Ìjọba àpapọ̀ yóò ṣe ìrànwọ́ fún àwọn tó n ta tòmátò àti ata, kìí ṣe àkàrà nìkan – Oluremi Tinubu

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aya Aarẹ Naijiria, Sẹnetọ Oluremi Tinubu ti sọ pe kii ṣe awọn to n ṣe okoowo agbado ati akara tita nikan ni ijọba apapọ fẹ ṣe iranlọwọ fun lati mu ki okoowo wọn gbooro sii.

O ni gbogbo awọn ọlọja ti wọn n ta ata, tomato, to fi mọ bọọli, ni ijọba Naijiria n foju sọna fun lati ro lagbara.

Sẹnetọ Tinubu lo sọrọ yii lọjọ Aje nibi eto ifilọlẹ gbọngan Abubakar Maje Haruna ti wọn ṣẹṣẹ kọ sinu ọgba aafin Emir tiluu Hadejia, nipinlẹ Jigawa.

Bi ẹ ko ba gbagbe, lọsẹ to kọja yii ni aya aarẹ sọ pe okoowo to dara ni akara, kulikuli ati agbadoo sisun tita, ati pe ijọba apapọ n gbero lati ṣe iranwọ fun awọn to n ṣiṣẹ naa.

Kete ti Sẹnetọ Tinubu mẹnuba ọrọ yii ni awọn ọmọ Naijiria ti bẹrẹ sii bu ẹnu atẹ lu u, ti wọn si n fi ye e pe ko mọ ohun to n sọ.

Nigba to n da awọn to n bu ẹnu atẹ lu ọrọ rẹ lohun, Tinubu sọ pe ijọba apapọ ti fi ọgọrun miliọnu kan naira ta ipinlẹ Jigawa lọrẹ, lati fi ṣe ironilagbara fun ẹgbẹrun meji awọn ọlọja kekeekee kaakiri ipinlẹ naa.

"Ọrọ kobakungbe ti awọn eeyan n sọ ko ni da iṣẹ rere ijọba duro"

O ni "Nitori agbegbe ti a wa, nipa nnkan to n lọ, mo ti sọ fun aya gomina pe a ti fun ipinlẹ naa ni ọgọrun miliọnu naira lati fi ro ẹgbẹrun meji awọn olokoowo kekeekee lagbara.

"Mo si mọ pe wọn sọrọ nipa akara ti mo darukọ. Kii ṣe akara nikan, a tun ni awọn to n ta tomato. A ni bọọli, ati awọn to n ta ata, to fi mọ ẹfọ fun wa ninu ọja.

"A maa tẹsiwaju lati maa ṣe ironilagbara fun wọn, ka si ṣe igbesoke fun okoowo ati ọrọ aje wọn. Ohun ti a n ṣe niyi."

O sọ siwaju pe gbogbo awọn to ba ni anfaani si eto naa yoo gba ẹgbẹrun lọna aadọta naira, lati ṣe agbelarugẹ fun okoowo wọn.

"A n tẹsiwaju lati gbe ẹru naa. A ni akọsilẹ ẹgbẹrun meji awọn obinrin to wa ni ilana okoowo kekeekee. Wọn maa gba ẹgbẹrun lọna aadọta naira lati mu idagbasoke ba okoowo wọn."

O wa sọ pe gbogbo awọn ti wọn n bu ẹnu atẹ lu ọrọ oun, ko nii da ijọba duro lati tẹsiwaju ninu ilana eto ironilagbara.

Olurẹmi tẹsiwaju pe "Mo mọ pe gbogbo awọn ti ọrọ yii kan ni wọn yoo mọ riri anfaani tuntun yii. Ati pe ọrọ kugbakungbe ti awọn eeyan n sọ si wa ko nii da wa duro lati tẹsiwaju. Ṣugbọn ṣa, a n tẹsiwaju lati rii daju pe a dide iranwọ fun awọn eeyan wa," Tinubu fi kun ọrọ rẹ.