukọ kan, Micheal Ojedokun, sori ayelujara.

Latigba naa ni igbesẹ ti n waye lati ri awon to wa nigbekun naa gba kalẹ, eyi to ti pe ọsẹ mẹta bayii.